Sunday Igboho Arrest: Ìbéèrè tí ọpọ ń bèèrè ni pe sé wọn ti fi Sunday Igboho sílẹẹ ni?

Oríṣun àwòrán, Others
Ni kete ti ileesẹ iroyin BBC gbọ iroyin to n tan kaakiri ayelujara pe wọn ti fi Oloye Sunday Igboho silẹ ni ilu Cotonuo ni orillẹ-ede Benin Republic ni BBC ti kan si agbejọro Sunday Igboho.
Amofin Yomi Aliu to n soju Oloye Sunday Igboho so fun BBC Yoruba pe irọ to jina si ootọ ni iroyin itusilẹ naa.
Amofin Yomi Aliu ni pe ijọba ilẹ Benin Republic ko tii fi ajijagbara Sunday Igboho naa silẹ.
- Sunday Igboho àti aya rẹ́, Ropo ni ọlọ́pàá Interpol mu ní Cotonou - Agbẹjọ́rò
- Kìí ṣe tuntun pẹ ìjọba Buhari tí mú Sunday Igboho, àmọ́ ọ̀nà àbáyọ sí ìtúsílẹ̀ rẹ̀ rèé - Agbẹnusọ Sunday Igboho
- Buhari, tú Sunday Igboho sílẹ̀ bo ṣe tú Boko Haram tó ronúpíwàda sílẹ̀ - Ladoja
- Wo àwọn ìgbésẹ̀ tí Sunday Igboho gbé, tó fi di ọ̀tá ìjọba
- Wo ìgbà márùn-ún tí wọn saáyan láti mú Sunday Igboho
- Àwọn agbẹjọ́rò tó dáńtọ́ ti wà ní Cotonou láti gba ìdáǹdé Sunday Igboho - Akitoye
O ni gbogbo igbese to yẹ naa ni awon ti n gbe lati rii pe wọn fi ajijangbara naa sile laipẹ laijinna.
Saaju ni iroyin naa ni Omooba Adeolu Atayero Olamijulo ti dupe lọwọ awọn eeyan to gbadura fun Igboho ati awọn to satilẹyin fun un paapaa ni Cotonou.
Ko pe ti iroyin yii n tan naa ni enikan tun fi soju opo Facebook re pe iwa ipa ti awon ọtẹlẹmuyẹ DSS Naijiria hu sile Sunday Igboho ko dara to ati pe awọn agbofinro Benin Republic kọ lati fi Sunday Igboho sill fun wọn
Àwọn agbẹjọ́rò tó dáńtọ́ ti wà ní Cotonou láti gba ìdáǹdé Sunday Igboho - Akitoye
Aṣaaju ẹgbẹ ọmọ Yoruba, ọjọgbọn Banji Akintoye ti sọ pe lootọ ni wọn ti fi ṣikun ofin mu Sunday Igboho lorilẹ-ede Benin ṣugbọn iṣẹ ti bẹrẹ lati gba itusilẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, cowrynews
Akintoye lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Maxwell Adeleye buwọlu, eyii to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.
O ni bo tilẹ jẹ pe wọn ti mu Igboho, oun atawọn ojulowo ọmọ Yoruba kan ti n sa ipa lati ri pe wọn ko faye gba ijọba Naijiria lati gbe Sunday Igboho wa si Naijiria lati Benin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba Naijiria ti fi pampẹ̀ òfin mú Sunday Igboho?
- "Á dá ohun àlùmọ́ọ́nì wa jọ láti gbèjà Sunday Igboho nílé ẹjọ́"
- "Buhari, kí ló dé tó ń mu Sunday Igboho àti Kanu, amọ́ tó mu àwọn agbébọn?"
- Adájọ́ kò yọjú lọ́jọ́ ọdún Iléyá fún ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí tí DSS kó nílé Sunday Igboho
- Ẹ rántí Buhari àtàwọn gómìnà nínú àdúrà bí ẹ ti ń ṣọdún Iléyá - Tinubu
- Ààrẹ Ògbóni sọ òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Gani Adams torí bó ṣe tàbùkù Ọba Ogboni tó ṣe ìwọ́de Yorùbá Nation
- Ẹ̀yin ọmọ Nàíjíríà, mó rí ìlàkàkà yín, ẹ ṣe sùúrù nítórí ìyá yìí yóò dópìn - Ààrẹ Buhari
Akintoyin ke si gbogbo ọmọ Yoruba lati fọwọsowọpọ lati gba ilẹ abinibi wọn silẹ lọwọ awọn to n kogun ja wọn.
O ni "Alẹ ana ni mo gbọ iroyin pe wọn ti fi pampẹ ofin mu oloye Sunday Igboho ni papakọ ofurufu kan niluu Cotonou."
"Lẹsẹ kan naa ni emi atawọn agbagba kan bẹrẹ iṣẹ lati ri pe wọn ko ṣe ohunkohun to lodi si ofin si, ati lati dena ijọba apapọ lati gbe wa si Naijiria."
Ọjọgbọn Akintoye sọ pe inu oun dun pe orilẹ-ede to bọwọ fun ofin ni Benin Republic jẹ, awọn si ti ke si agbẹjọro to dantọ lati bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ naa.
O ni ohun to kan bayii ki gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba nile ati loke okun parapọ lati ri daju pe ko si ọmọ Oduduwa kankan ti ijọba Naijiria fi iya jẹ lọna ti ko ba ofin mu.
Aṣaaju ẹgbẹ ọmọ Yoruba naa ni "Awa ọmọ Yoruba jẹ ẹya kan to ni akinkanju to si lagbara, a ni lati ji giri bayii lati ṣe ọkan akin."
Gẹgẹ bii ohun ti Akintoye sọ, igbesẹ akọkọ ni lati ri pe Sunday Igboho kuro ni ahamọ nitori kii ṣe ọdaran.
Akintoye sọ pe awọn eeyan kan lo n gbiyanju lati mọọmọ fi iya jẹ Igboho niroti pe o dide lati gba awọn eeyan rẹ silẹ lọwọ awọn amunisin.
Ọjọgbọn Akintoye pari ọrọ rẹ pe awọn ko ni sinmi titi ti Sunday Igboho yoo fo bọ ni ahamọ.



















