Coronavirus: Ìjọba London ti da ọlọ́pàá sí ìgboro láti mú ẹni tó bá ń rìn gbéregbère

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Ìjọba London ti da ọlọ́pàá sí ìgboro láti mú ẹni tó bá ń rìn gbéregbère

Ọmọ Naijiria kan to n fi ilu London ṣebugbe, Oladimeji Solomon ti ṣalaye bi igboro ṣe da paroparo nilu na nirotoi ajakalẹ arun Coronavirus to wa lode.

Solomon sọ fun BBC ninu fidio yi pe ọpọlọpọ awọn olugbe ilu London lo ti joko sile wọn bayii lẹyin ti ijọba ilẹ naa kede ofin konile o gbele, to si ti ile iwe, ile ijọsin ati awọn ileeṣẹ kan pa.

Bo tilẹ jẹ pe ọkọ akero si n ṣiṣẹ nigboro, ko dabi ti atẹyinwa ki arun Coronavirus naa to bẹ silẹ nitori ṣe ni gbogbo titi da paro.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọpọ owo nji ijọba ilẹ ọhun ti padanu nitori awọn eeyan ko san owo ori lasiko yi latari pe wọn ko lọ sibi iṣẹ oojọ wọn.

O ṣafihan ibudokọ ọkọ oju irin ti ọpọ eeyan ma n wọ tẹlẹ, ṣugbọn ti ko si awọn to n wọ mọ.

Solomon ni ijọba ilẹ UK ti da awọ ọlọpaa sigboro lati fi pampẹ ofin mu ẹnikẹni ti wọn ba gbamu pe o rin irin ti ko lalaye.