Alaafin of Oyo: Olori Anu dúpẹ́ lọ́wọ́ kábíyèsí Ọba Adeyemi fún ipa ribiribi to kó láyé òun

Oba Adeyemi III

Oríṣun àwòrán, Olori Anu/ Instagram

Àkọlé àwòrán, Olorì Anu Adeyemi ń ṣe ọjọ ìbí, ẹgbẹ́ ǹkan tò sọ sí Kábíyésì
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 14

Ọkan nínú olori lááfìn ọba Oyo, Ọba Lamidi Olayiwole Atanda Adeyemi III Iku baba yeye, olori Anu.

Nínú ọrọ rẹ ó gboríyìn fún aláàfin gẹ́gẹ́ bi abẹ ẹsẹ eni ti òun ti n kẹ́kọ̀ọ́, ẹni tó kami lati maa ní afojúsùn

O ní kábíyèsí ló kọòun pé ẹni ti kò ba ni ìwòye ni wọ́n n pè ń pè ni aláìniwòye ọjọ́ ìwáju '' Kábíyèsí ni ẹni náà dàbí ọkọ ojú omí ti kò sí atukọ níbẹ̀"

Olori Adejoke Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Anu Adeyemi/Instagram

Àkọlé àwòrán, Olorì Anu Adeyemi ń ṣe ọjọ ìbí, ẹgbẹ́ ǹkan tò sọ sí Kábíyésì

Olorì ní ọ̀na sí aṣeyọrí kò rọgbọ rárá, sùgbọ́n ìpinnu ọkan àti àforítì gangan ni èròjà fún àṣeyọrí"

"Baba kí ẹ pẹ́ lórí itẹ àwọn babanla yín, Ọdún tuntun yìí a sàn wá si ohun rere àti igbé aye ọtun ti yóò tì mi sí ibi gíga."

Ṣé olorì ṣì ni Badirat Ọla láàfin ikú bàbá yèyé?

Alaafin of Oyo: Olori Badirat ti fèsì fún ẹ̀yin tó fẹ́ mọ bóyá ó sì jẹ́ olorì Aláàfin àbí bẹ́ẹ̀kọ́ kọ́

Alaafin ati olori Badirat

Oríṣun àwòrán, Alaafin of oyo

Yoruba ni lowe lowe la n lu ilu agidigbo, ọlọgbọn lo n jo, ọmọran si nii mọ.

Bẹẹ ni ọrọ ri ni aafin Oyo nigba ti ọkan lara awọn olori Alaafin tilu Oyo, ayaba Badirat Olaitan Adeyemi da awọn eeyan to n sọrọ nipa rẹ lohun lori ayelujara.

Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin kan tan kalẹ pe olori naa ni ajọṣepọ ikọkọ pẹlu gbajumọ akọrin Fuji nni, Wasiu Ayinde Kwam I, bi o tilẹ jẹ pe awọn mejeeji ti ṣẹ lori ahesọ ọrọ naa.

Ohun ti gbajugbaja olorin Fuji, K1 si sọ̀ nigba naa ni pe, 'ko si idi fun mi lati ni ajọ̀ṣepọ̀ kankan pẹlu awọn ayaba laafin. koda mi o tiẹ gbọdọ roo lọkan depo ki n ṣe nnkan to jọ'

Amọ lati igba ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ni awọn eeyan ti n lakaka boya lootọ ni olori Badirat Ola si wa ninu aafin Oyo abi bẹẹ kọ.

Nigba to wa n fi okodoro ọrọ mulẹ pe ayaba si ni oun laafin Oyo, olori Badirat bọ soju opo Instagram rẹ, @queenola2, to si ṣe afihan aworan oun ati ọkọ rẹ, Alaafin papọ.

Àkọlé fídíò, Sekinat Quadri ọmọ ọdun meje ajẹsẹ to fẹ dabi Anthony Joshua

Ninu aworan naa la ti ri Badirat ati ọba alaye naa, ti wọn wọn aṣọ oke kan naa lori ijokoo, ti wọn si n tẹ sọrọ, ori awọn mejeeji lo fẹẹ sun mọ ara wọn pẹki pẹki.

