Gani Adams: Fulani kọ́ ni ìṣòro ètò ààbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ Yorùbá, àwọn èèyàn wa ni

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde
Lori ọrọ eto aabo to mẹhẹ nilẹ Yoruba, awọn Fulani kọ ni ìṣòro wá.
Eyi ni ọrọ ti Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams sọ nibi ipade apero ilẹ Yoruba to waye nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ni Ọjọbọ.
Ipade apero naa lo jẹ idasilẹ ẹgbẹ kan, South-West Security Stakeholders, lati ọwọ Gani Adams.
- Sunday Igboho kàn ń gbé ‘Camera’ lẹ́yìn kiri, kí wọ̀n lè rò pé ó ń jà fún Yorùbá - Gani Adams
- Gani Adams kilọ f'awọn darandaran
- Femi Adesina ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ni ṣùgbọ́n mo rán ọ sí Buhari - Gani Adams
- Olóṣèlú ti tọwọ́ bọ ọrọ Igboho àti ìṣòro Fulani, mo gbọdọ̀ ṣọ́ra - Gani Adams
- Gani Adams: Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ti kàn sí OPC lórí ètò ààbò
- Ojú afurasí oníjìbìtì àti ajínigbé tí Gani Adams pariwo wọn síta l‘Oke Ogun rèé
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
Ẹgbẹ naa ti yoo jẹ akojọpọ oriṣiriṣi ẹgbẹ nilẹ Yoruba, igbimọ lọba-lọba, ẹgbẹ OPC, Agbẹkọya, Sọludẹrọ, àwọn ọdẹ, fijilante àti awọn ẹgbẹ mii.
Ẹgbẹ naa ni yoo ma mojuto eto abo ilẹ Yoruba.
Ọpọ eeyan n bi mi pe ki n i mo n se lori aabo ilẹ Yoruba to mẹhẹ
Nigba to n ṣorọ, Iba Adams sọ pe ibanujẹ ni bi wọn ṣe ko awọn ọmọ ẹgbẹ OPC to mu Iskilu Wakili, olori Fulani ni ilẹ̀ Ibarapa, lọ sile ẹjọ.
Bakan naa ni awọn eeyan mii to sọrọ níbi ipade naa koro oju si awọn iṣẹlẹ ijinigbe, ifipabanilopọ, ipaniyan, ati biba ọkọ ati eto ọrọ aje àwọn eeyan jẹ nilẹ Yoruba.
Lara wọn ni Akọwe Agba fun igbimọ agbaagba ilẹ Yoruba, Ọmọwe Kunle Olajide to sọ pe ibi ọ̀wọ̀ ni awọn aginju to wa ni ilẹ Yoruba.
O fikun pe ẹ̀yà Yoruba ko ni i fun ẹnikẹni ni nkankan lara awọn aginju rẹ fun.
Adams wa kilọ pe ko yẹ ko jẹ pe awọn eeyan perete ni yoo ma a mojuto ọrọ abo.
O ni "ti a ko ba tete mojuto ọrọ abo to mẹhẹ nilẹ Yoruba, o ṣe e ṣe ki o buru si i.'
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- A ń lọ ṣí ẹnu bodè Yorùbá tíjọba tìpa sílẹ̀, kí oúnjẹ wọlé nírọ̀rùn - Sunday Igboho
- A kọ òrìṣà babańlá wa sílẹ̀ ló jẹ́ kí ọ̀daràn darandaran máa pa wá bí ẹ̀fọn - Àwọn Oníṣẹ̀ṣe
- Ìtàn ayé John Magufuli, Ààrẹ Tanzania tọ́pọ̀ èèyàn ń pè ní 'bulldozer'
- Wo ohun tí o kò mọ̀ nípa Ààrẹ Tanzania, John Magufuli tó jáde láyé
- Wo ewu tó rọ̀ ma kí wọn sin ọba tó ṣètùtù nílànà ẹ̀sìn Krìsítẹ́nì àti Islam
O fi ẹsun kan pe awọn adari ẹ̀yà Yoruba kan fi aarun Covid-19 ṣe awawi, lati má a kopa níbi ipade naa.
