UNIOSUN : Ètò ìgbaniwọlé orí ayélujára fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tuntun ní fásitì UNIOSUN kò dín iyì ilé ẹ̀kọ́ gíga kù fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa- VC UNIOSUN

Orukọ ileewe fasiti Osun lẹgbẹ ogiri

Oríṣun àwòrán, other

Awọn alakoso fatisi ti ipinlẹ Osun, UNIOSUN ti ni awọn ko mọ igba ti ajakalẹ arun Coronavirus yoo pari ni awọn ṣe ṣe ayẹyẹ igbaniwọlẹ Matriculation fun awọn ọmọ ileewe to ṣẹṣẹ wọ ile iwe giga naa.

Oludari ile iwe giga UNIOSUN, Ọjọgbọn Labode Popoola lo sọ bẹẹ fun BBC News Yoruba lẹyin ti wọn ṣe ayẹyẹ iwọle naa fun awọn ọmọ ileewe.

Ọjọgbọn Popoola ni idi ti awọn fi gbe igbesẹ naa ni wi pe ni ayẹyẹ naa pọn dandan ni awọn ṣe ṣe fun awọn ọmọ ileewe giga naa.

O ni ayẹyẹ naa lọ ni irọwọrọṣẹ pẹlu ẹrọ ayelujara to lọ geere lai si idiwọ idena fun ayẹyẹ naa ti awọn ṣe fun wakati mẹta.

Oludari ileewe UNIOSUN naa ni iyatọ to wa ni bẹ ni wi pe awọn akẹẹkọ naa ko ri asọ ẹ̀ku, Matric Gown ti wọn ma n wọ ni ọjọ ayẹyẹ naa.

Ọjọgbọn Popoola naa wa fikun wi pe ti awọn ba ni anfaani lati ṣe iru rẹ nigba miran, awọn yoo ri wi pe awọn fi asọ ẹku naa sọwọ si wọn ni ibi ti wọn ba wa.

Àkọlé fídíò, U.I Language Centre: Yorùbá ló làṣà àti èdè

Lori ibeere pe bọya ileewe naa yoo wọle laipẹ, Adari ileewe naa ni awọn akẹẹkọ ti n kẹkọ lori ẹrọ ayelujara fun igba diẹ si isinyii.

Bakan naa ni wọn fikun wi pe ti arun Coronavirus yii ko ba kuro nilẹ laipẹ, awọn yoo ṣe idanwọ fun awọn ọmọ naa.