Ohun ti Badirat si kọ si abẹ aworan naa ni pe Alaafin n beere pe " Ṣe o ko ni dẹkun lati maa rẹwa tabi dun wo ni?

Aworan yii lasan si ti sọ ohun ti awọn araalu fẹ mọ, eyi to n ṣọ pe ọba alaye naa si nifẹ oun bii oju, to si n gbadun pe oun rẹwa pupọ.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Alaafin of Oyo: Aláàfin pàṣẹ lórí ilẹ̀ tó ń dènà àbò fáwọn ará ìlú Ọ̀yọ́

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Alaafin

Awọn onimọ kan ni wọn paṣamọ pe eeyan ti were ba lu iya rẹ pa, bo ba ri mọkaliiki ko ni duro.

Eyi lo ṣebi ẹni difa fun awọn eeyan agbegbe Kosobo ni ilu Ọyọ alaafin ti wọn ni wọn ke gbajare tọ iku baba yeye, Alaafin Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta lori ilẹ kan ti wọn ti pati eleyi ti wọn ni o ti di igbo nla saarin ilu ti wọn si ni o ti di ibuba fawọn oniṣẹ ibi gbogbo.

Bi ẹ ko ba si ni gbagbe iṣẹlẹ kan to ṣẹ ni agbegbe Soka ni ilu Ibadan lọdun diẹ sẹyin nibi ti wọn ni awọn agbenipapawo fi ṣe ibuba ti wọn ti n pa awọn eeyan ti wọn si n ṣe karakata ẹya ara eniyan.

Ilẹ naa ti iwọn rẹ to ọgbọn sare ni wọn sọ pe Alaafin Lamidi Adeyẹmi fun eekan oludaleeṣẹsilẹ kan lati fi kọ ileewe girama ti wọn pe oruks rẹ ni Abiọdun Atiba Grammar School ki wọn lee lo iyoku rẹ fun idagbasoke lọjọ iwaju.

Alaafin atawon eeyan ilu Oyo

Oríṣun àwòrán, oyoinsight.com

Ilẹ apati yii ni wọn lo ti wa di ẹrujẹjẹ to lee pagidina abo awọn olugbe agbegbe naa ti wọn n ni awọn iwa ọdaran bii ifipabanilopọ, idigunjale ati ile fifọ lo n waye lati ibẹ wa.

Ariwo gbajare yii ni wọn ni o de eti Alaafin ti iku baba yeye fi paṣẹ ki wọn wa nnkan ṣe si ilẹ naa.

Àkọlé fídíò, Damilọla Ajayi: Ọ̀dá owó ló ṣún mi dé ìdí lílo ìyarun bíi fèrè

Aṣẹ alaafin lo ṣokunfa kiko awọn katakata nlanla ls si ilẹ naa lati fa awọn igbo naa kuro.

Pupọ awọn olugbe agbegbe naa ni wọn si ti n kan saara si Alaafin Adeyẹmi fun igbesẹ naa eyi ti wọn ni yoo mu ki ọkan awọn balẹ lọjọyipo ninu ile awọn.

Alaafin of Oyo: Kà nípa ohun mẹ́ta tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyemi III àtàwọn olorì rẹ̀

Alaafin atawon olori laafin

Oríṣun àwòrán, Alaafin

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Alaafin tilu Oyo, ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ni ọpọ olori ni aafin, ti ọjọ ori wọn kere jọjọ si ti baba.

Koda, lọwọ lọwọ, o to awọn ẹlẹyinju ẹgẹ, apọnbeporẹ ati orekelẹwa obinrin bii marun-un ti wọn wa ni aafin ọba alaye naa, ti wọn n ṣe abiyamọ, yatọ si awọn olori agba to wa ni aafin tẹlẹ.

Koda, lara awọn ọdọmọde ayaba naa la ti ri awọn bi ibeji, ibẹta fun ọba Adeyemi, ti ọjọ ori rẹ ti le ni ọgọrin ọdun.

