2021 Grammy Awards: Àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ti fà kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Grammy tẹ́lẹ̀ rí rèé

King Sunny Ade, Femi ati Seun Kuti

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Burna Boy ati Wizkid gbe ogo orilẹede Naijiria ga lẹyin ti wọn wa lara awọn to gbami ẹyẹ Grammy ninu orin takasufe.

Burna Boy to dantọ julọ lagbaye pẹlu awo orin rẹ to pe ni "Twice as tall," nigba ti Wizkid gba ẹyẹ tirẹ pẹlu ilumọọka olorin ilẹ Amẹrika, Beyoncé ati Blue Ivy.

Akọle orin ti wọn jọ kọ papọ lati gba ami ẹyẹ naa ni wọn pe ni "Brown Skin Girls."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, awọn alaṣẹ ami ẹyẹ Grammy ti fa awọn olorin kan to jẹ ọmọ Naijiria kalẹ fun awọn ami ẹyẹ Grammy tẹlẹ ri. Orukọ wọn ni wọnyii:

1. King Sunny Ade

Gbajugbaja olorin Juju, King Sunny Ade ni olorin ọmọ Naijiria akọkọ ti wọn kede orukọ rẹ lara awọn ti wọn mu lati gba ami ẹyẹ Grammy.

Koda igba meji ni orukọ KSA ti jade fun ami ẹyẹ Grammy.

Ọdun 1984 ni wọn kọkọ kede orukọ Sunny Ade fun ami ẹyẹ Grammy pẹlu orin rẹ to pe ni Syncro System ni ẹka orin ibilẹ.

King Sunny Ade

Oríṣun àwòrán, Instagram/sunnyadeofficial

Wọn kede King Sunny Ade fun ami ẹyẹ Grammy lọdun 1999, ni ẹka awo orin to pegede julọ.

2. Babatunde Olatunji

Onilu ara, Babatunde Olatunji ni ọmọ Naijiria keji ti iṣẹ orin to yan an laayo gbee de ibi ami ẹyẹ Grammy.

Ọdun 1998 ni wọn kede orukọ Olatunji fun ami ẹyẹ Grammy ni ẹka onilu to pegede julọ julọ lagbaaye.

Wọn bi Ọgbẹni Olatunji ni ilu Ajido ti ko jinna si Badagry nipinlẹ Eko lọdun 1927.

Babatunde Olatunji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdun 1950 ni Olatunji fi Naijiria silẹ lọ si orilẹede Amẹrika.

3. Femi Kuti

Olorin Afro, Femi Kuti ni olorin ọmọ Naijiria kẹta ti wọn fa kalẹ fun ami ẹyẹ Grammy.

Wọn fa Femi silẹ fun ami ẹyẹ Grammy lọdun 2003, 2010, 2012 ati 2014.

Ẹka awo orin to pegede julọ ni wọn kede ori Femi to akọle rẹ ni ''Fight to Win'' lọdun 2003.

Femi Kuti

Oríṣun àwòrán, Instagram/femikuti

Ọdun 1962 ni wọn bi Femi niluu London, oun si ni ọmọkunrin akọkọ oloogbe olorin Afro, Fela Anikulapo Kuti.

4. Wizkid

Ayodeji Ibrahim Balogun ti ọpọ mọ si Wizkid kọkọ pegede fun ami ẹyẹ Grammy pẹlu iṣẹ ajọṣepọ rẹ pẹlu olorin takasufe ilẹ Amẹrika, Drake lọdun 2015.

Ilumọọka olorin ni Wizkid ti ọpọ gbagbọ pe o bẹrẹ iṣẹ orin kikọ lọmọ ọdun mọkanla.

Wizkid

Oríṣun àwòrán, Instagram/Wizkidayo

Wizkid di ẹni tu araye n sọ nipa rẹ lagba ile orin lọdun 2011 lẹyin to gbe orin ''Holla at Your Boy'' jade.

5. Seun Kuti

Seun Kuti to jẹ ọkan lara awọn ọmọkunrin oloogbe Fela Kuti to n kọrin jọ ọkan lara awọn olorin ọmọ Naijiria ti wọn fa kalẹ fun ami ẹyẹ Grammy lọdun 2018.

Ẹka awo orin to pegede julọ ni wọn ti fa Seun kalẹ fun ami ẹyẹ Grammy pẹlu orin to pe akọle rẹ ni ''Black Times.''

Seun Kuti

Oríṣun àwòrán, Instagram/Seun Kuti

Seun ni ọmọkunrin Fela to kere julọ, oun lo si n dara ẹgbẹ olorin baba rẹ ti wọn n pe ni Egypt 80.

