Sunday Igboho: Ẹ gbàgbé Gẹ̀ẹ́sì, ọpọlọ mi pé ju tàwọn tó kàwé lọ

Oríṣun àwòrán, Ooni, Sunday Igboho ati Alaafin
Ilumọọka ajafẹtọ iran Yoruba, Oloye Sunday Igboho, tun ti yọ suti ete sawọn eeyan to n kẹgan rẹ pe ko kawe debi to ni apẹrẹ.
Sunday Igboho, lasiko to n bawọn ololufẹ rẹ sọrọ lọjọ Aiku lo fesi pada fawọn ọmọ Yoruba to ni ko kawe to nnkan.
- Mò ń lọ ibùdó tí Fulani ti ń wa kùsà ní Idere, màá lé wọn dànù pátápátá - Sunday Igboho
- Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó dá mi lọ́nà lọ́jọ́ Ẹtì fẹ́ pa mí ni -Sunday Igboho
- Ǹkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Olórí Miyetti Allah ilẹ̀ Yorùbá
- Wo ohun tí BBC rí nílé Seriki Fulani ní Igangan
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Sunday Igboho wà lọ́nà Ibarapa, Seriki Fulani ní àwọn kó níbiì lọ, àrọ̀wà ló kù fúnwà
- Wo ǹkan mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sunday Igboho tí orúkọ rẹ̀ gbẹnu aráyé kán
- Ògo ilẹ̀ Yorùbá ní Sunday Igboho jẹ́, ẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ìràwọ rẹ̀ wọlẹ̀ - OPC
Igboho ni awọn ọmọ Yoruba kan lo n kẹgan oun pe oun ko yẹ ni ẹni ti yoo lewaju iran Yoruba nidi ijijagbara nitori pe oun ko gbọ ede oyinbo bo se yẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho
Igboho ni "Wọn ni n ko kawe, ti n ko si le ja fun iran Yoruba, amọ alaimskan ni wọn, ti ko ni laakaye."
Ajafẹtọ ọmọniyan naa ni ọpọlọ toun ju tawọn eeyan to n pẹgan oun lọ, bi o tilẹ jẹ pe oun ko kawe to wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ dáábò bo ara yín, a kò le ṣọ́ gbogbo ilé ẹ̀kọ́ Nàíjíríà - Ìjọba àpapọ̀ lahùn
- Ohun tó ṣe mi rèé nígbà tí mo gba abẹ́rẹ́ àjẹ́sára AstraZeneca - Kọ̀misáná fétò ìlera l‘Eko
- Níbo ní £46,933 owó ìrànwọ́ tí wọn dá fún Sunday Igboho wa?
- Ẹ mú ẹ̀rí tó dájú wá lórí ọ̀rọ̀ Fulani darandaran Wakili, ọlọ́pàá rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo
- Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ti fà kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Grammy tẹ́lẹ̀ rí
- Iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ láti dóòlà akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì Fásítì Olabisi Onabanjo táwọn agbébọn jígbé- Ọlọ́pàá
- Asari Dokubo tó kéde orílẹ̀èdè Biafra lu òfin ìdìtẹ̀ sí orílẹ̀-èdè - Àgbà Amòfin
- Ọwọ́ mi dẹ púpọ̀ ní Ayete, n kò kéde lórí ayélujára ní – Sunday Igboho
Igboho ni ilẹ Yoruba ni oun n ja fun, ko si si ohun to kan ohun ninu sisọ ede Gẹẹsi nitori bi aarẹ Amẹrika yoo ba ba oun sọrọ, ede abinibi oun ni oun yoo fi baa sọrọ.
Asiko yii lo si bẹrẹ si ni sọ ede Gẹẹsi, tawọn alatilẹyin rẹ si n sa ni mẹsan-mẹwa.
"Ko si ohunkohun ti mo fẹ gba lọwọ ẹni to pe ara rẹ ni ọjọgbọn fasiti, nitori gbogbo awọn ti wọn ni awọn gbọ eebo yii, iru wọn lo n se isẹ asọna lẹnu ọna ile mi."