Lara orukọ awọn awẹlẹwa ayaba naa ni Olori Memunat Ọmọwumi àti olori Badirat Olaitan Ajoke,

Eyi ni awọn ohun mẹta ti a mọ nipa Iku Baba yeye atawọn olori rẹ laafin

Iku Baba Yeye kii kọnu ifẹ sawọn obinrin

Ni ọdun diẹ sẹyin ti Kabiyesi alaafin Ọys n dahun ibeere kan lori ọgbọn agba ti baba n lo lati kọnu ifẹ sawọn obinrin, esi ti Baba fọ lọjọ naa lọhun ni pe awọn ko fi igba kọọkan kọ ẹnu si obinrin kankan rii.

Gẹgẹbii itan ti Baba sọ lọjọ naa, wọn ni lati ori Olori agba laafin titi dori awsn olori yooku, awọn ko kọ ẹnu si obinrin kọkan ri.

Alaafin atawon olori laafin

Oríṣun àwòrán, Alaafin

Bawo ni baba ṣe wa n ṣe e. Ọgbọn wo ni baba n da si kini ọhun?

Ninu ifọrọwerọ kan ti Kabiyesi Alaafin ṣe pẹlu iwe iroyin abẹle kan ni ọdun diẹ sẹyin, Ọba Layiwọla ṣalaye pe 'Emi kọ ni mo dẹnu ifẹ kọ eyikeyi ninu awọn olori mi.

Nigba to n dahun ibeere naa lati ọdọ awọn akọroyin, Iku Baba Yeye ni oun ko figba kankan kọ ẹnu si awọn ọdọ olori ọhun pe oun fẹ fi wọn ṣe aya.

Ọba Adeyemi ni " Ń ko fi igba kankan kọnu ifẹ sawọn ayaba mi ri, ó wu wọn ni wọn pinnu pe awọn yoo duro ti mi tori emi ni mo n ran wọn lọ sile iwe."

Kabiyesi Alaafin ko fẹ kawọn Olori o fa sẹyin lori ọrọ eto ẹkọ

Alaafin ati olori memunat Adeyemi

Oríṣun àwòrán, olori memunat adeyemi

Pupọ ninu awọn olori laafin Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta, lo jẹ wi pe alaafin funrarẹ lo ran wọn lọ si fasiti.

Eyi kii ṣe ohun to bo rara. Koda Olori Memuna Adeyẹmi funrarẹ sọ eyi gẹgẹ bi ara ọrọ imoore to kọ ṣọwọ si alaafin loju opo Instagram rẹ. Eyi to ni iwe ẹri HND ninu wọn, kabiyesi ni oun ṣi tun ran an pada lọ sileewe giga fasiti.

Alaafin

Oríṣun àwòrán, Alaafin

Ọba alaye naa fikun pe, lẹyin ti wọn pari ẹkọ fasiti wọn, oun ni ki wọn kuro amọ wọn ni awọn yoo duro ti oun bii ayaba

Kabiyesi Alaafin ko fi ọrọ igbeyawo ṣere rara pẹlu gbogbo ẹru ojuṣe to rọ mọ itẹ Alaafin

Alaafin atawon olori laafin

Oríṣun àwòrán, Alaafin

Nigba to n dahun ibeere naa lati ọdọ awọn akọroyin ni ọdun diẹ sẹyin, Iku Baba Yeye ni "Emi kii ṣẹ obinrin tabi yan-an lodi, igbeyawo si jẹ ohun to yẹ ka daabo bo, ẹni kọọkan si lo ni ojuṣe lati ṣe ninu igbeyawo, ọkọọkan awọn ayaba si lo ni ile ti wọn n gbe ni ọtọọtọ."

Alaafin tun salaye pe "Ọlọrun lo fun mi ni abuda ati oore ọfẹ lati ko awọn obinrin jọ, paapaa awọn arẹwa obinrin, emi kii si sọ ọrọ tabi ajọṣepọ emi ati olori kan fun omiran, mo maa n fi ọrọ gbogbo ṣe mẹnumọ laarin ọkọọkan wọn ni."

