Funke Olakunrin: Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ ikú ọmọ Fasoranti sí oṣù kẹrin àti ìkarùn ún

Oríṣun àwòrán, @EyeinAfrica
Ikọ akọṣẹmọṣẹ ẹṣọ alaabo Force CID ati SWAT ti fi ṣikun ofin mu awọn eeyan marun un miran, ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu iku ọmọ adari ana fẹgbẹ Afẹnifẹre, Reuben Fasoranti, iyẹn Funke Olakunrin.
Iroyin naa di mimọ lasiko ti igbẹjọ awọn afurasi ti ọwọ kọkọ tẹ ṣaju n tẹsiwaju, nile ẹjọ giga to wa niluu Akure, eyi ti adajọ Bode Adegbehinde n dari rẹ.
Ẹjọ naa ni idaduro ranpẹ lẹyin ti agbẹjọro ijọba, Grace Olowoporoku sọ fun ile ẹjọ naa pe, ọwọ ti tẹ awọn afurasi miran lori ẹsun kan naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Agbébọn pa èèyàn 58 tó ń ti ọjà bọ̀, jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀, fi oúnjẹ ṣòfò
- Wakili àtàwọn méjì míì dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn, ìjínigbé àti olè kàn wọ́n
- Àwọn agbébọn jí èèyàn méjì gbé ní ibùdó tí wọ́n tí ń fọ́ òkúta ní Ibadan
- Agbẹnusọ Sunday Igboho ná N2.5m bíí owó oúnjẹ́ lásán, gbas gbos bẹ̀rẹ̀
- "Torí ₦20, ọlọ́pàá yìnbọn fún mi lọ́rùn, n kò sì le b'óbìnrin lòpọ̀ mọ́ tàbí bímọ''
- Bí Buhari kò bá ṣọ́ra, àwọn ọba alayé ni yóò ṣaájú ìjìjàgbara fún Yorùbá - Sunday Igboho
- Èèyàn mẹ̀rin kú, 189 wà nílé ìwòsàn torí ayédèrú ohun mímu tí wọn mu
Ṣaaju ni awọn agbofinro ti kọkọ mu awọn mẹrin kan lori ẹsun ipaniyan naa, ti wọn si ti n kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.
Wọn ko wọn lọ siwaju adajọ lori ẹsun mẹta ọtọọtọ, igbimọditẹ lati paayan, ipaniyan ati ijinigbe.

Oríṣun àwòrán, @RipplesNG
Ẹjọ ọhun ti wa niwaju adajọ lati oṣu Kẹjọ ọdun 2020, ṣugbọn ti ọwọ ti tẹ awọn afurasi marun un miran, iye eeyan to n jẹjọ lori iku arabinrin naa ti wa di mẹsan an.
Ọlọpaa to n ṣewadii ọrọ naa sọ pe, wọn lọ mu awọn marun un ọhun lẹyin ti orukọ wọn n jẹyọ nigba gbogbo lasiko ti igbẹjọ naa n lọwọ.
Grace Olowoporoku ti beere pe ki wọn sun ẹjọ naa siwaju, ki aye le wa lati ṣewadii awọn afurasi tuntun naa finni-finni.
Adajọ to n gbọ ẹjọ ọhun, Bode Adegbehingbe ti sun ẹjọ naa siwaju titi di ọjọ kẹtadinlọgbọn, ọjọ kọkandilọgbọn, ọgbọn ọjọ oṣu Kẹrin ati ọjọ karun un, osu Karun un, ọdun 2021.
Ti ẹ ko ba gbabe, oṣu Keje, ọdun 2019 ni awọn afurasi naa ṣekupa Funke Olakunrin loju ọna marosẹ Ore si Eko.

