"Ila ẹẹkẹ mi ni iwe ẹri pe mo jẹ ojulowo ọmọ Yoruba ti ko ni abula, ti ilẹ Yoruba ba si ni ominira tan, ede abinibi la mu lskunkundun.
Ede oyinbo ti wsn n gbe larugẹ yoo si jẹntẹdi, eyi ti ko ni wulo mọ rara."
N ko jẹ Aarẹ Ọna Kakanfo, ko si ohun ti mo fẹ fi se
Bakan naa ninu ifọrọwerọ ọhun ni oloye Sunday Igboho tun ti sisọ loju rẹ pe oun ko ni lero rara lati jẹ Aarẹ Ọna Kakanfo nilẹ Yoruba.
Igboho salaye pe oye to ga julọ, ti gbogbo agbaye fi mọ oun ni Igboho, Ọlọrun Ọba si lo fun oun.
"Ko si oye tẹ le fun mi laye yii, lai pe Igboho mọ, aye ko le mọ pe emi lẹ n sọrọ rẹ.
N ko nilo oye aarẹ ọna kakanfo kankan mọ lẹyin Igboho ti Ọlọrun fun mi."
Awọn ọba alaye setan lati siwaju ogun fun ijijagbara ilẹ Yoruba
Sunday Igboho tun ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ọba alaye ilẹ Yoruba ti wa lẹyin oun gbaa gbaa gbaa nidi ijijagbara fun ilẹ Yoruba.
Igboho ni "Iku Baba Yeye, alasẹ ekeji orisa lo n sọrọ lọwọ bi mo se n sọrọ yii, nitori o wa pẹlu wa.
Koda, Oonirisa Ọjaja Adeyeye Enitan Ogunwusi gan wa pẹlu wa, to fi mọ Awujale, Olugbon, Olu Ilaro atawọn ọba yoku ni agbegbe Oke Ogun to fi mọ Olukere.
Igboho ni awọn ọba alaye naa ti n sọ fun aarẹ Muhammadu Buhari pe ti ko ba sọra, o seese ko jẹ awọn ọba ilẹ Yoruba ni yoo siwaju ijijagbara yii gkgẹ bo se waye laye atijs ti ọba maa n siwaju ogun.
"Koda, gbogbo awọn kabiyesi ti kọ lẹta si Buhari lori ọrọ awọn apaayan Fulani pe funra awọn ni awọn yoo sigun, eyi to fi skan wa balẹ pe a ni baba to n ti wa lẹyin.'
Ọwọ́ mi dẹ púpọ̀ ní Ayete, n kò kéde lórí ayélujára ní - Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Instagram
Ilumọọka ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho, tun ti salaye lori bi irinajo rẹ silu Ayete lọjọru to kọja se ri.
Igboho, lasiko to n bawọn ọmọlẹyin rẹ atawọn araalu sọrọ lori ayelujara lọjọ Aiku lo ti salaye nipa irinajo rẹ ọhun.
Igboho ni " irinajo mi silu Ayete so eso rere pupọ, ti ọwọ oun si dẹ nidi sise awari awọn afurasi ọdaran darandaran amọ mo kọ lati kọkọ gbe sori ayelujara ni.
Awọn agbaagba Yoruba ti ba wa wi pe eeyan kii fi gbogbo ẹnu sọrọ, gbogbo asọ kọ la a saa loorun, a si ti gbọ, tori naa ni n ko se kọkọ gbe fidio sita nigba ti mo n lọ."
Igba ti Yoruba ba de ilẹ ileri, ti alaafia jọba ni maa to sinmi ijijagbara
O fikun pe diẹ ni fidio ati iroyin tawọn araalu gbọ nipa irinajo naa, kii si se gbogbo ohun ti oun ba n se, ni oun yoo maa gbe sori ayelujara mọ.