Ọba Adeyemi tẹ siwaju pe, oun ti kẹkọọ pe oun gbọdọ ko ipa manigbagbe rere ninu aye awọn eeyan, ki oun si jẹ ki ero wọn nipa òun nigba akọkọ jẹ ero rere.

line

Aláàfin Oyo: Kìí ṣe pé ìgbéyàwó èmi àti Aláàfin fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán àmọ́ a tiraka láti jẹ kó láyọ̀-Olori Memunat Adeyẹmi

olori memunat adeyemi

Oríṣun àwòrán, olori memunat adeyemi

Lẹnu ọjọ mẹta yii oniruuru iroyin lo ti jade lati aafin Kabiyesi Alaafin ti ilu Ọyọ eyi to ti mu ọpọ eti gbọn belebele, ṣugbọn lọtẹ yii iroyin tuntun lo tun ṣẹyọ nibẹ.

Ọkan lara awọn olori kabiyesi iku baba yeye, Adeyẹmi, iyẹn olori Memunat ti fohun ranṣẹ si kabiyesi Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta to si n kii ni mẹsan mẹwaa pe lootọ oun ko pe ṣugbọn Alaafin duro ti oun.

O ni lootọ igbeyawo awọn kii ṣe eyi to pe ni gbogbo ọna ṣugbọn oun ati Ọba Lamidi Adeyẹmi ti fi iṣọkan la awọn ipenija gbogbo to n jẹyọ nibẹ ja.

Bi ko ba ni gbagbe, laipẹ yii ni iroyin jẹyọ pe ọkan lara awọn olori laafin Kabiyesi Alaafin ti ko jade laafin eleyi ti aafin iku baba yeye ati olori naa ti sẹ jalẹ pe irọ lasan ni iroyin naa.

Amọṣa lọtẹ, olori Mẹmunat Adeyẹmi, to ti bi ọmọ mẹta fun Kabiyesi ṣalaye ninu ọrọ iwuri to kọ soju opo ikanni Instagram rẹ pe eekan sọrọsọrọ, olukọ ati awokọṣe rere to mu ayipada rere ba igbe aye oun ni kabiyesi Alaafin.

"Ọkọ mi, Alayeluwa Ọba Lamidi Ọlayiwọla Atanda Adeyẹmi kẹta, IKU BABA YEYE. ALAAFIN ILU ỌYỌ. JP CFR LLD SAP

"Ọkọ mi, Alaafin Oyo lo ṣe agbatẹru ẹkọ mi nile iwe, to si n tọ mi sọna lati koju ipenija aye ati ile aye laifọtape.",

mo si n dupẹ fun itọni ati isinileti wọn, ade yoo pẹ lori, bata yoo si pẹ lẹsẹ."

Olorì Memunat Omowunmi Adeyemi, ṣe sadankata si ọkọ rẹ, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta, pe oun ni ọkọ to dara julọ ni agbaye.

Olori Memunat, ẹni to gbosuba fun Alaafin lasiko ayajọ ọjọ ibi rẹ, loju opo Instagram rẹ ni oun n dupẹ lọwọ Ọlọrun to ṣe oun ni oloriire julọ lagbaye nitori bo ṣe fi ọkọ to dantọ da oun lọla.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Olori Memunat wa ṣe apejuwe Alaafin bii ẹni to jẹ awokọṣe rere, olutọnisọna, ọmọwe ati ọlọrọ apọnle.

Olori fikun un pe "Mo tun dupẹ lọwọ ọkọ mi fun ipa to ko lati jẹ ki n bi awọn ọmọ daradara ti Ọlọrun fun mi, mo mọ pe n ko pe, sugbọn wọn duro ti mi digbi lasiko ipenija"

Olori Alaafin tun tọkasi pe loootọ ni igbeyawo oun ati ọba naa kii ṣe eyi to pe julọ, amọ awọn tiraka lati jẹ ko jẹ igbeyawo alayọ, ọkọ oun si ni nkan to dara julọ, ti yoo sẹlẹ si oun, ti oun si n reti lati lo ọpọ ọdun laye pẹlu rẹ.

