Barry Jhay: Àgbẹjọ́rò ní irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí náà wáyé sí Ayinde Barrister tí wọn ló pa èèyàn lẹ́yìn egúngún

Oríṣun àwòrán, Instagram/therealbarryjhay
Adura to yẹ ki onikaluku maa gba ki o to jade nile ni pe, ki Ọlọrun maa jẹ ki a ri alakoba.
Ọgbẹni Temitope Salami to jẹ agbẹjọro Oluwakayode Junior Balogun, ọmọ oloogbe akọrin Fuji, Alhaji Sikiru Ayinde Barrister ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Barry Jhay lo sọrọ yii lori ohun to ṣẹlẹ si i nipa iku ọrẹ rẹ, Kashy Godson niluu Accra lorilẹede Ghana.
Agbẹjọro Salami ni bi ọrọ Barry Jhay ṣe ri gan an niyii nipa bi awọn ọlọpaa orilẹede Ghana ṣe mu un gẹgẹ bi ọkan lara awọn afurasi ti wọn fọrọ wa lẹnu wo nipa iku Kashy.
- Àwọn ọ̀rẹ́ Kashy Godson bú sẹ́kún, wọ́n ń dárò, wọ́n ń sọ rere tó ti ṣe láyé
- Ẹgbẹ́ Òṣùgbó fi tipá gbé òkú Ọba ní Ijebu, mọ̀lẹ́bí fárígá
- Nígbà tí èmi náà rí fídíò Kashy tí ẹnu rẹ̀ ń ṣẹ̀jẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tó kú, mo bèrè àwọn ìbéèrè kan - Ẹ̀gbọ́n Barry Jhay
- Ọ̀daràn Fulani pa ọmọ mí, jó ile, ọ̀kọ́, tí ìlú wa sì di ahoro - Ará Yewa l‘Ogun figbe ta
- Krìsìtẹ́nì àti Mùṣùlùmí ń sọ òkò lura wọn ní Ilorin torí aáwọ̀ lílo Hijab
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí márùn ún míràn lórí ikú ọmọ Fasoranti
- Wakili àtàwọn méjì míì dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn, ìjínigbé àti olè kàn wọ́n
- Àwọn agbébọn jí èèyàn méjì gbé ní ibùdó tí wọ́n tí ń fọ́ òkúta ní Ibadan
- Anthony Joshua bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì láti kojú Tyson Fury nínú ìjà tí yóò yeruku lálá
Ọgbẹni Salami ṣalaye pe, Barry Jhay ko mọwọ, ko mẹsẹ nipa iku Kashy, atipe ọrẹ rẹ timọ timọ ni Kashy jẹ fun un.
Agbẹjoro Salami tun ṣalaye pe, ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Ghana ko figba kan fẹsun kan Barry Jhay pe o mọ nipa iku Kashy.

Oríṣun àwòrán, Barry Jhay
O ni wọn kan fọrọ wa a lẹnu wo lasan ni, kii ṣe Barry Jhay nikan, awọn ọlọpaa tun fọrọ wa eeyan mẹrin miran lẹnu wo ninu iṣẹ iwadii wọn.
"Asọdun awọn eeyan lasan lawọn kan n gbe kiri pe Barry Jhay lọwọ ninu iku Kashy.
Alaye ree lori bi isẹlẹ iku Kashy se waye to fi kan Barry Jhay?
Lọjọ ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ, ọtọ ni yara ti Barry Jhay wa, nigba ti Kashy ati ọrẹbinrin rẹ naa wa ninu yara mii.
Lojiji ni ọrẹbinrin Kashy sare lọ ba Barry Jhay ninu yara to wa pe oun ko mọ bi Kashy n ṣe mọ.
Barry Jhay ba sare lọ wo Kashy, ṣugbọn nigba to de ibi ti Kashy wa, ija ni Kashy gbe koju Barry Jhay ,ti o si bẹrẹ si ni lẹ nkan mọ an,'' agbẹjọro ṣalaye.
Ọgbẹni Salami ni nigba ti ọrọ ri bayii ni Barry Jhay sare kuro lọdọ Kashy pẹlu ẹjẹ lẹnu, lẹyin to ti ṣeeṣe, ti o ṣi lọ sọ fawọn agbofinro ni isalẹ nipa ohun to n sẹlẹ si Kashy.
Agbẹjọro Salami sọ pe leyin bi iṣẹju mẹwaa ti Barry Jhay sa kuro ni yara Kashy, ni Kashy jabọ lati ori oke kẹrin silẹ, ti o si gbabẹ di oloogbe.
''Kamẹra CCTV lo fi otitọ han pe Barry Jhay ko lọwọ ninu iku Kashy niluu Accra.
Awọn ọlọpaa ati ẹgbọn Kashy ati emi fun ra mi, ni a jọ wo kamẹra CCTV nibi ti a ti ri bi Kashy ṣe ku.
Ti ko ba si kamẹra CCTV ni, ko ba le diẹ lati fidi rẹ mulẹ pe Barry Jhay ko mọ ohun kan nipa iku Kashy.
Ayẹwo oku Kashy naa tun fihan pe, Barry Jhay ko lọwọ ninu iku ọrẹ ati ọga rẹ to di oloogbe.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Iru ipo wo ni Barry Jhay wa bayii lẹyin iku Kashy?
Nibayii, ọkan Barry Jhay bajẹ lori iṣẹlẹ yii nitori ọrẹ kori o sun ni oun ati Kashy jẹ.
Koda, Kashy fun Barry Jhay lẹbun ago ni bii ọjọ meji si ọjọ ti o jade laye,'' agbẹjọro Salami lo ṣalaye bẹẹ.
Ẹwẹ, agbẹjọro Salami sọ pe iru nkan to ṣẹlẹ si Barry Jhay ti ṣẹlẹ si oloogbe Ayinde Barrister lọdun 1974.
O ni wọn tiran mọ Barrister lọrun pe oun lo pa ẹni to ku lẹyin egungun kan ṣugbọn ododo pada foju han ni igbẹyin gbẹyin.
Ọgbẹni Salami ni lẹyin naa ni Barrister ṣe awo kan to pe akọle rẹ ni ''Okiki'' jade.


















