Coronavirus: Ohun tó ṣì ṣókùnkùn sí ìgboro ayé nípa àrùn Covid-19

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, James Gallagher
- Role, Health and science correspondent
Niṣe ni ọrọ naa jọ bi ẹni pe ati ogun ọdun la ti n ba bọ ṣugbọn ko ju oṣu Kejila ọdun 2019 to kọja ta bẹrẹ si ni jẹ ọrọ Coronavirus lẹnu.
Toun ti akitiyan awọn onimọ sayẹnsi jakejado agbaye,diẹ lohun ta mọ nipa arun yi ti gbogbo aye si ti wa n ṣakitiyan lati wa idahun si ibeere to mu wa.
Diẹ re e lara awọn ibeere ti o fakọyọ nipa arun Coronavirus


Eeyan meloo ni o ti lugbadi arun yi
Ibeere kan to jọ pe ko le ṣugbọn eleyi to si ṣe pataki nipa arun yi leyi jẹ
Jakejado agbaye lati ka nipa ọkẹ aimọye eeyan to ko arun naa ṣugbọn lotitọ,diẹ leleyi jẹ lara awọn to ni gaan.
Ohun miran to tun dakun darudapọ nipa iye eeyan to ni ni pe awọn mi ti arun yi mu wọn ko fi apẹrẹ han-awọn wọn yi ni arun naa ṣugbọn wọn ko ṣaare .
Ti awọn onimọ ba ri ayẹwo to poju owo ṣe lati mọ ni to ni arun yi eleyi yoo ṣe anfaani to pọ lati mọ bi arun naa ṣe n tan kaakiri si.
2.Bawo ni arun yi ṣe loro si

Bi a ko ba mọ iye eeyan to ni arun yi,yoo ṣoro ki a to le sọ iye awọn to padanu ẹmi wọn lọwọ arun yi.
Lọwọlọwọ, a gbọ pe ida kan ninu ọgọrun awọn to ko arun naa lo gba ibẹ ku.
Ṣugbọn ti imọ nipa awọn ti ko ba fi apẹrẹ arun yi han ba pọ si, o ṣeeṣe ki a mu adinku ba iye awọn to ku latari arun Coronavirus.
3. Ki lawọn apẹrẹ ti a fi n da mọ
Eyi to jẹ ojulowo apẹrẹ arun yi ta mọ ni ara gbigbona ati ikọ
Lawọn ibi kan apẹr bi ki ọna fun ma dun eeyan, ori fifọ tabi yiya igbẹ gburu naa a ma farahan ti awọn kan a si ma ni eeyan ko ni le gborun nnkan daada.
Ibeere to ṣe koko ni pe njẹ apẹrẹ diẹdiẹ tabi eleyi to farajọ otutu bi ki eeyan ma sin tabi ko ma yọ ikun nimu a ma farahan lara awọn alaisan kan.
Iwaadi ti fi han pe o ṣeeṣe ki awọn eeyan ni arun yi lara lalai mọ ti eleyi si ni ewu pupọ.
4.Ipa ti awọn ọmọde n ko ni itankalẹ Coronavirus.
Ko si ani ani pe awọn ọmọde le ko arun Coronavirus .
Amọ,apere arun naa diẹdiẹ ni wọn ma n ṣe afihan ti ko si wọpọ pe ki awọn ọmọde gba ti ọwọ arun yi lọ niafiwe ti awọn eeyan ọjọ ori toku.
Awọn ọmọde a ma tan arun yi kaakiri nitori pe wọn a ma ba awọn ọmọ miran ṣere ṣugbọn a ko ti le sọ boya wọn ṣalabapin kokoro arun yi fẹlomiran.