"Oni ni ọjọ ibi mi, mo si gbadura fun alaafia, ki n bori gbogbo ipenija aye pẹlu irọrun, ki ayọ ati inu didun si jẹ temi."

line
Àkọlé fídíò, Kini Yoru[bá ń pe Necklace?

Coronavirus cases in Nigeria: Láì náání awuyewuye tó ń lọ láàfin rẹ̀, Aláàfin dẹ́rìn ín pẹ̀ẹ̀kẹ́ àwọn èèyàn ìlú Ọ̀yọ́

Alaafin pin ounjẹ loriṣiriṣi fun awọn eeyan rẹ.

Alaafi ObaAdeyemi III atawọn olori rẹ

Oríṣun àwòrán, Alaafi ObaAdeyemi III

Pẹlu bi iroyin nipa ajọṣepọ ohun ati ọkan lara awọn olori rẹ ṣe n ja ranyinranyin lori ayelujara bayii, Kabiyesi iku baba yeye, Alaafin ti ilu Ọyọ ti pin awọn ounjẹ fun idẹrun awọn eeyan ilu Ọyọ lasiko ajakalẹ arun Coronavirus yii.

Alaafin funrarẹ farahan pẹlu ibomu nibi ayẹyẹ naa toun tawọn olori rẹ.

Lara awọn ohun ti wọn pin faraalu ni irẹsi, gaari atawọn ohun jijẹ miran.

Apo gaari ti Alaafin pin

Oríṣun àwòrán, Alaafi ObaAdeyemi III

Ṣaaju eyi, awọn ọbalaye bii Ọọni, Oluwo ati Olugbo ni wọn ti gbe igbesẹ lori igbayegbadun awọn eeyan wọn lasiko Coronavirus yii.

Iya arugbo kan n tẹwọ gba ipin ounjẹ tirẹ

Oríṣun àwòrán, Alaafi ObaAdeyemi III

Coronavirus
Coronavirus

Wasiu Ayinde: Ìkórira pé mo jẹ Mayegun ni wọn ṣe parọ́ pé mo ń fẹ́ olorì Aláàfin, kò rí bẹ́ẹ̀ rá

Wasiu Ayinde ati Alaafin

Oríṣun àwòrán, others

Ọba Fuji, Wasiu Ayinde Marshall, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ si Kwam 1, tí sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí àwọn èèyàn kan fi kàn-án pé, ó ń ní ajọṣepọ pẹ̀lú ọkàn lára àwọn olórí Aláàfin tilu Ọ̀yọ́.

Kwam 1, lásìkò to ń takurọsọ lójú òpó Instagram pẹ̀lú agba ọjẹ akọroyin kan, Dele Momodu, ṣàlàyé pé, irọ lásán ni wọn pa mọ òun.Wasiu Ayinde ni, ìkórira pé òun jẹ Mayegun ilẹ̀ Yorùbá lo mu ki wọn pa irọ mọ òun, ó ní lérò àwọn èèyàn náà, oyè ọhun kò tó sí òun.

Kwam 1 sọ síwájú pé "Nígbà tí wọ́n ko ṣepe fún mi? Èèyàn kan tó jókòó sibi kan ló kan gbé irọ ńlá yìí kalẹ nítorí Ìkórira, kò leè ṣẹlẹ̀ láéláé."

"Gbogbo àwọn olórí bàbá Aláàfin ni n kò ní àǹfààní láti pàdé wọn tẹ́lẹ̀ ayafi ìgbà tí mo jẹ oyè Mayegun ilẹ̀ Yorùbá.