" Lati igba ti mo ti di Aarẹ Ọna Kakanfo, oriṣiriṣi ojúṣe lo wa ni ọrùn mi, sugbọn ọpọ eeyan si n beere pe, ki ni mo n ṣe lori ọrọ aabo nilẹ Yoruba."
Ẹyọ kan lara agbara ti mo ni ni mo lo lati mu Wakili
O tẹsiwaju pe ọpọlọpọ awọn ọmọ Yoruba to wa ni ipo agbára, lo ti gbagbe orisun wọn.
"Fun ẹyin ti ẹ n beere pe ki ni mo n ṣe lori ọrọ abo, ẹyọ kan lára agbára ti mo ni, ni mo lo laarin ọsẹ meji, ti ilẹ mì titi."
O ṣalaye pe laarin ọsẹ meji pere ni awọn ọmọlẹyin òun wọ inu aginjù, ti wọn si mu igbakeji Iskilu Wakili, ati awọn mẹta mii ti wọn fa le ọlọpaa lọwọ.
" Oṣù kan ni a fi n sọ ìwọlé ati ijade Wakili, ko to o di pe ọwọ tẹ ẹ, ati awọn mẹta míì ni Ibarapa.
"Bi wọn ṣe fi ẹsun ipaniyan, didana sun dukia, ati di darapọ mọ ẹgbẹ ti ko ba ofin mu, kan àwọn to mu Wakili nile ẹjọ yẹ ko mu ẹ̀yà Yoruba ronu.
Wọn gbe igbesẹ lati ṣọ eto aabo nilẹ Yoruba di alailagbara ni.
" Sugbọn ṣa, awọn eeyan wa gan-an ni ìṣòro wa, kii ṣe Fulani, nitori mo gbọ pe awọn ọmọ Yoruba kan jẹ ọdalẹ."
- Krìsìtẹ́nì àti Mùṣùlùmí ń sọ òkò lura wọn ní Ilorin torí aáwọ̀ lílo Hijab
- Wo ibùdó tó sún mọ́ ọ láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 l'Eko
- El Rufai àtàwọn gómìnà míì ló n tako sísan owó oṣù tó kéré jùlọ - NLC
- Ilé ẹ̀kọ́ 10 tíjọba Kwara tìpa di ṣíṣí padà, akẹ́kọ̀ọ́bìnrin le lo Hijab níbẹ̀
- Boko Haram gboró, ó dáná ṣun ìbùdó ológun, iléẹ̀kọ́ àti ilé ìwòsàn
Nibi ipade naa ni awọn to sọrọ ti rọ àwọn gomina nilẹ Yoruba, lati ṣe igbelarugẹ fun eto ọgbin àti nkan ọsin.
Wọn ni eyi yoo fi opin si bi ilẹ Yoruba ṣe n gbojule Ariwa Naijiria fun oúnjẹ.
Àwọn agbébọn láti Òkè Ọya ń wa góòlù ní Ilesa, Owo àti Igangan láì sí ìdíwọ́ - Gani Adams

Saaju la ti mu iroyin wa pe Aarẹ Ọna Kakanfo nilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams tun ti sọrọ soke nipa eto aabo to mẹhẹ nilẹ Yoruba atawọn ọna abayọ si.
Oloye Adams, lasiko to n fọwọ werọ pẹlu iwe iroyin Vanguard tun mẹnuba ọpọ ipenija eto aabo tilẹ Yoruba n koju ati ewu to wa nibẹ fun iran yii.
Aarẹ ni lọwọ lọwọ bayii, awọn janduku kan lati apa oke Ọya wa lawọn agbegbe kan nilẹ Yoruba, paapaa nilu Owo, ni abule Iwuse, tawọn baalu kekeke si maa n wa ja ibọn fun wọn.
