Coronavirus: Ọ̀ọ̀ni jẹ ọkùnrin Rwanda kan tí kò pa òfin kónílé-ó-gbélé nítorí coronavirus mọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkunrin kan to kọ lati tẹle ofin konile o gbele ti ijọba orilẹ-ede Rwanda fi sita nitori itankalẹ aarun coronavirus ti kagbako iku ojiji.
Ọkunrin naa fi ile rẹ silẹ, o si lọ si odo lati pa ẹja, ṣugbọn ọọni sọ ọkunrin naa di ounjẹ.
Olori agbegbe Gusu Kamonyi ti iṣẹlẹ naa ti waye, Alice Kayitesi sọ fun BBC pe owurọ Ọjọbọ ni iṣẹlẹ buruku naa ṣẹlẹ ni odo Nyabarongo.
"O kọ lati tẹle ofin ijọba pe ki olukulu joko sile rẹ, o wa lara awọn eniyan diẹ ti ko pa ofin naa mọ, lati dena itankalẹ coronavirus."
Ọjọ aiku to kọja ni awọn alaṣẹ ni Rwanda paṣẹ pe ki gbogbo nkan o dawọ duro, nitori bi awọn to ni arun naa ṣe n pọ si i.
Ogoji eniyan lo ti ni coronavirus ni Rwanda.
Bi ijọba ṣe f'ofin de eto ọrọ aje ti ṣe akoba nla fun ọpọ eniyan ti ko fi ii bẹ ri taje ṣe.
Bakan naa ninu iroyin miran, a gbọ pe awọn ọlọpaa yinbọn pa ọkunrin meji ni agbegbe Nyanza lẹyin ti wọn kọ lati tẹle ofin naa.
Ṣugbọn, ileeṣẹ ọlọpaa ko ti i sọ nkankan nipa ẹsun naa.
Ọmọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Charles ti ní aàrùn coronavirus

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọmọ ọba ilẹ Gẹẹsi, to tun jẹ ori-ade ilu Wales, Charles naa ti ni aarun coronavirus.
Agbẹnusọ fun aafin ọba ilẹ Gẹẹsi ṣalaye pe ilera Charles ẹni ọdun mọkanlelaadọrin si wa daadaa.
Bakan naa, Ọmọbabinrin to jẹ iyawo rẹ, naa ṣe ayẹwo, amọ ayẹwo fihan pe ko ni aarun naa
- Mò ti ya ara mi sọ́tọ̀ bí mo ṣe dé láti America nítorí coronavirus- Soyinka
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ni ki gbogbo ọjà wà ni títì pa, sùgbọ́n...
- O ti di ènìyàn Mẹrinlelógóji to ti ni ààrun Coronavirus ni Naijiria
- Èṣi àyẹ̀wò jáde, Gómìnà Bauchi ti ní aàrùn coronavirus báyìí
- Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Nàìjíríà kó igbá wọlé l'Abuja nítorí coronavirus
Tí a bá ní káwọn èèyàn jókòó sílé nítorí coronavirus, ebi àti olè jíjà ma pọ̀- Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́
Ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria, ijọba ipinlẹ Eko atawọn ijọba ipinlẹ mii ti kede pe kawọn oṣiṣẹ lati ipele kinni si ekejila joko sile wọn nitori aarun coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eyi jẹ ọna kan lati dena itankalẹ arun naa eyi to ti mu eeyan mẹrinlelogoji bayii ninu eyi ti ẹnikan ti di oloogbe ti awọn meji si ti kuro nile iwosan lẹyin ti wọn gbadun tan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ọpọ awọn ijọba orilẹ-ede agbaye lo ti kede pe ki awọn eeyan joko sile nitori arun naa ṣugbọn ṣe ijọba Naijiria naa le gbe iru igbesẹ yii?
Onimọ nipa ọrọ aje, Bisi Iyaniwura to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye ofin konile o gbele le ma ṣiṣẹ ni Naijiria nitori iṣẹ oojọ lọpọ ọmọ Naijiria n ṣe.
Iyaniwura ni ọna to dara lati dena itankalẹ arun covid-19 ni kawọn eeyan maa joko sile, ṣugbọn ''ti a ba ni kawọn eeyan joko sile ni tootọọ, kinni wọn o maa jẹ?''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Jijoko sile lọrọ coronavirus ba de ṣugbọn ẹni ebi n pa ko gbọ Anago,'' Iyaniwura ni lẹyin ebi to maa pa awọn eeyan, jijoko sile le mu ki ọpọ maa jale.
Ọgbẹni Iyaniwura fikun ọrọ rẹ pe iwadii ti fihan pe ida ọgọrin ninu ọgọrun un awọn ọmọ Naijiria lo n ṣiṣẹ oojọ, eyi tun maa jẹ ki o nira lati sọ fawọn eeyan pe ki wọn joko sile.
O ni ti ọpọ ọmọ Naijiria ko ba lọ si ibi iṣẹ fun ọjọ kan, ko si ohun ti wọn fẹ jẹ.
Iyaniwura ni jijoko sile yoo pa ọrọ aje Naijiria lara nitori owo epo to jẹ ọrọ aje Naijiria ti lọọlẹ.
O sọ pe eyi gan an lo maa jẹ ki ijọba Naijiria naa maa ro daadaa ki wọn to le gbe igbesẹ naa.
















