Coronavirus in Nigeria: K1 de Ultimate ní káwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò bá ńidìí láti jáde ó gbé inú ilé wọn

Oríṣun àwòrán, k1 de ultimate
Agba oye Wasiu Ayinde Ọmọgbọlahan ti ọpọlọpọ eeyan mọ si K1 ti ke sawọn ọmọ orilẹede Naijiria pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii lori arun coronavirus, gbogbo ẹni ti ko ba ni nnkan to nṣe ki wọn gbe ile wọn ni.
Ninu orin rẹ kan to n kaakiri lori ayelujara bayii, K1 ṣalaye pe ọrọ coronavirus yii ki ṣe ṣereṣere rara, gbogbo ọmọ Naijiria lo si gbọdọ gbaruku ti awọn alaṣẹ lati gbe awọn igbesẹ gbogbo to yẹ ni didẹkun arun naa.
Ki ni Toyin Abraham sọ ni tirẹ?

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham
Ẹwẹ, Gbajugbaja Oṣere Tiata, Toyin Abraham naa ti da si ọrọ arun coronavirus to gbode kan bayii.
Toyin jẹ ọkan lara awọn wọ kilu o mọ akọkọ ti yo mẹnu le ọrọ lori arun yii.
Ninu ọrọ kan to fi sori oju opo twitter rẹ, Toyin Abraham rọ awọn ololufẹ rẹ lati mojuto ilera wọn fun oun nitori oun nifẹ wọn gidigidi.
Toyin Abrahams to gba ami ẹyẹ oṣere to gbamuṣe julọ lobinrin lagbo ere tiata nibi ami ẹyẹ AMVCA laipẹ yii tun fi fidio ilanilọyẹ kan lori bi a ṣe lee tọju imọtoto ara ẹni lasiko yii.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1

End of Instagram post, 2
Toyin Abraham kọ ni gbajugbaja oṣere akọkọ ti yoo ke sawọn ololufẹ wọn ati gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria pe ki wọn tọju imọtoto wọn lasiko ajakalẹ arun yii.
Awọn adẹrinpoṣonu bii Ushbebe to jẹ adẹrinpoṣonu, ati Ayọdele Makun to jẹ adẹrinpoṣonu naa.
Bi a ko ba gbagbe arun coronavirus yii naa ti ṣọṣẹ laarin awọn ilumọọka ati wọọ-ki-ilu-mọ kaakiri agbaye.
Idris Elbar

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ni ọjọ aje ni gbajugbaja oṣere sinima ni ilẹ Gẹẹsi, Idris Elba kede pe oun ti wa ni igbele bayii nitori oun pẹlu ti ko arun COVID-19 ti ọpọ n pe ni Coronavirus.
Amọṣa o kọọ pe "ara oun ji pepe, gbogbo ami to si maa n farahan lara ẹni to ba ni arun naa ko jẹyọ lara oun o oun si ti fi ara oun si igbele lati igba ti oun ti fidi rẹ mulẹ pe oun ni arun yii'
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Tom Hanks ati iyawo rẹ, Rita Wilson

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa, Tom Hanks ati Rita Wilson lorilẹede Naijiria naa ti koo.
Hanks kede faraye pe oun ati iyawo oun, Rita ti ko arun naa lorilẹede Australia.
Kristofer Hivju

Oríṣun àwòrán, Kristofer Hivju
Kristofer Hivju to jẹ ọkan pataki lara awọn oṣere to kopa ninu sinimọ 'Game of thrones" naa kede pe oun pẹlu ti ko arun ọhun.
O nioun atawọn mọlẹbi oun ti fi ara wọn si igbele titi di igba ti aisan naa yoo fi wọn silẹ. Amọṣa o ni 'ṣaka lara emi ati idile mi le'
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3