Baba Ijesha: Yomi Fabiyi ní afurasí náà ní òun kò tíì ní agbẹjọ́rò tí yóò ṣojú rẹ̀ níléẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Babaijesha/realyomifabiyi/Instagram
"Mo bẹ Baba Ijesha wò l'àhámọ́, ẹ ẹ́ gbọ́ wirínwirìn ọ̀rọ̀ nílé ẹjọ".
Ilumọọka osere tiata nni, Yomi Fabiyi ti sisọ loju rẹ pe oun ti se abẹwo si Baba Ijesha ni ahamọ ọlọpaa, ẹni ti wọn fẹsun sise asemase pẹlu ọmọde kan.
Yomi Fabiyi sisọ loju ọrọ yii lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iwọde to fẹ se tako awọn ọlọpaa ti wọn ko ba gbe iya ọmọ ti ọrọ kan lori ẹsun lilo ọmọ rẹ fun asemase lati ko ẹri jọ.
"Emi o mọ ibi ti awọn to ni awọn pupọ ṣẹ n tẹle mi ti ri ero o, mo ti ni ero temi tẹ́lẹ̀, botilẹ jẹ pe ko tii pọ to, awọn to mọ ibẹrẹ mii naa lo fẹran mi to n tẹle mi".
O ni awn to n wọ tẹle oun jẹ awn to rii pe eeyan kan ṣe maa da duro to si jẹ pe ootọ lo n sọ.
Yomi Fabiyi ni lasiko abẹwo rẹ si agọ ọlọpaa Panti, nibi ti wọn fi Baba Ijesha pamọ si ni oun ti bi afurasi naa pe ko sọ ootọ to ba jẹ pe o ba ọmọde naa lopọ.
- Ohun tí ìyàwó Adeboye ṣe ní ìgbà akọkọ tó fojú hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn Dare
- Pasítọ̀ Dare, ọmọ́ Pásítọ̀ Adeboye ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 42
- Nǹkan pàtàkì mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Salawa Abeni bí ó ṣe pé ọgọ́ta ọdún.
- Ikú tó fẹ́ pa Opeyemi Ayeola ṣí i ní fìlà, ló bá ń kọrin ẹ fọ̀rọ̀ mi kọ́gbọ́n
- Ẹ̀wọ̀n gbére tàbí ọlọ́dún mẹ́ta, méje, àtàwọn ìjìyà tó ṣééṣe kí Bàbá Ijeṣa jẹ rèé - Ìjọba ìpínlẹ̀ eko
- Toyin Abraham jọ̀wọ́ dáríjì mí - Yomi Fabiyi
- Ṣé o mọ àwọn òrìṣà ìṣẹ̀mbáyé méje tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú?
"Mo gbiyanju, mo lọ si Panti, mo si ni ki wọn jẹ ki n ri Baba Ijesha, mo bii pe se lootọ lẹ ba ọmọ naa sun amọ o sọ fun mi pe ko ri bẹẹ, oun ko ba sun rara.
Mo wa sọ fawọn ọlọpaa pe ki wọn duro si ẹgbẹ mi, ki wọn maa gbọ ohun ta n sọ, mo si tun bi Baba Ijesha pe ẹ jọọ se fidio ta n sọ yẹn, se fidio pe ẹ n ba ọmọ yii sun ni ?
Baba Ijesha wa ni Yomi, emi fi n da ẹ loju pe ko ri bẹẹ amọ to ba ri bẹẹ, bẹ ori mi sogun, n ko ba ọmọ yii sun ninu fidio yẹn, amọ mo fi ọwọ kan."
Yomi Fabiyi wa tẹsiwaju pe oun tun bi Baba Ijesha pe se o ti ri fidio ti wọn gbe sita nipa oun ati ọmọde naa, to si ni rara amọ ki oun lọ wo lati se atupalẹ rẹ.
O ni oun wa bẹ awọn ọlọpaa pe ki wọn jẹ ki oun ri fidio naa amọ wọn ni oun ko le ri, ti oun si sọ fun Baba Ijesha pe yoo dun oun gan, ti ọrọ naa ba de ile ẹjọ, ti asirir si tun pe o sẹ ẹsẹ naa.
Gbajumọ osere tiata naa ni oun tun bi afurasi naa pe se wọn n fiya jẹ ni ahamọ ọlọpaa bi, to si ni rara amọ o ni oun ko ti ni agbẹjọro ti yoo soju oun nile ẹjọ.
"Mo tun bi pe bawo lo se n jẹun, ti mo si se iwọnba ohun ti mo le se fun lori eyi nitori emi kii se ajẹnisẹni.
Bi eeyan to sun mọ mi ba sẹ, ẹtọ mi ni lati se atilẹyin fun. Kii se pe ẹnikẹni n gbe lẹyin Baba Ijesha, ohun tawọn eeyan n sọrọ le lori lo da lori ẹri to wa niwaju wọn."