"Ọjọ́ yìí ni ni mo tó fojú rinju pẹ̀lú àwọn olorì, nígbà míràn tí mo tún rí wọn, wọn máa ń wà pẹ̀lú Aláàfin,

Wasiu Ayinde

Oríṣun àwòrán, Wasiu Ayinde

Ìkórira pé mo jẹ Mayegun lo fa wàhálà àti ahesọ ọrọ yìí, tí mo si tún gbọ laipẹ yìí pé, àwọn kan ni òye náà kò tọ́ si mi".

Àkọlé fídíò, Kí ni Yorùbá ń pe ọmọ tí wọ́n bí lẹ́yìn Àlàbá?

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, laipẹ yìí ni ìròyìn gbalẹ kan pé àwọn ènìyàn kan fi esun kan Kwam 1 pé ó ń fẹ́ ọkàn lára àwọn olorì Aláàfin, Ayaba Badira.Nigba tó ń sọ̀rọ̀ lórí ajọṣepọ rẹ pẹlu olóògbé Sikiru Ayinde Barrister àti Oloye Bola Tinubu lórí eto ohun.

Wasiu Ayinde

Oríṣun àwòrán, Wasiu Ayinde/instagram

Wasiu Ayinde ní àwọn èèyàn méjèèjì náà lo ṣe àwárí òun, tí òun fi di òhun ti oun da lónìí.

"Ẹ̀gbọ́n àdúgbò ni Asiwaju Tinubu jẹ si mi.

Mo sì tún máa ń tẹle mama mi lọ sí ọdọ mama wọn ní Mọsalasi Jimoh.

Tí àwọn ìyá wá méjèèjì bá sì ń sọ̀rọ̀, Tinubu yóò rán mi láti lọ ra èédú tí yóò fi lọ aṣọ."Kwam 1 ni lẹ́yìn ìgbà tí òun bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ, tí òun lọ kọrin ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní Asiwaju tún ṣe àwárí òun, tí òun si dara pọ mọ ijija-gbara kan to ń ṣe nígbà náà.

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàfin Ọ̀yọ́?

Ṣé lóòtọ́ ni Aláàfin lé Olorì rẹ̀ tàbí àhesọ ọ̀rọ̀?

Ọpọ ọrọ lawọn eeyan ti n sọ lori ayelujara, ṣugbọn ewo lootọ, ewo ni irọ nibẹ?

Olori Adejoke Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Queenola2

Ni ẹnu lọwọlọwọ yii ni iroyin kan jade si igboro aye pe nnkan n ṣẹlẹ laafin iku baba yeye, Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi III lode Ọyọ.<Story>

Awọn iroyin to suyọ lori ayelujara n sọ pe Iku baba yeye ti da ẹru ọkan lara awọn olori rẹ, Badirat Ajọkẹ, sita.

Ki ree? Ka maa ri o! Ni ohun ti ọpọlọpọ n sọ lori ọrọ naa nigba ti wọn gbọ.

Olori Badirat Adeyẹmi kii ṣe ajeji si ori itakun ayelujara nitori naa nṣe ni iroyin ọhun lalẹ gaaraga.

Ki ni iroyin naa?

Iroyin to n lọ kaakiri ni pe Kabiyesi, iku baba yey ti le olori to kere julọ laafin rẹ, iyẹn Olori Badirat Ajọkẹ kuro laafin lori ẹsun pe o n ṣe aṣemaṣe pẹlu gbajugbaja olorin Fuji to tun jẹ Mayegun ilẹ Yoruba, Wasiu Ayinde Marshal, ti ọpọlọpọ mọ si KWAM 1, K1 De Ultimate.

Ki ni ootọ ọrọ yii?

Aworan Ọba Adeyẹmi Alaafin ati Mayegun ilẹ Yoruba KWAM 1

Oríṣun àwòrán, others

Ko si ẹni to lee sọ ni pato ododo ọr yii gan an.

Amọṣa nigba ti BBC News Yoruba gbe ọrọ kalẹ leti iya Olori Badirat Ajọkẹ Adeyẹmi, ohun ti iya sọ fun wa ni pe ko si ohun to jọ bẹẹ ati pe iroyin ahesọ ni awọn eeyan n gbe kiri.