Igboho ni nigba toun di ilu Ayete de, ni oun to se fidio sita nipa awọn isẹ ribiribi ti oun se lati pe alaafia pada silu naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Rògbòdìyàn míì bẹ́ sílẹ̀ láàrin Yorùbá àti Bòròró ní Saki, ẹ̀mí bọ́, dúkìá ṣòfò
- Àlàyé rèé lórí bí wọn ṣe pa bàbá mi àti mọ̀lẹ́bí mi màrùn-ún l‘Osun - Ọmọ olóògbé
- Buhari fẹ́ yá ₦895m owó aráàlú ti wọn ko lo ní báǹkì, Serap fọnmu dele ẹjọ
- Ògo àgbáyé wọ Nàíjíríà, Burna Boy àti WizKid gbàmì ẹyẹ Grammy
- Mò ń lọ ibùdó tí Fulani ti ń wa kùsà ní Idere, màá lé wọn dànù pátápátá - Sunday Igboho
- Oloolu lọ ṣètùtù kí òjò rọ̀ n‘Ibadan, áwọn jàǹdùkú kọ lù ú, ọ̀pọ̀ ṣèṣe, ẹ̀mí sì bọ́
- Àwọn agbébọn láti Òkè Ọya ń wa góòlù ní Ilesa, Owo àti Igangan láì sí ìdíwọ́ - Gani Adams
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá tún wa sílẹ̀, àwọn àjínigbe yìí le ṣe ohunkóhun fún wa
- Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá làwọn ọkùnrin ti ń fipá bá mi lòpọ̀ nígbà márùn-ún - Iyabo Ojo
"Fidio ti mo gbe diẹ sita nipa ohun ta se nilu Ayete ni yoo jẹ kawọn eeyan mọ pe kii se ẹnu lasan ni oun fi n se ijijagbara fun ilẹ Yoruba, tabi pe a ti lọ sinmi tabi jami lori rẹ."
Sunday Igboho ni o di igba ti iran Yoruba ba de ilẹ ileri, toun ri pe alaafia ti wa, ki oun to sinmi nidi ijijagbara naa.
Mo n jẹ mọsa ọrọ Fulani ni eteeti lọwọ ni, n ko tii bo loju gan
Bakan naa lo ni oun si n jẹ mọsa ọrọ awọn ọdaran Fulani ni eteeti lọwọ ni, oun ko tii bo loju gangan amọ laipẹ ni oun yoo bo loju torotoro, ti Yoruba yoo si de ilẹ ileri.
Ajijagbara ọmọ ilẹ Yoruba naa wa fi ọwọ sọya pe awọn ọdọ tawọn n jija gbara fun ilẹ Yoruba lasiko yii, ni yoo gba ominira fun ilẹ Yoruba, kii si se iran to n bọ.
"Awọn ọmọ wa kọ ni yoo gba ominira fun iran Yoruba, awa ọdọ yii ni. Ẹ gbagbe pe a se aseti lori rẹ, ta si gbe le awọn ọmọ wa lọwọ.
Ọlọrun lo ti mi sita lati wa sisẹ yii, ko si oun ti mo fẹ, ti Ọlọrun ko fun mi, ko si yẹ ko jẹ iru emi ni yoo ma sisẹ ijijagbara yii, amọ Ọlọrun lo ran mi."
Yoruba, ẹ fun sokoto yin ko le, a ko boju wẹyin mọ
Ninu eto ibanisọrọ naa ni Igboho tun ti kesi awọn ọmọ Yoruba lati fun sokoto wọn ko le, nitori ko si ọrọ pe a n boju wẹyin mọ.
O fikun pe ko si ohunkohun kankan to le dun mọhurumshuru mọ wa mọ.
"Sheik Gumi mọ ibi ti awọn ajinigbe agbebọn wa, to si n beere pe ki ijọba darijin wọn. Amọ awa ta n fẹ alaafia fun Yoruba lẹ n ko, tẹ fẹ gbe sahamọ, ko le seese.Yoruba, ẹ fun sokoto yin ko le, a ko boju wẹyin mọ























