Sunday Igboho: Bó ṣe bèèrè àtìpó ní Germany, náà ló ń bèèrè nílẹ̀ Benin

Ile ẹjọ orilede Benin Republic ti dá ajijagbara ọmọ Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sundayh Igboho padà si ahamọ ọlọpaa, titi di ọjọ Aje ọsẹ to n bọ ti ile ẹjọ yoo tun joko.
Bi o tilẹ jẹ pe Sunday Igboho ti saaju kọwe ẹbẹ lati se atipo ni orilede Germany tẹlẹ, amọ o tun ti n gbiyanju lati se bẹẹ pẹlu ni orílede Benin bayii.
Iroyin to tẹ wa lọwọ fi kun pe, ìgbésẹ yii yoo waye ni àwọn ọsẹ bii melo si asiko yii ati pe o jọ bi eni pe ijọba orilẹede Benin yoo jawọ lori ẹsun pe Sunday Igboho lo iwe irina ayederu ti wọn fi kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho ń bẹ iléẹjọ́ láti ṣe àtìpò òṣèlú nílẹ̀ Benin
- Ẹgbẹ́ òṣèlú mọ́kànlá forí ṣánpọ̀n nílé ẹjọ́ láti wọ́gilé ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ l‘Eko
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
- N kò ṣe ẹlẹ́yà Sunday Igboho, irọ́ ni wọ́n pa mọ́ mi - Olayomi Koiki
- ‘Passport’ Nàíjíríà àti Germany ni wọ́n ká mọ́ Sunday Igboho lọ́wọ́ - Agbẹjọ́rò
- "Ẹni tó bá gba 'Passport Benin Republic' láì ṣe ọmọ onílùú, yóò fi ẹ̀wọ̀n jura"
- Mo kìlọ̀ fún Igboho kó má wá sí ilé mi ní Benin Republic, lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ mi - Alábàṣiṣẹ́pọ̀
- Benin Republic ló bẹ́gi dínà aáyan ìjọba àpapọ̀ láti kù gììrì gbé Igboho wá Naijiria - Amòfin
Asoju àwọn agbẹjọro Oloye Sunday Igboho, Yomi Aliyu naa tun fi kun ninu atẹjade kan pe ko ṣeeṣe ki wọn da Sunday Igboho pada wa si Naijiria.
O ni eyi ko ṣẹyin adehun to ti wa laarin Naijiria ati Benin lọdun 1984 lori dida ẹni ti ijọba n wa pada si Naijiria paapa julọ ẹsun to ba ti ni ọwọ oṣelu ninu bi ti Igboho.
Ẹwẹ, lasiko ti wọn mu Igboho, oun ati iyawo rẹ ni wọn mu ni ahamọ, sugbọn ni bayii ile ẹjọ Cour De'appal De Cotonou ti paa lásẹ lọjọbọ pe ki wọn fi Ropo iyawo Igboho silẹ lalafia to ri kop si ẹsun ti wọn fi kan, sugbọn ki Igboho si wa ni ahamọ.
O to wakati mẹfa ti igbẹjọ naa fi waye pẹlu isinmi ranpẹ laarin, sugbọn adajọ ti pasẹ pe ki Igboho wa ni ahamọ titi di asiko igbẹjọ miiran lọsẹ to n bọ.
Gẹgẹ bi iroyin se sọ, ijọba Naijiria ti rọ ìjọba orilede Benin lati fi Igboho si ahamọ titi ti wọn yoo fi pari iwe ẹsun ti wọn fi kan ati bi wọn yoo se fi sọwọ pada si Naijiria.
Wọn ni ésun ti ijọba tun fi kan ni pe, o n sowo ibọn ni Naijiria, ati pe ti ijọba Benin ba tilẹ fi silẹ, o ṣeeṣe ki wọn tun pada mu nitori ẹsun pe o n ṣowo ibọn ti wọn fi kan.
Ninu atẹjade kan adari Ilana Omo Oodua ti ọjọgbọn Akintoye fi sita lo ti ṣalaye pe awawi lasan ti ko fi idi mulẹ ni ẹsun ti ijọba Naijiria fi kan Igboho nitori wọn ko ni ẹri kankan lati gbee lẹsẹ, eyi ko si to nnkan ti Benin yoo fi da Igboho pada si Naijiria.
Ẹwẹ Pelumi Ogunlesi to tun jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho ṣalaye pe, ireti wa pe ile ẹjọ Benin yoo da Igboho silẹ, wọn ko si ni daa pada fun ijọba Naijiria lọna aitọ.
Ẹwẹ, agbẹjọro rẹ miiran, Salami ti sọ saaju fun BBC pe, "Passport" Naijiria ati Germany ni wọn ka mọ Igboho lọwọ nigba ti wọn mu nitori naa, ireti wa pe igbẹjọ naa yoo lojutuu laipẹ.


















