John Magufuli: Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò mọ̀ rèé nípa Ààrẹ Tanzania tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin iku Aarẹ John Magufuli, oriṣiriṣi awọn ọrọ lo ti jade ipa irufẹ ẹni to jẹ lasiko to wa loke eepẹ.
- Magufuli ko ṣejọba bi ẹni to ṣaaju rẹ nitoti o jẹ ẹnikan to ja fafa ti ki si fi iṣẹ rẹ ṣere
- Bo ṣe maa n ṣeto ilu jẹ ki ọpọ eeyan fẹran rẹ lawọn orilẹ-ede to yi Tanzania ka, lara eyii to fa itakurọsọ oju opo Twitter #WhatWouldMagufuliDo ti ọpọ eeyan kopa ninu rẹ, eyii to ṣapejuwe bi ko ṣe faye gba iwa jẹgudujẹra
- Ariyanjiyan ti n waye lori boya ẹni ti yoo ṣejọba lẹyin rẹ yoo tukọ ilu gẹgẹ bi Magufuli ṣe ṣejọba, tabi ko ṣe ijọba bi o ṣe wu lọkan rẹ
- Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan fẹran bi Magufuli ṣe ṣejọba lasiko aye rẹ, awọn ii n fẹ Aarẹ ti yoo ṣe ododo, ti ko si ni fi bi eto ilera rẹ ṣe ri pamọ fun awọn eeyan ilu
- Iroyin ni Magufuli ku lẹyin to ti n ba arun ọkan finra fun ọjọ pipẹ, ṣugbọn ọpọ eeyan lo gbagbọ pe arun Coronavirus lo lo mu ẹmi rẹ lọ
- O ṣeni laanu pe magufuli lọ ṣiwaju arun ọhun lẹyin to kọkọ sọ pe arun naa ko si.
Aarẹ Tanzania, John Mugufuli jade laye lẹyin ahesọ pe o ni arun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, AFP
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Aarẹ orilẹede Tanzania, John Magufuli ti jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọta.
Igbakeji aarẹ lorilẹede naa, Samia Suluhu Hassan lo kede iku aarẹ Mugufuli pẹlu afikun pe ọjọru ni oloogbe naa dakẹ nile iwosan kan nilu Dar es Salaam.
Lasiko to n bawọn eeyan orilẹede naa sọrọ lori mohun maworan, Hassan ni o le ni ọsẹ meji ti aarẹ naa ti jade sita gbangba sẹyin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ewu tó rọ̀ ma kí wọn sin ọba tó ṣètùtù nílànà ẹ̀sìn Krìsítẹ́nì àti Islam
- Wo bí òfin owó sísan USSD tuntun tí báńkì CBN ṣe, ṣe kàn ọ́
- CCTV yọ Barry Jhay lórí ikú Kashy, òtítọ̀ ọ̀rọ̀ fojú hàn nígbẹ̀yìn
- Wo ibùdó tó sún mọ́ ọ láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 l'Eko
- El Rufai àtàwọn gómìnà míì ló n tako sísan owó oṣù tó kéré jùlọ - NLC
- Krìsìtẹ́nì àti Mùṣùlùmí ń sọ òkò lura wọn ní Ilorin torí aáwọ̀ lílo Hijab
- Agbébọn pa èèyàn 58 tó ń ti ọjà bọ̀, jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀, fi oúnjẹ ṣòfò
- Ilé ẹ̀kọ́ 10 tíjọba Kwara tìpa di ṣíṣí padà, akẹ́kọ̀ọ́bìnrin le lo Hijab níbẹ̀
Bẹẹ ni ahesọ ọrọ si ti n tan kalẹ nipa ipo ti ilera rẹ wa.
Koda, awọn ọmọ ẹgbẹ oselu alatako gan ti sọ lọsẹ to kọja pe Mugufuli ti ni arun Coronavirus, eyi ti wọn ko ti fidi rẹ mulẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Mugufuli jẹ skan lara awọn asaaju ilẹ Afirika to n siyemeji nipa arun Covid-19, to si n beere pe kawọn eeyan maa gbadura, ki wsn si maa fin agbo lati dena arun naa.
Igbakeji aarẹ Tanzania wa kede pe wọn yoo daro iku aarẹ naa fun ọjọ mẹrinla gbako, ti wọn yoo si fa asia orilẹede naa wa silẹ.
Nibamu pẹlu ofin orilẹede Tanzania, Igbakeji aarẹ yii ni wsn yoo bura fun lati gba ipo aarẹ, ti yoo si pari saa Mugufuli to ku ninu saa ọdun marun eyi to sẹsẹ lo ọdun kan pere.












