Coronavirus in Nigeria: Wọ́n ti fi ọmọ orílẹ̀-èdè Italy tó kó coronavirus sílẹ̀ nílèéwòsàn

Oríṣun àwòrán, Twitter/babajide sanwo-olu
Wọn ti fi ọmọ orilẹ-ede Italy to ko arun coronavirus wọle si Naijiria silẹ nileewosan.
Ninu ikede kan to fi sita l'oju opo ayelujara Twitter, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu sọ pe lẹyin ti wọn pada ṣe ayẹwo fun ọkunrin naa ni wọn ri i pe ko ni arun naa lara mọ, lẹyin naa ni wọn si yọnda rẹ nileewosan.
- Èyí ni àwọn nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọmọ Italy tó kó Coronavirus wọ Eko
- "Inú ìbẹ̀rù bojo làwa ọmọ Nàíjíríà wà ní Italy, a kò leè jáde tàbí ra ọjà"
- Coronavirus: Italy sọ àgádágodo sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama
- Aṣíwájú ni Nàíjíríà nínú ìdènà Coronavirus, ohun márùn-ún rèé tí àgbáyé ń kọ́ lára wa
- Ààrẹ Buhari sún eré ìdárayá àpapọ̀ Edo 2020 síwájú
Bakan naa lo sọ pe ọkunrin naa gba lati finu-findọ fi odiwọn eroja inu ẹjẹ 'white blood cells' silẹ ko to o kuro nileewosan.
Eroja yii jẹ eyi to kun fun oriṣiriṣi nkan aṣaraloore to le kọju ija si arun coronavirus.
Sanwo-Olu sọ pe awọn yoo fi eroja 'white blood cells' ọhun pamọ sinu amu nkan tutu, ti wọn yoo si lo lati fi tọju awọn miran to ba tun ni arun COVID-19 ọhun.
Igba akọkọ niyii ti ẹnikẹni lara awọn to ni arun naa ni Naijiria gbadun, to si bọ lọwọ rẹ.
Lọwọlọwọ, eniyan mejila ni ijọba fidirẹmulẹ pe o ni coronavirus ni Naijiria.