Yomi Fabiyi wa sisọ loju rẹ pe o seese ki Baba Ijesha ti ni agbẹjọro ti yoo soju rẹ bayii ti yoo sọrọ fun nitori ẹni kan ti pe oun lori ọrọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ayé ń pè wá ní 'Yeyebrity' torí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, nǹkan bà wá lágbo tíátà Yoruba"
- "Ṣé ẹ léró pé ọmọ mi ṣì lè padà wá bá mi láàyè báyìí? Òbí akẹ́kọ̀ọ́ Kaduna
- Tóo bá ní ìmọ̀ nípa ǹkan, ran àwọn tí kò ní ìmọ̀ lọ́wọ́ láti mọ̀ - Yomi Fabiyi
- Kí ni àwọn Mùsùlùmí máa ń ṣe ní alẹ́ ọjọ́ 10 tó gbẹ̀yìn àwẹ̀ Ramadan?
- Mínísítà ìbaraẹnisọ̀rọ̀ ti sún ìsopọ̀ NIN àti SIM di June 30
- Ìdí rèé tí ìgbéyàwó ọdún 27 tú ká láàárín Bill àti Melinda Gates
- Haram ni kí èèyàn máa san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé - Sheikh Ibrahim Maqari
O fikun pe wọn ko tii gbọ ọrọ lẹnu Baba Ijesha amọ nigba to ba dele ẹjọ, a o gbọ winrinwinrin lẹnu rẹ.
Nigba to n sọrọ lori iwọde to fẹ se, Yomi Fabiyi ni ohun ko le dakẹ lori ọrọ naa nitori ko dara ki wọn maa fi ọmọde ko ẹri jọ, o le sọ wọn di apẹẹrẹ Ajasẹ.
O fikun pe bi oun se iwọde, bi oun ko se iwọde, nigba ti ọrọ naa ba de ileẹjọ, gbogbo aye yoo gbọ ẹsun lorisirisi, wọn yoo fi ẹsẹ fẹ.

Tóo bá ní ìmọ̀ nípa ǹkan, ran àwọn tí kò ní ìmọ̀ lọ́wọ́ láti mọ̀ - Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi
Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba to ti n gba waju ga ẹyin lati igba ti ọrọ ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijesha ti ṣẹlẹ, yomi Fabiyi tun ṣe afiwe ọrọ kan fi yi awọn akẹgbẹ rẹ lara.
O jẹ ko di mimọ pe oun mọ nkan ti oun nṣe tabi sọ lori ẹsun naa paapaa lẹyin to ti wo fidio kan to jade ti iroyin ni o ṣafihan bi Baba Ijesha ṣe n fi ọwọ pa ọmọde ti wn ni o ba ṣe aṣemaṣe lara.
Yomi to ti kede pe oun yoo ṣe iwọde bi ijọba tabi ọlọpaa ko ba ṣe nkankan ni Iwọde lati ja fun ẹtọ ọmọde lori ifipabanilopọ ni nkan to tọju lati ṣe.
"Iwọde wọọrọwọ lori ẹsun ifipabanilopọ ati aṣemaṣe pẹlu ọmọde yẹ ko jẹ nkan ti yoo di ranto. Ija fun ẹmi Naijiria lo jẹ ati ija fun ọjọ iwaju wa ni".
Fabiyi ni ẹtọ rẹ ni iwọde wọọrọwọ. O ni asiko ti to lati ya awọn to ni imọ, to laju, ti ko gbe sẹyin ẹnikan, to n ja fẹtọ ọmọniyan ati olufọkansin araalu sọtọ kuro lara awọn ti ida keji wọn.
"Ija yii, fun ọmọ rẹ ati awọn ọmọ mii ni". Yomi Fabiyi fi kun un wipe iṣẹlẹ yii to eyi teeyan n fi gbogbo nkan ji fun.
"Bakan meji ni, yala Naijiria n pada sẹyin tabi lọ siwaju ni. Agbajọwọ wa la le fi sọya nipa fifi ohun kan sọrọ lori gbogbo iwa biba ọmọde ṣe aṣemaṣe, fifi wọn dẹ pakute, ifipaba wọn lopọ ati ilkulọ ibalopọ."
Gbogbo eyi ni Yomi ni o lee mu orilẹede lọ siwaju tabi ko mu u jo ajorẹyin to si ni ẹni ti ko ba ni imọ ko wa a daadaa ko to maa bọ sori ayelujara sọrọ soke.
- "Ṣé ẹ léró pé ọmọ mi ṣì lè padà wá bá mi láàyè báyìí? Òbí akẹ́kọ̀ọ́ Kaduna
- Mínísítà ìbaraẹnisọ̀rọ̀ ti sún ìsopọ̀ NIN àti SIM di June 30
- Haram ni kí èèyàn máa san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé - Sheikh Ibrahim Maqari
- Ìdí rèé tí ìgbéyàwó ọdún 27 tú ká láàárín Bill àti Melinda Gates
- Microsoft gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè iṣẹ́ 27,000 fún àwọn ọmọ Naijiria




















