Sunday Igboho: ''Ẹ ó ríjà oba, tí ẹ bá gbìyànjú láti fọ́wọ́ kan Sunday Igboho''

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajijagbara ilẹ Yoruba, Ọgbẹni Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho tun ti kilọ fawọn to ba n gbero lati mu un.

Nigba ti Igboho ṣe abẹwo si Oba ilu Oke-Iho lagbegbe Oke Ogun nipinlẹ Oyo, Oba Rafiu Osuolale Mustapha, Igboho sọ pe Alaafin Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi duro gbọin-gbọin lẹyin ohun.

Igboho sọ ninu fido kan to fi sori Facebook pe ''nigba tawọn ijọba Naijiria lọ ba Alaafin wi pe ko fa Sunday Igboho le wọn lọwọ, o ni ko ṣeeṣe bẹẹ.

Alaafin ni Sunday Igboho ti ẹ n wo yẹn, mẹwaa ni, eleyi ti ẹ n ri yẹn to n kaakiri kii ṣe Sunday Igboho tori pe oun mọ an dele dele.

Nitoripe awọn baba toun atawọn baba tiẹ jọ ṣe pọ ni.

Ti ẹ ba si gbiyanju lati fọwọ kan Sunday Igboho, igba naa lẹ o rija ọba, Alaafin lo sọ bẹẹ.

Alaafin lo kọkọ kọ lẹta si Buhari pe o to gẹẹ nipa ọrọ awọn Fulani nipinlẹ Oyo,'' Igboho lo sọ bẹẹ.

Sunday Igboho ko ṣai sọ fun Oba Mustapha pe oun ṣetan lati le awọn Fulani kuro lori ilẹ Oke-Iho ti Kabiyesi ba fẹ bẹẹ.

Igboho tun sọ fun Kabiyesi nipa erongba rẹ lori bi iran Yoruba yoo ti yapa kuro lara Naijiria.

Ajijagbara Igboho ni yiyapa iran Yoruba kuro lara Naijiria ti ṣeeṣe na.

Ninu ọrọ tirẹ, Oba Mustapha Adeitan Keji gbadura pe fun Igboho pe didaduro iran Yoruba yoo ṣeeṣe.