Forbes Africa: Davido, Wizkid, Falz kogoja lẹ̀ka amuludun ní Áfíríkà

Oríṣun àwòrán, AFP
Iwe atigbadegba agbaye kan, Forbes Africa ti tọka si awọn gbajugbaja onkọrin ọmọ orilẹede Naijiria kan gẹgẹ bii ara awọn ọdọ ti o lamilaaka julọ lẹnu iṣẹ ti wọn yan laayo nilẹ Afirika.
Awọn onkọrin taka-sufe hip-hop, Davido pẹlu Wizkid wa alara awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti Forbes Africa tọkasi gẹgẹ bii wọọ kilumọ ti wọn n dabi ẹdun, rọ bi owe lẹka iṣẹ ti wọn yan laayo.
Ẹka mẹta ni wọn pin awọn ti wọn kede si, ẹka ọgbọn atinuda, imọ ẹrọ ati oowo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn miran ti wọn tun darukọ ni Falz, Sarkodie, Nasty C, Cassper Nyovest, Falz, Yemi Alade, Beverly Naya, Sonia Irabor ati bẹẹbẹẹ lọ.
Bakanna ni wọn tun mu awọn oludalee'sẹ aṣaraloge silẹ bii Adebayo Oke-Lawal ati Tania Ọmọtayọ, Anita Adetola Adetoye ati Joyce Jacobs pẹlu.