Bakan naa nigba ti BBC News Yoruba gbe ọrọ naa tọ awọn to yẹ ko mọ nipa rẹ laafin, eeyan kan laafin Kabiyesi Alaafin ilu Ọyọ to sun mọ kabiyesi Iku baba yeye ṣalaye pe ko si nnkan to jọ bẹẹ rara.

Koda o fi da BBC News Yoruba loju pe lọwọ yii, ko soun to jọ bi aawọ laarin kabiyesi ati olori rẹ tabi laarin kabiyesi ati Mayegun ileẹ Yoruba, iyẹn KWAM 1

Ninu atẹjade kan eleyii ti agbẹnusọ fun KWAM 1 , Ọgbẹni Kunle Rasheed fi sita lọjọbọ, irọ lasan ni iroyin naa eleyii ti awsn eeyan kan kan n gbe kiiri lati ba awọn eekan kan lorukọ jẹ.

Abiola Ajimobi: Wo àwọn ìwà tó burú ju àlè yíyàn lọ nínú ìgbéyàwó

Abiola Ajimọbi ati Florence di mọ ara wọn

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi

Nigba ti a fi koko ọrọ yii sita loju opo Facebook wa pe ẹsẹ wo ni ọkọ tabi aya le sẹ ara wọn to le ju agbere lọ, awọn kan lara wọn sọ pe ẹsẹ agbere yii naa ni kọ́kọ́rọ́ to ba eyin aja jẹ lọdọ ti wọn.Diẹ lara awọn idahun wọn niyii:Yetunde Olatile sọ pe ẹsẹ agbere lagbara pupọ debi pe o le tu igbeyawo ka. O gbagbọ pe obinrin to ba n yan aale le fa iku fun ọkọ rẹ.

Bakan naa ni Idowu Bukunmi ni ti ẹ sọ pe ọrọ owo ni. O sọ pe ti owo ba da ọkọ ati iyawo pọ nigba miran, ija le lagbara ju aale yiyan lọ.Fun Morufudeen Olabanjo, iwa ki ọkọ tabi iyawo gbá òbí ẹnikeji l'eti buru ju aale yiyan lọ.Eero ti Nikks Omotoso Bolarinwa yatọ gedegbe. Oun sọ pe iwa to buru ju ni ki ọkọ tabi iyawo gbiyanju lati fi ẹnikeji ṣe ogun owo.Ẹ le ka gbogbo idahun naa ni

Ọpọlọpọ lo gbagbọ pe ti ọkọ tabi iyawo wọn ba yan aale nikan lo le mu wọn binu tabi tu igbeyawo wọn ka, àmọ́ onimọ sọ pe awọn nkan miran tun buru ju u lọ.

Laipẹ yii ni iyawo gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan, Florence Ajimobi sọ ninu fidio kan pe ọpọ igba ni oun ti dari ji ọkọ oun, Abiola Ajimobi, fun ẹsẹ agbere.

O ni sugbọn, oun naa ti hu awọn iwa kan to buru ju agbere lọ.

Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Abiola ajimobi

O mẹnu ba kikọ ile lai sọ fun ọkọ rẹ.

Eyi lo mu ki a ba onímọ̀ nipa irinajo ifẹ laarin ọkunrin ati obinrin, pe kini awọn iwa tabi ẹsẹ to tun buru ju agbere lọ ninu igbeyawo tako igbagbọ ọpọlọpọ pe oun lo buru ju.

Oludamọran naa, Arabinrin Temiloluwa Morohunkeji, ti ajọ Temi Love Clinic, sọ pé ọrọ naa dabi ìlù gangan, nitori pe nkan ti Taye le gba mọ́ra, o ṣeé ṣe ki Kehinde o ma le gba a.

O sọ pe fun ẹlomiran, yiyan ale le ma dùn ún.

Awọn nkan miran to tọka si ni pe ki ọkùnrin mọ pe oun ko le ba obinrin ni ajọsepọ, sugbọn ti ko sọ fun iyawo rẹ ki wọn o to o segbeyawo, to jẹ pe inu igbeyawo ni asiri ti tu.