- Sunday Igboho kàn ń gbé ‘Camera’ lẹ́yìn kiri, kí wọ̀n lè rò pé ó ń jà fún Yorùbá - Gani Adams
- Gani Adams kilọ f'awọn darandaran
- Olóṣèlú ti tọwọ́ bọ ọrọ Igboho àti ìṣòro Fulani, mo gbọdọ̀ ṣọ́ra - Gani Adams
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Gbàjarè! Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ agbébọn lo wà nílúù Kishi, National Park - Gani Adams figbe ta
- Bí Sunday Igboho bá tàpá sófin, kí lẹ ṣe fáwọn ọ̀daràn Fulani tó ń pa èèyàn - Gani Adams
- Ìlànà ‘Referendum’ nìkan la fi le gba orílẹ̀èdè Oduduwa, kìí ṣe ìwọ́de
"Sẹ mọ pe ijọba ipinlẹ Ondo ati awọn eeyan ilu Owo ko le wọ inu igbo naa lati lọ koju wọn. Bakan naa ni awọn janduku yii naa n wa goolu wa lọna aitọ nilu Ilesa laisi ẹni ti yoo yẹ wọn lọwọ wo.
Koda, awọn ọdaran yii lo n wa ohun alumọọni wa nilu Igangan lọna aitọ, eyi to jẹ ki Wakili atawọn ọmọ ogun rẹ ni owo tabua lọwọ lati fi ra ohun ija oloro, ti wọn fi tun n ji eeyan gbe."
Oloye Adams fikun pe bakan naa nilu Irawo Ile ati Idere, wọn n wakusa lọwọ nibẹ lọna ti ko bofin mu, awọn ohun alumọọni ti iran to n bọ si nilo ree lati se aye wọn.
- Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá làwọn ọkùnrin ti ń fipá bá mi lòpọ̀ nígbà márùn-ún - Iyabo Ojo
- Ẹ fi ilẹ̀ tí a kò lò hááyà fáwọn darandaran bíi ibùdó ọ̀sìn màálù - Tinubu
- Ondo ló lékè nínú ìpínlẹ̀ tó lùgbàdì àrùn Coronavirus júlọ ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá tún wa sílẹ̀, àwọn àjínigbe yìí le ṣe ohunkóhun fún wa
- Ìhòhò ọmọlúàbí ní òṣèrébìnrin yìí fi lọ sí àmi ẹ̀yẹ tí wọ́n pè é sí
O ni ko si ọmọ Yoruba to le lọ sapa Oke Oya lati wa kusa wọn nibẹ lai fa wahala, ti ọpọ eeyan to le ni ọgọrin si ti sa kuro lawọn abule to wa ni agbegbe Ibarapa nitori ọsẹ awọn janduku yii.
Gani Adams wa rọ awọn ọmọ Yoruba to n gbode gba fawọn janduku lati ronu piwada ki wọn si fọwọ sowọpọ fun isọkan ati irẹpọ ilẹ Yoruba.
O fikun pe ti wọn ba kọ lati ronu piwada, awọn yoo bẹ awọn alalẹ nilẹ Yoruba si wọn ni, pe ki wọn se wọn bi ọsẹ ti n soju.
Gani Adams ni ọpọ awọn ọdaran Fulani yii mọọmọ n sediwọ fun awọn agbẹ lati gbin ire oko tabi kore wọn ni nitori ki wọn le maa ko ounjẹ wa si ilẹ Yoruba lati apa oke ọya ni
"Ni ojoojumọ, miliọnu mejilelogun naira ni awọn eeyan apa oke ọya to n ko ounjẹ wa silẹ Yoruba n pa lọ sile, eyi si wọn ko se fẹ ka seto ọgbin ni aseye."
Gbogbo ipinlẹ ni mo rọ lati maa lo orin ibilẹ Oduduwa:
Nipa orin ibilẹ Yoruba to sẹsẹ jade, Aarẹ ni Oloye Obafemi Awolowo lo kọ orin naa silẹ, ko to ku, o si yẹ ki gbogbo ipinlẹ nilẹ Yoruba tẹwọ gba a.
O wa rọ awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba lati tẹwọgba orin ibilẹ Yoruba tuntun ti wọn sẹsẹ gbe jade.
