Sunday Igboho Arrest: Ohun tí a mọ̀ rèé nípa bí ìjọba Naijiria ṣe mú Sunday Adeyemo ní Cotonou

Oríṣun àwòrán, Naija2day
Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe awọn agbofinro ti fi ṣikun ofin mu oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho niluu Cotonou, lorilẹ-ede Benin Republic.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, wọn ni ijọba mu Igboho ni papakọ ofurufu kan lorumọju ọjọ Aje.
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin nnkan bii ọsẹ mẹta ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS kede pe awọn n wa Igboho lori ẹsun pe o ko ohun ija ogun sile.
- Kí ló dé tí DSS kó bàńtẹ́ òògùn, ba ilé Sunday Igboho jẹ́ lái fara pa?
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
- "Gbàjarè! Àwọn èèyàn tí DSS kó nílé Sunday Igboho nílò ìtọ́jú kíámọ́sá"
- Sunday Igboho ń dáró èèyàn kejì tí DSS pa nílé rẹ̀
- Ìbọn àti nǹkan ìjagun ni Igboho kó pamọ sílé ló jẹ kí á yabo ilé rẹ̀ - DSS
- Sunday Igboho ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí DSS pa
- DSS kò mú mi lọ́dọ̀ Guru Maharaji, èmi rèé n‘Ibadan, ẹ sinmi àhesọ ọ̀rọ̀ - Sunday Igboho
Bo tilẹ jẹ pe Igboho ti fesi pe irọ patapata ni ẹsun ti DSS fi kan ohun, sibẹ, DSS sọ pe o ni lati farahan nileeṣẹ awọn.
Iroyin naa sọ pe ijọba Naijiria yoo gbe Igboho wa si Naijiria lonii, ọjọ Iṣẹgun lati Benin Republic lati wa jẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni DSS ti kọkọ kọlu ile Igboho loru ọganjọ ọjọ kinni, oṣu keje ọdun 2021, nibi ti wọn ti ṣẹkupa eeyan meji ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia jẹ.
Lẹyin naa ni ijọba apapọ ke si ileeṣẹ aṣọbode ati ileeṣẹ to n ri si iwọle-wọde ni Naijiria lati maa ṣọ gbogbo irin Igboho.
Gbogbo akitiyan BBC lati kan si agbẹjọro Igboho ati Olayomi Koiki, to jẹ agbẹnusọ rẹ lati fi idi ọrọ naa mulẹ ko tii yọri si rere.



















