Sunday Igboho: Ìgbẹ́jọ́ yóò wáyé láti mọ̀ bóyá wọ́n ó fa Igboho lé ìjọba Naijiria lọ́wọ́

Igbẹjọ yoo waye lonii lorilẹ-ede Benin, lati mọ boya ijọba orilẹ-ede naa yoo fa Sunday Adeyemo Igboho le ijọba Naijiria lọwọ.
Ọjọ Aje ni awọn oṣiṣẹ alaabo mu oun ati iyawo rẹ, Ropo, lasiko ti wọn fẹ wọ baalu lọ si orilẹ-ede Germany.
Iroyin sọ pe aago mẹwa owurọ oni, ni igbẹjọ naa yoo bẹrẹ.
Ọjọru lo yẹ ki igbẹjọ naa kọkọ waye, ṣugbọn wọn ko gbe Sunday Igboho wa sile ẹjọ ni ilu Cotonou ni orilẹede Benin Republic.
Akọroyin BBC Yoruba to wa ni Cotonou ni ko si igbẹjọ kankan nitori wọn ko gbe Sunday Igboho wa si ileẹjọ.
Gẹgẹ bi akọroyin wa se wi, awọn eeyan duro lati foju ganni Igboho amọ nigba ti wn ko ri, ni awọn eniyan bẹrẹ si ni kuro ni ileẹjọ.
Ile ẹjọ to yẹ ki igbẹjọ naa ti waye ni wọn n pe ni Paequet, ti iroyin naa si ni ahamọ kan ti wọn n pe ni Brigade De Criminel to wa lagbegbe Berlier, ni wọn fi Sunday Igboho pamọ si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho kìí ṣe ‘Terrorist’, ẹ fi sílẹ̀ ní àhámọ́ - Àwọn Olùwọ́de faraya
- "A kò sinmi lórí ọ̀rọ̀ Yoruba Nation, Sept 14 lá yọjú sí United Nation"
- Ooni Ife àtàwọn èèkàn Yorùbá ṣèpàdé ìdákọ́nkọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Amotekun àtàwọn jàndùkú kọlu ara wọn ní Ibadan, èèyàn méjì kú lọ́jọ́ Ileya
- Wọn yóò tẹ ẹ̀tọ́ Sunday Igboho mọ́lẹ̀ tó bá padà sí Nàìjíríà - Afenifere Renewal Group
- Ìwọ́de ńlá yóò wáyé lónìí ní London lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Àwọn ajìjàgbara Yoruba Nation yóò ṣe iwọ́de tako bí wọ́n ṣe mú Sunday Igboho
- "Ẹ̀yìn ọba Yorùbá, ẹ dìde láti gbe Sunday Igboho níjà kó le jàré nílẹ̀ Benin"
- "Ìdí tí ìjọba Benin Republic kò ṣe ní le è fa Igboho lé Nàíjíríà lọ́wọ́ ree"
- Ìyàtọ̀ wà láàrin èsì àyẹ̀wò ikú Jumoke àti ohun tí ọlọ́pàá sọ
Iwadii akọroyin naa fihan pe, Sunday Igboho ṣi wa ni agọ ọlọpaa ti wọn n pe ni BRIGADE DE CRIMINEL, nibi ti wọn fi pamọ si.
Lọwọlọwọ awọn eniyan pejọ si agọ ọlọpaa naa lati mọ ipo ti Sunday Igboho wa, amọ ọlọpaa kankan ko i tii bawọn sọrọ.

Amọ wọn ko tii le sọ boya wọn yoo si gbe lọ si ileẹjọ ki ilẹ oni to ṣu.
Bi iroyin naa ba ṣe n lọ ni a o ma a fi to yin leti.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Ọgunjọ, Oṣu Keje, ọdun 2021 ni ẹṣọ agbofinro lati orilẹede Naijiria mu Sunday Igboho ni papakọ ofurufu ni Benin Republic, lẹyin ti ajọ DSS lorilẹede Naijiria kede pe wọn n wa Sunday Igboho fun ẹsun pe o ko ohun ija oloro pamọ si ile rẹ.
Awọn eekan ni ilẹ Yoruba to fi mọ awọn lọbalọba ni wọn ti n ṣepade lori ọrọ naa, ti awọn alakoso Yoruba Nation si n sọ pe awọn yoo sa gbogbo ipa wọn lati ri pe wọn ko gbe Sunday Igboho pade si Naijiria nitori wọn yoo tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ.
















