Yoruba film celebrities: Yomi Fabiyi ké sí àwọn ará kí wọ́n gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi
Gbajumọ ni Yomi Faibiyi lagbo oṣere fiimu Yoruba o si ti kede faraye pe oun ti pada sinu ẹsin ti wọn bi oun si bayii.
Ọniruuru ni iroyin ti awọn eeyan mọ nipa oṣere yii amọ ọpọ ololufẹ rẹ ko fibẹẹ le tọka si ẹsin kan pato to n ṣe.
Ninu atẹjade to kọ sita funrarẹ lori ayelujara lo ti ni inu ẹsin Islam ni wọn bi oun si, oun si ti pada sinu rẹ pẹlu iwuri.
"Mo ti pada si ẹsin ti wọn bi mi sinu ẹ. Mo ni iwuri lati jẹ Musulumi. E gbe Ọlọrun Ọba tobi..."
Yomi Fabiyi kede pe nibayii, orukọ oun ni Lukmon Abayomi Fabiyi.
Lori eyi ni ọpọlọpọ akẹgbẹ rẹ ati ololufẹ r ti n kan sara sii fun igbesẹ tuntun to gbe.

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi
Bi awọn kan ṣe n ki i ku oriire ni awọn mii ro pe sakamanje lasan ni to fi n gbe awọn mọra. Koda awọn kan n kọ ọ pe kii ṣe ọwọ alafia bi ko ṣe ọwọ tun ni wọn maa n gbe Al Quran si.

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi










