Ìtànjẹ ti pọ̀jù nínú iṣẹ́ tíátà, a kò rí kọ́bọ̀ nínú fíìmù tó wà lórí YouTube - Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, yomi fabiyi
Gbajumọ elere tiata, Yomi Fabiyi ti salaye pe, ọpọ eeyan to fi gbogbo ara ṣiṣẹ tiata, ti wọn ni okiki ati ọrọ, ni akude tí de ba lasiko yii.
Fabiyi salaye bẹẹ lasiko to n kopa lori eto kan ni ikanni BBC Yoruba pẹlu afikun pe, iya n jẹ ọpọ elere tiata lasiko yii.
O ni afihan awọn sinima to n waye lori ayelujara, ti awọn alagbata n gbe sinima silẹ ni gbẹfẹ lai jẹ kò ṣe iyebiye loju araye, n din ifẹ ati ojulowo isẹ tiata ku.
"Ọpọ awa ta ni sinima to wa lori YouTube ni a ko ri kọbọ gba lori afihan rẹ. Awọn to n ta sinima wa lo n pa owo sapo ara wọn lai fun ẹni to ni iṣẹ ninu ere ti wọn ba jẹ."
"Ẹtan ti pọju ninu iṣẹ tiata, o ti bajẹ , o si ti pin yinkin, ko si le e to ogun ọdun mọ ti ẹka iṣẹ tiata yoo fi dojude."
Bakan naa ni Fabiyi tọka si pe, iya n jẹ awọn eeyan ninu iṣẹ tiata ni oun ṣe n pariwo sita, ẹni to ba si wu, ko fẹran oun, tabi korira oun, osere tiata ti ojuṣe rẹ ba si tọ si sinima kan, lo yẹ ki wọn maa pe sibẹ, lai fi ọrọ ẹbi abi ti ọrẹ ṣe.
" Ẹ jẹ ka ye tan ara wa mọ. Ẹ jẹ ka sootọ pẹlu ara wa, ka ṣe ipade ba ti pin èrè, iya ko ni jẹ wa, tori isẹ ọwọ wa to wa jẹ.

Oríṣun àwòrán, yomi fabiyi
O ni "ko si bi awọn ti yoo ṣe onigbọwọ sinima ṣe le e gbe owo kalẹ, nitori ko si ilana to tọ lati ọdọ awọn oni sinima Yoruba."
Yomi Fabiyi wa gbosuba fun ikọ alaanu ti Foluke Daramola da silẹ, to pe ni para, eyi to n ṣe itọju awọn alaini, pẹlu afikun pe, o seese ki abuku ta ba eeyan nidi ṣiṣe isẹ aanu amọ eyi ko yẹ ko da omi tutu si eeyan lọkan.
" Ọpọ ni ara n ni lori isẹ aanu ti Foluke Daramola n ṣe, ọpẹ iru wa to wa lẹyin rẹ, awọn kan ro pe o n wa okiki, lo ṣe n ṣaanu."
Nigba to n sọrọ lori ẹgbẹ awọn osere ori itage TANPAN ati eto iranwọ to n fun awọn agba ọjẹ ninu ẹgbẹ, Fabiyi ni o ṣe ni laanu pe ko si ọmọ ẹgbẹ naa to n san owo sinu ẹgbẹ, ti wọn ko si pọn omi silẹ de ongbẹ.
- Fásitì UNIOSUN ṣètò ìgbaniwọlé orí ayélujára fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tuntun fún ìgbà àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà, Ohun tí a mọ̀ nípa rẹ̀ nìyí
- N4,200 la fẹ́ fi pèsè oúnjẹ fún akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan láti ìdílé tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta yíká Nàìjíríà - ìjọba àpapọ̀.
- Nínú ìṣèjọba yìí, Èmi àti Ààrẹ Buhari lọlọ́rọ̀, kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà-Ibrahim Gambari, olórí òṣìṣẹ́ lọ́fíìsì ààrẹ
- Mo kábàámọ̀ pé n kò kàwé, kí n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà - Sanyeri
" Aarẹ ẹgbẹ wa, Bolaji Amusan, taa mọ si Mr Latin n saayan lati to ẹgbẹ naa, ọmọ ẹgbẹ ti ko ba si ṣe ojuse rẹ ninu ẹgbẹ, yoo da ran isoro to ba baa ni."
Lori ohun ti yoo sẹlẹ si iṣẹ tiata lẹyin ti arun Covid-19 ba kasẹ nilẹ, Fabiyi ni adinku gbọdọ ba awọn sinima oyinbo ti wọn n gbe wa si awọn ile sinima ni Naijiria, ki awọn osere tiata si ni orisun ọrọ aje pupọ, kipo iṣẹ sinima nikan, ti wọn gbajumọ.
Yomi Fabiyi tun koro oju si iwa aibọwọ fofin lati ọdọ awọn alaṣẹ ati agbofinro lasiko igbele Covid-19, ti wọn si n tẹ ẹtọ araalu loju.
O ni ko si ipese ina lati ọdọ ìjọba, ko si nọmbà foonu ipe pajawiri, pẹlu afikun pe, o yẹ ki agbekalẹ ilana wa fun ẹni to ba nilo itọju pajawiri, lọna ti igbele Covid-19 ko fi ni ṣe akoba fun ilera rẹ.












