Coronavirus: Ẹ̀kọ́ márùn ún tí orílẹ̀-èdè àgbáyé lè kọ́ lára Naijiria lórí ìdènà àjàkálẹ̀ àrùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arun Coronavirus ti tan de orilẹ-ede mẹrinlelaadọfa lagbaye lati igba to ti bẹ silẹ nilu Wuhan, lorilẹ-ede China lọdun 2019.
Lara awọn orilẹ-ede ti arun naa ti ra pala wọ ni Naijiria, eyi to ko ibẹru sọkan ọpọ eeyan, ti ọpọ ọmọ orilẹ-ede yii si lero pe ijọba kọ ni le kapa rẹ itankalẹ arun naa.
Ṣugbọn o jẹ ohun iyalẹnu pe ijọba ṣe akitiyan ti ko kere lati kapa arun naa to bẹ gẹẹ, ti ajọ eleto ilera agbaye, WHO fi gboṣuba kare fun Naijiria fun akitiyan rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá, DSS, ẹ fún Sanusi lómìnira àti rìn fanda padà - Iléẹjọ́ pàṣẹ
- Ọkùnrin tó bẹ́ sì òdò ọ̀sà pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, lòun náà fi fẹ́ kú - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Kò sẹ́ni tó fẹ́ pa Buhari o, ọkùnrin tó pakuru mọ́ ààrẹ kàn fẹ́ bọ̀ọ́ lọ́wọ́ ni - Femi Adesina
- Yorùbá rẹwà, kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ìró ẹnu wọn jọra àmọ́ tí ìtumọ̀ wọn yàtọ̀
Iwọnyi si ni awọn ẹkọ marun un ti awọn orilẹ-ede mii lagbaye n kọ lara Naijiria nidi aṣeyọri rẹ lati kapa arun ọhun.
Akitiyan awọn ileeṣẹ iroyin:
Lati igba ti iroyin ti kede pe ọmọ orilẹ-ede Italy kan ko arun naa wọ Naijiria, ni awọn ileeṣẹ iroyin to ṣe e fọkan tan, bii ileeṣẹ BBC atawọn ileeṣẹ iroyin miran ti n ṣe ifitonileti iroyin nipa arun ọhun.
Ojumọ kan ko nii mọ ki ileeṣẹ BBC ma gbe iroyin bo ba ṣe n lọ nipa Coronavirus sita, bẹẹ naa ni wọn n ṣe idanilẹkọ fun awọn eeyan nipa bi wọn ṣe le dabo bo ara wọn, bi wọn ṣe le ṣe imọtoto ara ati bẹ bẹ lọ.
- Àríwá Nàíjíríà, ẹ sọ ẹran jọ̀bọ̀-jọbọ nù pẹ̀lú Sanusi tẹ yọ lóyè - Soyinka gbarata
- Coronavirus tún ti bẹ́ gìjà sí Ghana àti Gabon
- Wọ́n ti wọ́gilé ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Arsenal àti Brighton lẹ́yìn tí Mikel Arteta lùgbàdì àrùn Coronavirus
- Coronavirus ti di àjàkálẹ̀ àrùn káàkiri àgbáyé- WHO
- Àríwá Nàíjíríà, ẹ sọ ẹran jọ̀bọ̀-jọbọ nù pẹ̀lú Sanusi tẹ yọ lóyè - Soyinka gbarata
- A kò mọ ẹni tó pa ọlọ́pàá Ondo àti ìyàwó rẹ̀, òun kọ́ ló pa ara rẹ̀- ọlọ́pàá
Ohun kan gbogi ti awọn ileeṣẹ iroyin naa n tẹnu mọ, ni bi eeyan ṣe le pa ara rẹ mọ nipa lilo ọṣẹ lati fọwọ ẹni ni igba de igba, atawọn nnkan miran to yẹ fun eeyan lati ṣe, ki arun naa le jinna si wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ ṣe ipade lori itakun agbaye:
Ni kete ti arun naa tan de Naijiria ni ọkan gboogi lara awọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ, MTN, ṣe adinku si bi awọn eeyan ti kii ṣe oṣiṣẹ, wọn ṣe n wọle sinu ile iṣẹ wọn, eyi ni Yellow Drome to wa nilu Eko.
Bakan naa, iroyin kan sọ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa fiwe ransẹ si awọn ileeṣẹ mii ti wọn n ba ṣiṣẹ pe, idaduro ti de ba ipade ojukoju ti wọn maa n se loore-koore, ti wọn si sun awọn ipade wọn si ori itakun agbaye.
Arakunrin kan, Michael Adeniran sọ pe wọn ko gba oun laye lati wọle sinu ọgba ileeṣẹ naa, to si fi kun pe, wọn ni igbeṣẹ naa ko ṣẹyin ikede nipa arun Covid-19 lati ọdọ ileeṣẹ eto ilera Naijiria.
Awari kanmọ n kia nipa awọn to ba ẹni to ko arun ọhun wọ Naijiria:
Ko pẹ ti arun naa de Naijiria ti ijọba ipinlẹ Eko bẹrẹ igbeṣẹ lati ṣawari gbogbo awọn eeyan to wọ ọkọ baalu kan naa pẹlu ọmọ ilẹ Italy, to ko arun naa wọn Naijiria.
Ko pẹ si asiko naa ti kọmiṣọna feto ilera ipinlẹ Eko, Akin Abayomi kede pe, wọn ti ṣawari awọn meji ti wọn n wa, ti wọn wa ninu ọkọ baalu ilẹ Turkey to gbe ọgbẹni naa wa si papakọ ofurufu ilu Eko.
Koda, wakati mẹrinlelogun si igba ti wọn kede pe wọn n wa awọn eeyan naa ni ijọba Eko ṣawari wọn, ti wọn si fi wọn pamọ fun ayẹwo ati itọju.
Kiko ọgọrun eeyan pamọ fun iyasọtọ ati itọju:
Ko din ni ọgọrun eeyan to ba ọmọ ilẹ Italy to ko arun Coronavirus wọ Naijiria, ti ijọba ko si ipamọ fun ayẹwọ ati itọju.
Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Eko ti kọ sọ pe o ṣoro lati wa awọn eeyan ọhun ri, nitori pe ọpọ ninu wọn ni ko fi ojulowo adirẹsi ile wọn silẹ.
Ṣugbọn lẹyin iṣẹ takuntakun ti ijọba ilu Eko gunle, pẹlu iranlọwọ lati ọdọ ijọba apapọ, wọn ṣawari awọn eeyan naa.
Gẹgẹ bi ọrọ ti kọmiṣọna feto ilera Eko sọ, awọn eeyan mọkandinlọgọjọ lo wa ninu ọkọ baalu naa, awọn mẹfa si ṣalabapade rẹ nile itura to wọ si, ti awọn marundinlogoji mii tun ṣalabapae rẹ nile iṣẹ to ṣabẹwo si ni ipinlẹ Ogun.
Sise ayẹwo irufẹ́ kokoro Coronavirus to wọ Naijiria:
Orilẹ-ede Naijiria ni orilẹ-ede akọkọ lagbaye ti wọn ti kọkọ ṣe ayẹwo irufẹ kokoro Coronavirus to wa lara ẹni to ko wọ Naijiria, ti wọn si ri pe iru rẹ naa lo kọkọ ṣẹyọ nilu Wuhan, ti arun ọhun ti bẹ silẹ.
Aṣeyọri nla ni eyi jẹ nitori ọpọ lo gbagbọ pe, orilẹ-ede Naijiria ko koju oṣuwọn to nipa iwaadi ijinlẹ nipa eto ilera.














