Coronavirus Update: Olóòtú Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Boris Johnson ti kó àrùn Coronavirus!

Britain"s Prime Minister Boris Johnson speaks during his first remote news conference on the coronavirus disease (COVID-19) outbreak, in London, Britain March 25, 2020

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba Ilẹ Gẹẹsi ni Olootu ijọba Ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson ti ko arun Coronavirus.

Downing Street to fi lede ni Johnson n fi apẹrẹ diẹdiẹ han pe o ni arun naa lara, ti o si ti wa ni ahamọ ni ile rẹ bayii.

Atẹjade ti wọn fi lede sọ wi pe lẹyin ti Olori ẹka eto iwosan ni Ilẹ Gẹẹsi, Ọjọgbọn Chris Whitty gba a ni imọran lo lọ ṣe ayẹwo ara rẹ naa.

Afikun nipa aarun Coronavirus
coronavirus

Atẹjade naa fi lede pe Arakunrin Johnson ni yio si ma a ṣẹ akoso ijọba, ati igbogun ti arun Coronavirus.

Ọgbẹni Johnson sọ pe oun ṣafihan apẹrẹ arun naa bii ara gbigbona ati ikọ lati nkan bi wakati mẹrinlelogun ṣeyin.

Ninu fidio kan to fi lede loju opo Twitter, o ni "Mo ti bẹrẹ si n ṣiṣẹ lati ile mi bayi, mo si ti ya ara mi sọtọ fun itọju gẹgẹ bi ohun to tọ lati ṣe lasiko yi."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Àkọlé fídíò, Njẹ Chloroquine nipa kankan lati le koju Coronavirus

Lalẹ Ọjọbọ ni ọgbẹni Johnso darapọ mọ awọn ara ilu lati fi ẹmi imore han si ileeṣẹ eto ilera ilẹ naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ti ṣẹ fun awọn to ni arun naa.

A ko tii le sọ boya ọgbẹni Johson yo ṣi ma gbe papọ pẹlu afẹsọna rẹ, Carrrie Symond to wa ninu oyun lọwọ yii.

Yatọ si Johsnon, awọn eeyan nla mii to ti fara kaasa arun Coronavirus nilẹ Gẹẹsi ni ọmọ Ọba ilẹ Wales ati ọmọ Ọba ilẹ Gẹẹsi, Charles.

Ni bayii, o le ni ẹgbẹrun mọkanla awọn eeyan to ti ni Coronavirus nilẹ Gẹẹsi, ti awọn to le ni ẹẹdẹgbẹta si ti jẹ Ọlọrun nipe.

Ìtànkálẹ̀ àrùn Coronavirus nílẹ̀ Amerika ti ju ti Italy àti China lọ!

Ilẹ Amẹrika ma ti gba ipo kini gẹgẹ bi orileede ti itankalẹ Coronavirus ti poju lọ lagbaye pẹlu eniyan to le ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínláádọ́rún to ti ni arun naa.

Àkọlé fídíò, Iye èèyàn tó ní àìsàn náà níbẹ̀ ti kọjá ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínláádọ́rún, àmọ́ iye èèyàn tó kù níbẹ̀ kò tó ti Italy ati China

Akọsilẹ fihan wi pe orilẹede Amerika ti bori China to ni ẹniyan to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrin (81,782) ati Italy to ni eniyan to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrin(80,589) to ni arun naa.

Amọ iye awọn eniyan to ti ku ni orileede China to le ni ẹgbẹrun lọna mẹta (3,291)ati ti Italy ẹgbẹrun lọna mẹjọ (8,215)pọ ju ti orilẹede Amerika to le ni ẹgbẹrun kan lọ (1,300).

Itankalẹ arun yii peleke si lẹyin ti Aarẹ Donald Trump sọ wi pe o da oun loju pe orilẹede naa yoo pada si ipo laipẹ.

Aarẹ Donald Trump lasiko to n fesi si ọrọ naa ni idi ti nọmba awọn to ni arun naa fi peleke si ni pe awọn n se ayẹwo fun awọn eniyan loju mejeeji lo jẹ ko ri bẹẹ.

Igbakeji aarẹ orilẹede Amerika, Mike Pence sọ wi pe ẹgbẹgbẹrun ile iwosan ayẹwo lo ti wa ni gbogbo ipinlẹ aadọta to wa lorilẹede naa.

Ọsẹ̀ mẹ́ta gbáko lorílẹ́èdè South Afrika yóò fi wà lábẹ́ òfìin kónílé-ó-gbélé

Awọn ileeṣẹ ologun lorileede South Afrika ti bẹrẹ si ni fi ofin konileogbele ọlọsẹmẹta mulẹ lọna ati fopin si itankalẹ arun Coronavirus.

Lilọ bibọ pata ni ofin yi lọdi si, yatọ si awọn to ba n ṣiṣẹ koṣemani ti awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun si ti wa ni ṣẹpẹ lati fi ofin na rinlẹ.

Awọn ọlọpaa ni South Afrika ti bẹrẹ si ni mu awọn to tapa si ofin yi

Oríṣun àwòrán, AFP

Ṣaaju ki ofin naa to gberasọ ni oru ọjọbọ,niṣe ni awọn ile itaja kun fọfọ ti awọn eeyan si n sare ra ọja witiwiti.

Coronavirus

Lorileede South Afrika, eeyan ẹtadinlọgbọnlelẹẹdẹgbẹrun ni o ti ni aisan naa eleyi to pọjulọ ni Afrika.

Ko i ti si eeyan kankan to ku ni ilẹ naa latari aisan naa.

Aworan aarẹ Ramaphosa

Oríṣun àwòrán, EPA

Lalẹ Ọjọbọ ni a ri aarẹ Cyril Ramaphosa nibi to ti ṣe abẹwo si awọn ọmọ ogun ni ibudo wọn to wa ni Soweto.

Ijọba ti kilọ pe ẹnikẹni to ba tapa si ofin konileogbele yoo fi ẹwọn oṣu mẹfa jura.

Labẹ ofin naa, awọn ile itaja to ba n ta ounjẹ nikan ni wọn yoo ṣi kalẹ ti wọn si ti wọgile tita ọti.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Fífi nkan bó ìmu nìkan kò le dènà kíkó coronavirus

O sọ fun awọn ọmọ ogun ilẹ naa pe ''mo ran yin jade lati lọ daabo bo awọn eeyan wa lọwọ Coronavirus ni''

''Ohun ti ko ṣẹlẹ ri ni ninu itan ilẹ wa pe ki a deju awọn eeyan mọlẹ fun ọjọ mọkanlelogun lati lọ doju ija kọ ọta ti a ko fi oju ri''