"Orin ibilẹ wa naa lagbara pupọ, o n fun ni ni iwuri, imuyangan gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, tawọn ọdọ wa nile iwe ba si n kọ, yoo fun wọn ni iwuri gẹgẹ bii ogo alawọ dudu."
- Ṣé lóòtọ ni pé Alhaji Sikiru Ayinde Barrister ló bí Barry Jhay tí wọn fi ẹsun pípa Kashy kàn ní Ghana?
- A tọrọ àforíjì lórí ìdàmú tí ẹ là kọjá lẹ́yìn ìkéde àfikun owó epo bẹntiró - Ìjọba àpapọ̀
- Iye tí wọ́n ń ta jálá epo ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ jákàjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
- Iya Rainbow di ònílé tuntun, ilé méjì ni wọ́n fi ta á lọ́rẹ
- Àwọn ọ̀rẹ́ Kashy Godson bú sẹ́kún, wọ́n ń dárò, wọ́n ń sọ rere tó ti ṣe láyé
Nigba to n sọrọ lori awọn ọba alaye, aarẹ Gani Adams ni lootọ ni ominu n kọ oun lori bi awọn ọba alaye nilẹ Yoruba se bu ẹẹkẹ diwọ lori ikọlu awọn ọdaran darandaran.
O ni oun mọ pe diẹ lara awọn ọba alaye yii ni wọn fi tipa gbe le wa lori, ti wọn si n fun wa ni wahala se ams idajọ ọba, ọwọ eledumare lo wa.
Awọn eeyan to n tako wa laarin ẹya Yoruba ni isoro wa nitori awọn kan wa ti wọn n jowu wa, ti wọn si n sisẹ tako aseyọri wa.
O wa rọ awọn eeyan lati mase maa tabuku wọn lori aye amọ se la mọ baa se maa fi ara da fun wọn nitori awọn Fulani gan kii yaju si ọba tiwọn, ko si bi wọn se le buru to.
Idi ree ti mo fi n wọ asọ funfun, de fila Abeti Aja:
Bakan naa ni Aarẹ Gani Adams ti sisọ loju rẹ pe kii se pe oun wa ninu ẹgbẹ awo kan ni oun se maa n wọ asọ funfun, gẹgẹ bi awọn eeyan kan se lero.
Amọ o ni "Ohun ti ayanmọ mi fẹ ni asọ funfun ti mo n wọ nitori ki ẹsin to gba ọpọ nnkan lọwọ wa, akọsẹjaye wa lati mọ ohun ti isẹda ọmọ tuntun yoo jẹ.
Idile Musulumi ni wọn ti bi mi, ti ko si seese fun wọn lati beere akọsẹjaye mi amọ lasiko ti mo n se ẹgbẹ ọmọ Oduduwa, OPC, ọpọ ibi ti mo n lọ ni wọn ti salaye fun mi pe asọ tuntun ni ki n maa wọ."
Aarẹ Ọna Kakanfo fikun pe lati ọdun 2000 ni wọn ti n sọ ọrọ yii fun oun ams oun ko ja kunra, ti igbe aye oun ko si fi bẹẹ ni iyipada rere.
O ni nigba to di ọdun 2004 ni oun pinnu lọjọ kan, ti oun si ra asọ funfun bii ọgbọn, oun gbe fun aransọ lati ran, to fi mọ awọtẹlẹ oun si lo n funfun pẹlu lati igba naa.
"Awọn asọ to le ni igba lo wa ninu kọbọọdu asọ mi ti kii se funfun, mo si bẹrẹ si pin fawọn ọmọ ẹyin mi lọjọ naa, lati igba naa ni mo ti n wọ asọ funfun."
Aarẹ ni bakan naa fila gọbi ni oun maa n de sori tẹlẹ, to si maa n yun oun lori tabi fun oun ni ẹfọri amọ baba kan lo yọ si oun loju oorun pe ki oun bẹrẹ si ni de abeti aja.
O ni lati igba naa ni oun ti n de fila abeti aja ti aye mọ oun mọ, eyi si ni oun ro pe yoo jẹ ẹkọ fun awọn iran to n bọ.






