Oríṣun àwòrán, Science Photo Library
5. Nibo ni ó ti wá gan:Kòkòrò aifojuri Corona jáde láti ìlú Wuhan, ní China ni opin ọdún 2019 nigbati onírúurú rẹ ń jeyo laarin awọn ènìyàn nínú ọjà kan tí wón ti ń tà nkan ọ̀sìnAarun tí wọn koko npe orúkọ rẹ ni Sars-Cov-2 fara pé kòkòrò aifojuri tí wọn rí lára àdán, èwe, wọn ní gbagbọ pé kòkòrò náà tí ara àdán bo si ara ẹranko miran ti o fi wá dé ara ènìyàn.Àlàfo àárín yìí sí jẹ ohun tó suniloju di asiko yii èyí sì lè ṣokùnfà aarun miran.
6. Bóyá Aarun náà yóò dín kù lásìkò erun(Summer)Ofinkin má ń wọ́pọ̀ lásìkò òtútù ju asiko èérún lọ, sugbon a kò tíì mọ bóyá ìtàn kalẹ rẹ yóò dín kù tó bá di igba ẹẹrun.Olubadamoran ijoba ile Geesi tí gba ìjọba nimoran pé àwọn kò tíì tlri àrídájú bóyá aarun tó ń bá ìgbà rìn ni, tó bá jẹ́ àsìkò lọ ń bá ṣe ó túmọ̀ sí pé nkan tó kéré sì kata àti ofinkin ni.
7. Kí ló dé tí àpẹrẹ tó fi hàn fún àwọn kan lágbára jù tí àwọn míràn lọÀàrùnCovid-19 kii se nkan tó nira fún ọ̀pọ̀ ènìyàn rárá. Ẹwẹ̀, ìdá ogún lọ padà wá ń tún ní ìpèníjà tó pọ̀. Kíni ìdí rẹ?Ipò tí àwọn èròjà tó ń jà fún ara bá wà ṣe pàtàkì lori oro aarun a Coronavirus, tí ó bá seese fún wọn láti gbógun ti aarun náà ti wọn si se àṣeyọrí, bákan náà ni ó nise pelu ara ẹni tí ènìyàn tí jáde, tí òye yìí bá yẹ àwọn ènìyàn, yóò ṣe iranwo láti mọ àwọn tí wọn dabo bo ara wọn láti má lè yọjú sì ipele tí ó lágbára nílé ìwòsàn.8. Ìgbàwo ni èròjà tó gbógun ti àìsàn lára lè ṣiṣẹ́ dá, àti pé bóyá ó lè ní ààrùn náà ni ẹ́ẹmèjì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Onírúurú aheso lọ tí wá sugbon peleu ẹri péréte lórí bí èròjà tó gbógun ti àìsàn ṣe lè ṣíṣe pé tolati gbógun ti aarun náà.Aláìsàn gbodo tí ni èròjà ara to ń gbogun ti ààrùn, ti wọn ba se àṣeyọrí láti bá aarun náà ja. Sugbon óò, asiko ti aarun náà lọ kò tíì pé, èyí kò sì lè jẹ ki a ní àwọn àkọsílẹ̀ tó dájú. Ọ̀rọ̀ tí kò fìdí múlẹ̀ ni pé àwọn kan tó ti gba ìwòsàn tún padà ní aarun náà, a lè sọ pé bóyá ayẹwo tí wọn koko ṣe ni kò múná doko tó kí wọn tó sọ pé wọn kò ní aarun náà mọ.Ìbéèrè nípa èròjà ara ro gbógun ti aarun ṣe pàtàkì tí òye rẹ bá yẹ ni èyí sì ni yóò sọ nkan ti yoo sẹlẹ tí ẹni náà bá ní aarun.9. Bóyá àrùn náà yóò tún yà irú òmírànGbogbo àwọn kòkòrò aifojuri lọ má ń tú gbile sí irú òmíràn ni gbogbo igba, sugbon awon iyato tí wọn ní yìí kii sábà farahàn tó bẹ́ẹ̀.Gégé bí ìlànà tó, ìwòye ni pé kí àwọn kòkòrò aifojuri yìí kò dinku nínú agbára rẹ kì í sì má lè pá ènìyàn mo ti bá ya ṣùgbọ́n kò sí afọwọ́sọ̀yà pé.Nkan ti o wa kan ni lominu ni pé tí kòkòrò na bá tún yà irú òmíràn, èròjà tó ń gbógun ti aarun lára kò ní damọ̀ mọ́ àwọn abẹ́rẹ́ tí wọn tí pèsè fún náà kò ní ṣıṣẹ́ mọ (Gege bí ó ṣe rí pelu ofinkin)
Ilu Wuhan ni China lo ti jẹyọ niipari ọdun 2019 nibi ti a ti ri awọn iṣẹlẹ arun naa lọja lekulẹja nibẹ.
Coronavirus ti orukọ rẹ n jẹ Sars-CoV-2,sunmọ kokoro aifojuri to n ba awọn adan finra amọ igbabọ ni pe lati ara adan si ẹrank miran lo gba ki o to de ara awọn eeyan.
Ọna to gba yi ṣokunkun ti o si ṣeeṣe ki o jẹ ọna tawọn ẹlomiran yoo fi ko arun yi.














