Sunday Igboho: Amòfin ní Benin Republic kò ní fa Igboho lé Nàíjíríà lọ́wọ́ torí àdéhùn ọdún 1984

Oríṣun àwòrán, succo
Agbẹjọro oloye Sunday Igboho, Yomi Aliyu ti sọrọ lori idi ti yoo fi ṣoro fun ijọba apapọ lati gbe Igboho lati orilẹ-ede Benin Republic wa si Naijiria.
Agbẹjọro agba naa sọ pe ijọba Naijiria ko ni le gbe Igboho wọle lati Benin nitori ọrọ ajọsọ laarin orilẹ-ede mejeji eyii ti wọn ti tọwọ bọwe adehun rẹ lọdun 1984.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, adehun ọhun waye lọdun naa lọhun laarin Naijiria, Togo, Ghana ati Benin Republic.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sé lóòtọ́ ni wọ́n ti fi Sunday Igboho sílẹ̀ ní Cotonou?
- Mo kìlọ tó fún àwọn ọmọ Nàìjíríà pé kí wọn má dìbò fún Buhari ní 2015 sùgbọn wọn kò gbọ- Pásítọ̀ Oyedepo
- Sunday Igboho àti aya rẹ́, Ropo ni ọlọ́pàá Interpol mu ní Cotonou - Agbẹjọ́rò
- Kìí ṣe tuntun pẹ ìjọba Buhari tí mú Sunday Igboho, àmọ́ ọ̀nà àbáyọ sí ìtúsílẹ̀ rẹ̀ rèé - Agbẹnusọ Sunday Igboho
- Wo àwọn ìgbésẹ̀ tí Sunday Igboho gbé, tó fi di ọ̀tá ìjọba
- Wo ìgbà márùn-ún tí wọn saáyan láti mú Sunday Igboho
O ni "Iwe adehun ti Togo, Naijiria, Ghana ati Republic of Benin tọwọ bọ lọdun 1984 sọ pe ijọba orilẹ kan ko ni fi afurasi lori ẹsun to rọ mọ ọrọ oṣelu ṣọwọ si ijọba orilẹ-ede miran laarin awọn mẹrẹrin."
"Adehun naa tun ṣalaye pe orilẹ-ede ti afurasi naa ba wa ko ni jọwọ rẹ fun orilẹ-ede keji to ba ṣe pe ko ni ri idajọ ododo gba tabi to ba ṣeeṣe ki wọn fa ẹjọ naa nilẹ."
Aliyu sọ siwaju si pe iwe adehun ti awọn orilẹ-ede kan nilẹ Afrika buwọlu, eyiti Naijiria ati Bening Republic wa lara wọn sọ pe araalu lẹtọ labẹ lati ja fun ominira, gẹgẹ bii ori ogun iwe naa ṣe sọ.
O ni fun idi eyii, orilẹ-ede Benin ko ni fi Sunday Igboho ṣọwọ si ijọba Naijiria nitori labẹ adehun naa, afurasi lori ẹsun to rọ mọ ọrọ oṣelu ni Igboho.
Ninu atẹjade kan to fi lede, agbẹjọro naa ni Igboho ko le ri idajọ ododo gba ti wọn ba gbe wa si Naijiria, ati pe o ṣeeṣe ki pa gan nitori awọn eeyan ti ijọba Naijiria mu nile rẹ lọjọ kinni oṣu yii ṣi wa ni ahamọ lai ni anfani lati ri agbẹjọro wọn.
O ni aya Igbogo, to jẹ ọmọ orilẹ-ede Germany ni wọn mu lasiko ti wọn fi panpẹ ofin mu u ni Cotonou.
Lẹyin naa lo ke si ijọba Benin republic ati ajọ agbaye lati da si ọrọ naa, paapaa lori iwa ifiyajẹni lọna aitọ ti ijọba Naijiria n wu.

