6. Burna Boy

Burna Boy tun ni olorin takasufe ni Najiria ti wọn ti fa kalẹ fun ami ẹyẹ Grammy.

Ọdun 2019 ni wọn kọkọ fa Burna Boy kalẹfun ami ẹyẹ Grammylori orin rẹ to pe ni ''Fall Out Boy's Mania.''

Burna Boy

Oríṣun àwòrán, Instagram/Burna Boy

Ọdun 2020 ni wọn tun kede Burna Boy fun ẹka awo orin to pegede julọ ti o pe akọle rẹ ni ''African Giant.''

Ṣugbọn Burna Boy pada gba ami ẹyẹ Grammy lọdun 2021 yii pẹlu orin rẹ to pe ni ''Twice as Tall.''

7. Chimamanda Ngozi Adichie

Chimamanda Ngozi Adichie ni obinrin akọkọ to jẹ ọmọ Naijiria ti wọn kọkọ kede orukọ rẹ fun ami ẹyẹ Grammy.

Wọn fa Chimamanda kalẹ fun ami ẹyẹ Grammy lọdun 2015 lori ajọṣepọ rẹ pẹlu olorin Amẹrika, Beyonce ti wọn pe orukọ rẹ ni ''Flawless.''

Chimamanda ti ọpọ maa n pe ni CNA jẹ gbajugbaja onkọwe ati ajijagbara fun ẹtọ awọn obinrin.

Chimamanda Adichie

Oríṣun àwòrán, Instagram/chimamanda_adichie

Oun lo kọ awọn iwe pẹlu akori bii ''Purple Hibiscus, Half of a Yellow Sun, The Thing Around Your Neck, Americanah, ati We Should All Be Feminists.''

Ògo àgbáyé wọ Nàíjíríà, Burna Boy àti WizKid gbàmì ẹyẹ Grammy

Awọn gbajugbaja olorin takasufe meji to jẹ ọmọ Naijiria, Burna Boy ati Wizkid ti gba ami ẹyẹ Grammy fun igba akọkọ.

Burna Boy gba ami ẹyẹ awo orin to pegede julọ lagbaye pẹlu awo orin rẹ to pe ni "Twice as tall."

Grammy

Oríṣun àwòrán, @AfricaFactsZone

Lara awọn ti wọn jọ n du ami ẹyẹ naa ni ipele awo orin to pegede julọ ọhun ni awọn olorin juju lati ilu New York, Antibalas, ọmọ ilẹ Brazil-Amẹrika, Bebel Gilberto, olorin ọmọ ilẹ Gẹẹsi ati India, Anoushka Shankar atawọn mii.

Eyii ni igba keji ti wọn yoo fa Burna Boy kalẹ fun ami ẹyẹ naa ṣugbọn o fidi rẹmi nigba akọkọ lẹyin ti ọmọ orilẹ-ede Benin, Angélique Kidjo fidi rẹ janlẹ lọdun naa lọhun.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Lẹyin to gba ami ẹyẹ naa tan, Burna Boy sọ pe "aṣeyọri yii jẹ ti awọn iran mi nilẹ Afrika kaakiri gbogbo agbaye."

Grammy

Oríṣun àwòrán, @TheNationNews

"Ati pe ami yii jẹ ẹkọ fun gbogbo ọmọ ilẹ adulawọ pe ko si ibikiti ti eeyan ba wa tabi ohunkohun ti ko le ṣaṣeyọri ninu rẹ to ba tẹpamọṣẹ."

Wizkid naa ti darapọ mọ awọn to ti gba ami ẹyẹ Grammy lagbaye lẹyin to gba ami ẹyẹ ọhun fun igba akọkọ.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Orin rẹ to pe ni "Brown Skin Girls" to gbe jade pẹlu gbajugbaja olorin ilẹ Amẹrika, Beyoncé ati Blue Ivy lo fun ni ami ẹyẹ naa.

Lara awọn olorin miran to lamilaka lagbaye to tun gba ami ẹyẹ Grammy ọdun yii ni; Kanye West, Nas, John Legend, Billie Eilish, Taika Watiti, Lady Gaga, Dolly Parton pẹlu Zach Williams, ati bẹbẹ lọ.

Ami ẹyẹ Grammy ni ami ẹyẹ awọn olorin to gbajumọ julọ lagbaye.

Oṣu Kinni ọdun 2021 yii lo yẹ ki ayẹyẹ naa waye ṣaaju ṣugbọn awọn to n ṣagbatẹru rẹ sun si oṣu Kẹta nitori ajakalẹ arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra.

Àkọlé fídíò, Prophet Shittu Adeniyi: Ẹni tó bá ń tọrọ agbe, kìí jẹ́ èèyàn ní mo ṣe tẹ́pa mọ́ṣẹ́