Gbogbo nkan nipa coronavirus
Ibeere yin
Skip Gbogbo nkan nipa coronavirusCoronavirus jẹ ajakalẹ arun ti wọn ri ni China ni oṣu kejila, ọdun 2019 ti wọn n pe ni Covid- 19
O le ni ọgọrọọrun oriṣii coronavirus- ni eyi ti o wọpọ laarin ẹranko bii: ẹlẹdẹ, rakunmi, adan, ati olongbo. Ṣugbọn diẹ lo n nipa lara eeyan bii ti Covid 19 yii
Awọn coronavirus kọọkan maa n fa ailera ti ko lagbara pupọ bii ọfinkin, iba ṣugbọn ti Covid 19 lagbara pupọ lati fa ailera nla bii otutu aya Niumoníà
Awọn to ba ti kagbako rẹ le ni awọn apẹrẹ bii iba, ara riro paapaa tọwọtẹsẹ ati ikọ. Ni eyi to ṣeeṣe lati gbadun lai lọ fun itọju àrà ọtọ kankan

Awọn arugbo ati awọn to ni ailera ni ara wọn tẹlẹ biiaisan ọkan, itọ ṣuga, arun jẹjẹrẹ lo ṣeeṣe ki o pa lára julọ
Nigba ti ara awọn eeyan ba ti ya tán, awọn ohun eelo ija kan a ṣi ṣẹku ni agọ ara wọn lati gbogun ti irufẹ ikọlu naa sii
Awọn eroja igbogun ti ni agọ ara kii ṣe titi aye nitori pe o le dinku ni agbara ti ọjọ ba ṣe n pẹ sii
Ti o ba ti ni coronavirus, ara rẹ yoo maa ja fun ẹ nitootọ ṣugbọn a ko tii mọ odiwọn igba ti agọ ara ẹ le ja fun mọ lẹyin igba akọkọ too ni coronavirus

O kere tan, Ọjọ marun un ni ami coronavirus a bẹrẹ si ni farahan lara eniyan. ṣugbọn awọn onimọ sayẹnsi ni omiran le tete ni apẹrẹ

Ajọ eleto ilera agbaye, (WHO) gba imọran pe o ṣeeṣe ko pe ọjọ mẹrinla lara ni eyi ti iwadii ni o le to ọjọ mẹrinlelogun
O ṣe pataki lati mọ iwọn asiko ti o fi le duro lara ko to fojuhan. Asiko yii lawọn dokita ati eleto ilera fi le gbe igbesẹ ki arun naa ma baa tan kalẹ
Aisan mejeeji jẹ ajakalẹ arun
o kere tan, eeyan meji si mẹta le ko coronavirus lara ẹni to nii nigba ti ẹni kan le ko otutu igba ọginiti lara ẹni to nii
Awọn igbesẹ to rọrun wa too le gbe lati dẹkun itankalẹ coronavirus
Lara awọn eeyan mẹrin ninu marun un awọn to ni Covid- 19 ko ni mọọ lara pupọ, o kan maa dabi otutu lasan lara wọn
Diẹ lara àmì ẹ ni iba, ikọ ẹgbẹ ati ailera fun ọjọ diẹ ti waa si gbadun laarin ọsẹ kan ti awọn apẹẹrẹ yii yoo lọ
Ti o ba ti wọ ẹ lara ni yoo kọle si inu ẹdọ-fooro rẹ nibi ti yoo ti jẹ ki eemi mimi rẹ ko nira pẹlu otutu aya. ẹni kan ninu eniyan meje maa nilo itọju ile iwosan bayii














