Coronavirus tips: Kí ni a ń pè ní fẹntilétọ̀ àtipé kí ni pàtàkì rẹ̀?

fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí

Oríṣun àwòrán, dyson

Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí pé fún rírà ẹgbẹ́gbẹ̀run ẹ̀rọ fẹntíletọ̀ láti mú irọ̀rùn bá àwọn ilé ìwòsàn nítorí wàhálà ààrùn Coronavirus tó ń bá àgbáyé fíra.

Fún ẹni tí ààrùn Coronavirus bá bá jà gidi, Fẹntíletọ̀ nìkan lọ́nà àbáyọ láti lè jẹ kí òní anfaani yíyè.

Kini a ń pè ní Fẹntílàtọ̀ àti pé kí ni iṣẹ́ rẹ̀?

Ní kúkúrú, Fẹntíletọ̀ lọ máa ń gba isẹ́ mímí ṣe nígbà tí àìsàn bá ń bá ẹ̀dọ̀ fòòró ja tí kò sì lè ṣe ojúṣe rẹ̀ mọ́.

Èyí ni yóò fún aláìsàn ni àǹfààní láti bá aarun náà já títí tí ara yóò fi bọ̀ sípò.

Onírúurú Fẹntíletọ̀ lọ wà nínu ìṣẹ́gùn òyìnbó.

1. Ohun elo aṣeranwọ eemi to n lo ẹrọ

2. Ohun elo aṣeranwọ eemi ti ko nilo ati ti bọ inu ara

ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí fẹntilétọ̀

Gẹ́gẹ́ bí àjọ elétọ̀ àbò àgbáyé (WHO) ṣe sọ ìdá ọgọ́rin àwọn ènìyàn tó ní ààrùn Coronavirus ni kò nílò láti dé ilé ìwòsàn kí ara rẹ̀ tó dá.

Ṣùgbọ́n ẹ̀yán kan nínú mẹ́fà ni yóò ṣe àìsàn gidi ti yoo si nira fún wọn láti mi.

eeyan kan n tẹ ẹrọ fẹntiletọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nínú irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó lágbára bayii kòkòrò aifojuri yìí le ba ẹ̀dọ̀ fòòró jẹ́. Ní kété tí èròjà ara tó bá àìsàn ja bá ti rí èyí yóò fi ààyè gba àwọn èròjà tó kú láti kó ọmọ ogun wọlé láti dáàbò bo ara.

Ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ yìí leè kí omi máa wo inú ẹ̀dọ̀ fòòró èyí sì lọ máa ń fà tí èémí yọ fi nira fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ tó ń wọ ara yóò sì dínkù.

Láti wá mú èyí kúrò, ẹ̀rọ Fẹntílàtọ̀ yìí ni wón ń lọ láti gbé afẹ́fẹ́ wọ inú ẹ̀dọ̀ fòòró.

Fẹntílàtọ̀ yìí bákan náà ni afẹ́fẹ́ kosooru-kosotutu tí yóò máa fẹ́ gbígbóná sínú afẹ́fẹ́ ìsẹ̀gùn láti lè bá àgọ́ ara ènìyàn mu.

Eeyan kan

Oríṣun àwòrán, Intersurgical

Àwọn tí ó bá jẹ pé àmì tiwọn kò nira jú wọn lé máa fi ìbòjú-bomu Fẹntílàtọ̀ mí niti wọn.

Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ London College tí bá wọn onimo miran tó ń ṣe Mercedes ti wọn n se (CPAP) rí wọn pé ní Continuous Positive Airways pressure Device po tí wọn sì ti lọ làwọn ilé ìwòsàn kan tó sì ń ṣe iṣẹ́tó yẹ. Ilé ìṣe náà yoo

bere si ki ṣe egberun kan rẹ ni ojúmọ́ láti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ lọ (6 April).

Àjọ tó ń mójú tó ìsẹ̀gùn àti àwọn irinsẹ ìsẹ̀gùn tí jan ẹ̀rọ CPAP lọ́ntẹ̀

Afikun nipa aarun Coronavirus
Banner

Ẹ̀wẹ̀ ọ̀pọ̀ lọ ní àríwísí lórí lílo Fẹntílàtọ̀ onibòjú-bomu nitoripe tí ihò kan bá si sílẹ̀ tí aláìsàn sì wúkọ́ èyí lè tá sì ọ̀sìsẹ́ ìlera lára kí ó sì kó aarun náà.

Irú Fẹntílàtọ̀ yii ni wọn ń pè ní Non-invasive Ventilation nítorí pé wọn tí nkan kan bọ ẹni náà lọ́fun.

Ẹ̀wẹ̀ àwọn elétò ìlera yóò tètè fún ẹni tó bá nira fún láti mi ni Fẹntílàtọ̀ kí a dinku máa bà bá afẹ́fẹ́ tó ń wo inú ara.

Fẹntíletọ̀ melo ni gbogbo ilé Gẹ̀ẹ́sì ni ati pe mélòó lọ yẹ kí o wà?

NHS sọpe egberun mejo lè díè ni Fẹntílàtọ̀ to wà sugbon wọn gbìyànjú láti ra kun ni kíákíá.

Ijoba nígbàgbọ́ pé nígbà tí àjàkalẹ̀ ààrùn náà bá dé góńgó àwọn yóò nílò tó ọgbọn ẹgbẹ̀rún Fẹntílàtọ̀, wọn tí pé fún àwọn egberun mewaa tuntun míràn lat ilé ìṣe Dyson.

Dyson sọ fún BBC pé àwọn ń sise lori awon eya tí ó wà nílè ṣùgbọ́n awon yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ si ni gbedi rẹ láti ilẹ̀ ni.

Bákan náà ni wọn ti pé fún rírà lati ọdọ Luton Smith group èyí yóò sí jẹ eya kelebe.

fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
Àkọlé àwòrán, fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí

Ilé ìṣe ilé Geesi miran Gtech tí ṣe irú rẹ miran ti kí ni nílò afẹ́fẹ́ ile iwosan tí kò sì nílò iná mọ̀nàmọ́ná..

Bákan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn àgbáríjọ onímò sáyẹ́nsì àti onímọ̀ ẹ̀rọ láti ilé ìwé Oxford àti King's College London náà tí ṣe àfılọ́lẹ̀ Fẹntílàtọ̀ olówó pọ́ọ́kú tiwọn, èyí tí wọn ní àwọn lè bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe rẹ̀ ni kíákíá.

Àwọn àṣẹ wádìí ni Fáṣítì East Angellia náà ń wá onímọ̀ 3D láti ṣe Fẹntílàtọ̀ àti ìbòjú-bomu pelu gbogbo àwọn irinsẹ míràn.