Coronavirus in Nigeria: Àwọn awakọ̀èrò, ọlọ́kadà arìnrìnàjò faragbá nínú ìpa Coronavirus

Gomina ipinlẹEkiti, Kayọde Fayẹmi

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government

Gẹgẹ bii ara igbesẹ lati dena arun Coronavirus ni ipinlẹ Ekiti, ijsba ipinlẹ naa ti ti gbogbo ileewe to wa nibẹ pa.

Ninu iwe aṣẹ mawobẹ (Executive order) kan to fi sita ni ọjọ Ẹti, gomina Kayọde Fayẹmi ni gbogbo ipesjọpọ to ba ti n ni ọpọ ero to ju ogun eeyan lọ, yala ni ile ijọsin, ile igbafẹ, awujọ oṣelu, ile ijo ati ile ọti ko gbọdọ waye mọ titi di igba ti nnkan ba fi rọgbọ lori arun naa.

Ninu ọrọ to ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọ lori ẹrọ maohunmaworan lori iṣẹlẹ arun naa eyi to ti mu eeyan kan bayii ni ipinlẹ ọhun, gomina Kayọde Fayẹmi fi ọkan awọn eeyan ipinlẹ Ekiti balẹ pe wọn ti kapa arun naa nipinlẹ ọhun ṣugbọn sibẹ oju lalakan fii ṣọri.

Awọn agunbanirọ n ṣe idanilẹkọ fun awọn ọlọja ni ilu Ado Ekiti

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government

Bakan naa lo paṣẹ pe awọn onimọto nibẹ ko gbọdọ gbe ju eeyan kan ni iwaju ati ero mẹta-mẹta ni ila aga kọọkan ninu ọkọ wọn.

Awọn aṣẹ miran ti ijọba ipinlẹ Ekiti pa lori kikapa arun yii niwọnyii:

Àrùn Coronavirus ti tàn dé orílẹ̀èdè Eritrea

Orilẹede Eritrea ti fi lede wi pe awọn ti ni ẹni akọkọ to ni Coronavirus lorilẹede naa.

Ẹni ọdun mọ̀kandinlogoji ni ara ilẹ Eritrean to n gbe ni Norway.

Ọjọ Satide ni arakunrin naa de papkọ ilẹ wọ ni Asmara International Airport, ti wọn si ya a sọtọ fun ayẹwo to fihan pe arakunrin naa ti ni arun Coronavirus.

Bakan naa ni orilẹede Uganda ti paṣẹ ki ọkọ ofurufu kankan maṣe wọle si orilẹede naa lati dẹkun itankalẹ arun naa.

South Korea

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi ni gbogbo igbesẹ ni ijọba ipinlẹ naa n gbe lati rii pe ọṣẹ arun Coronavirus nipinlẹ naa mọ leeyan kan to wa lọwọlọwọ.

Amọ orilẹede Democratic Republic of Congo, Gabon, SUDAN ati Burkina Faso ti darapọ awọn orilẹede ni ilẹ Afirika ti awọn to lugbadi arun Coronavirus ti gbẹ ẹmi mi.

Iwe iroyin ilẹ naa fi lede wi pe dokita to n ṣiṣẹ ni ileeṣẹ ijba ni ẹni to ku naa lẹyin to pada si orilẹede DRC lati ilẹ Faranse.

Ọjọ Eti lo gbe ẹmi mi lẹyin aisan ọna ọfun rẹ ko ṣiṣẹ daradara mọ.