Coronavirus: Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Nàìjíríà kó igbá wọlé l'Abuja nítorí coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile igbimọ aṣofin Naijiria ti kogba wọle nilu Abuja to jẹ́ olu ilu Naijiria nitori coronavirus to gbode kan.
Alhaji Ahmad Lawan to jẹ abẹnugan ile igbimọ aṣofin ni Abuja lo ṣiṣọ loju ipinnu gbogbo ọmọ ile yii nilu Abuja lonii.
O ni igbesẹ yii di dandan lati gbe lasiko yii lataari aarun coronavirus to ti le ni ogoji eeyan to ti lugbadi ẹ ni Naijiria bayii.
O rọ awọn eniyan Naijiria lati gbọran si aṣẹ ajọ NCDC lẹnu ki onikaluku yan imọtoto laayo bayii.
Èrò wìtì-wìtì lọ́jàa Dugbẹ, Bodija, Orita-Challenge láì náání Corona Virus ní Ibadan
Corona Virus in Nigeria: Buhari: Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ní kí àwọn òṣìṣẹ́ grade 1 sí 12 jókòó sílé

Aarun COVID-19 ti di tọrọfọnkale bẹẹ sini o ti lu ọpọ ẹmi pa, ṣugbọn bi aarun yii ṣe lewu to, ọpọlọpọ awọn eeyan ni ko tii fi bẹẹ mu imọtoto ara ẹni ati yiyago fun ọpọ ero nigboro lọkunkundun.Abẹwo ti ikọ iroyin BBC ṣe si igboro ilu Ibadan fi han wi pe ewu n bẹ loko longẹ Wo bí àwọn ará Ibadan ṣe ń ṣe lásìkò Corona Virus yìí
Aṣẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ pa lori ẹdinku ti o yẹ ki o ba iye ero ti awọn ọlọkọ ati ọlọkada n gbe ko tii walẹ.Alaye awọn ọlọkada, oni-Maruwa ati awakọ ero ni wi pe awọn to n gba owo lọwọ wọn fun ijọba (park managers) gbudọ kọkọ din iye ti wọn n gba lọwọ wọn ku na ki ẹdinku to le ba iye ero ti wọn n gbe.
- Wò ó ọ̀nà láti mú ara rẹ dé ibi tó ga jùlọ nínú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìlànà Tantra
- Wo àwọn ààrẹ ilẹ̀ Afirika tó kéde òfin kónílé ó gbélé nítorí coronavirus
- Awakọ̀-èrò, ọlọ́kadà farakásá àṣẹ ìjọba Ekiti láti dẹ́kun Coronavirus
- Eni mẹ́rin míì kó coronavirus ní Nàìjíríà, àfàìmọ̀ kó má dàbi ti China, Italy- Mínísítà kìlọ̀
Wọn tẹsiwaju wi pe lai ṣe eyii, ko ni rọrun fun awakọ ati ọlọkada ti o ba tẹle aṣẹ ijọba lati ri owo mu dele lẹyin ti o ba ṣiwọ iṣẹ tan.

Lorii sisun mẹyin funra ẹni lawujọ:
Aṣẹ naa ko tii di itẹwọgba nitori ọgọọrọ awọn eeyan lo to si ẹnu awọn ẹrọ to n pọ ọwọ lọwurọ oni lai sun fun ara awọn.
Awọn to n to lọwọọwọ lati wọ inu ile ifowopamọ naa ko ni onka.
Bo tilẹ jẹ wi pe gbogbo awọn onibara ni awọn oṣiṣẹ ile ifowopamọ n ṣe ayẹwo fun ki wọn to wọle, bi awọn ẹniyan wọnyii ṣe sunmọ ara wọn pẹkipẹki gan an lo n kọnilominu.
Karakata ṣi n lọ ni awọn ọja bii Dugbẹ, Bodija, Orita-Challenge ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ati ontaja ati onraja lo n fi ara nu ara wọn lọwọ ti ẹnikẹni ko si bikita.Alaye wọn ni wipe bi ọja ba di titipa niori aarun Corona, afaimọ ki ẹbi ma lu awọn eeyan pa sinu ile.
Ìjọba àpapọ̀ ní kí àwọn òṣìṣẹ́ grade 1 sí 12 jókòó sílé nítorí Coronavirus
Buhari: Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ní kí àwọn òṣìṣẹ́ grade 1 sí 12 jókòó sílé
Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ijọba tí wọn wa ni ipele ikinni si ikejila lati ma wa si ibi iṣẹ mọ.
Adari awọn oṣiṣẹ ijọba, Dokita Folasade Yemi-Esan lo fi atẹjade yii ṣọwọ si awọn oṣiṣẹ ijọba lọna ati dena itankalẹ arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Google
Yemi-Esan ninu ọrọ rẹ sọ wi pe eto ilẹra awọn oṣiṣẹ ijọba jẹ awọn logun nitori ọmọ Niajiria rere ni awọn naa.
O rọ awọn oṣiṣẹ ijọba lati tẹlẹ aṣẹ awọn eto ilera lori imọtoto ki arun naa ba le tete ka kuro nilẹ.
Yemi-Esan ni awọn oṣiṣẹ ipele ikejila silẹ gbọdọ ṣiṣẹ lati ile bẹrẹ ni Ọjọ Iṣẹgun, Ọjọ Kẹrinlelogun, Osu Kẹta, ni ọdun 2020 titi akoko ti ajakalẹ arun naa yoo fi ka kuro nilẹ.
Ijọba wa paṣẹ fun awọn ọga agba iṣẹ ti yoo ma a lọ ileeṣẹ ki wọn ri wi pe awọn ko gba alejo pupọ julọ.
Bakan naa ni wọn paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ti wọn ti lọ si orilẹ-ede ti arun Coronavirus ti peleke, abi ti wọn ba ti ni ifọwọwẹwọ pẹlu awọn ti o ba ti de lati oke okun lati se ara wọn mọ ile.
Awọn ti wọn ba si ti n ri awọn ami to dabi ẹni pe wọn ni arun Coronavirus yii, wọn gbọdọ pe ileeṣẹ to n risi ajakalẹ arun (NCDC) lori nọmba 0800970000-10.
