O miran tun ni ki obinrin o ma ni ile ọmọ tabi ko ma le bímọ, ki oun naa o ma sọ fun afẹfẹsọna rẹ saaju igbeyawo.

Fun awọn kan, iwa ipá ninu igbeyawo ni nkan ti wọn ro pe o buru ju. Ifọti ti tu igbeyawo ka ri.

Abiola Ajimobi ati Florence Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Abiola ajimobi

Nkan miran ti o tun mẹnuba ni ki ọkunrin ko ba ọmọ rẹ obìnrin ni ajọsepọ, tabi aburo ati ibatan iyawo rẹ ni ibalopọ. "Iru eyi tun buru pupọ".

"Ju gbogbo rẹ lọ, ko si nkan ti eeyan ko le foriji, sugbọn eyi ko tumọ si pe irinajo ifẹ naa yoo ri bo ṣe ri tẹlẹ.

Aale yiyan lagbara pupọ, o kan jẹ pe ọpọ ti tẹwọ gba a ni gẹgẹ bi agbelebu.

Obìnrin k'óbìnrin tó bá yan Abiola Ajimọbi l'álè, ajẹ kù mi ló ń jẹ-Florence Ajimọbi

Florence Ajimọbi to jẹ aya gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ti ṣalaye pe igba meji ọtọọtọ loun ti ka ọkọ oun mọ ale yiyan.

Iyaafin Ajimọbi tu kẹkẹ ọrọ yii sita lasiko to fi n ba ọmọ rẹ obinrin sọrọ lori fidio kan to n ja ranyinranyin bayii lori ayelujara.

Gẹgẹ bi ọrọ ti Florence Ajimọbi sọ, ko si ohun meji ti ọkunrin n ri nidi ale yiyan ju ibalopọ lọ, bi wọn ba si ti ni ibalopọ naa tan, ọrs pari niyẹn ọkan wọn kii si pẹlu ẹni ti wọn n yan lale.

Florence Ajimobi ati ọkọ rẹ Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi

Arabinrin Ajimọbi ni, "Igba kan si meji ni mo ti ba ọkọ mi to n yan ale, yoo si tọrọ aforiji lọwọ mi, ni kete to ba si ti bẹ mi, o tan niyẹn mi o kii ro arokan lori rẹ tabi fi sọrọ sii mọ. Mi o ṣe bẹẹ ri Bisọla nitoripe mo mọ pe ko si ẹda kan ti kii ṣẹ Ọlọrun lọba alaforiji.

Florence Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi

"Ọrẹ ni wa. Koda gẹgẹ bi iyawo, emi naa maa n ṣe aṣiṣe, lọpọ igba aṣiṣe bẹẹ gan yoo buru ju ki eeyan yan ale lọ."

Nigba ti wọn bii pe iru aṣiṣe wo lo ju ale yiyan lọ, aya gomina ana nipinlẹ Ọyọ Abiọla Ajimọbi naa fesi pe ọpọ awọn obinrin lo n da ile kọ lẹyin ọkọ wọn, eyi buru pupọ. Ki lo de ti waa fi ṣe iru nnkan bẹẹ lai sọ fun un? oniruru nnkan ni a n ṣe ti o buru. Kii ṣe ale yiyan.

Abiola Ajimọbi àti Florence Ajimọbi

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi

O wa fi kun un pe bi obinrin ba ka ọkọ rẹ mọ ale yiyan, ko daarijii ko si gbagbe ni o.

O ṣalaye pe bi ọpọ ọkunrin ba nyan ale nitori ati ba obinrin bẹẹ lajọṣepọ ni kii ṣe nitori ifẹ ati pe ibalopọ laarin ọkunrin ati obinrin to ba fẹ sile a maa yatọ

O ni ajẹku ẹba ni obinrin to n ba ọkọ oun sun n jẹ nitori oun gangana lo ti jẹ ogidi ẹran ara rẹ tan.

Afikun nipa aarun Coronavirus
Banner