Russia 2018: Salah yóò gbá bọ́ọ̀lù fún Egypt nínú ìdíje àgbáyé

Oríṣun àwòrán, SERGEI SUPINSKY/AFP/Getty Images)
Orílè-èdè Egypt ti kéde orúkọ Mohammed Salah mọ́ àwọn tí yóò sójú rẹ ni ìdíje àgbáyé ni Russsia
T'òhun tí pé Salah n tọjú ará rẹ lataari ìpeníjà ifarapa to wáyé nínú aṣekagba ìdíje Champions League; yóò lọ sidije agbaye fun Russia.
Salah ti o jẹ ọmọ ọdún meedọ́gbọ̀n kò ní lè dárapo mọ àwọn akẹgbẹ rè títí dì ọjọ́ kẹsán an, oṣù kẹfà nítorí pé ò n gba ìtọjú lọwọ.
Ifẹsẹwọnsẹ àkọkọ Egypt yóò wáyé pẹlú Uruguay ni ọjọ keedogun, oṣù kẹfà.
Wọn yóò tún pàdé Russia ni ọjọ kọ́kàndínlọ́gbọ̀n tí wọn yóò sì parí pẹlú Saudi Arabia ti wọn yóò jo wàá kò ní ọjọ keedọ́gbọ̀n oṣù kẹfà.
Ṣugbọn ṣáájú ìgbà náà, Salah kò ní lè kópa nínú ifẹsẹwọnsẹ Egypt pẹlú orílè-èdè Belgium lọjọru.
Egypt ati Colombia ti kókó gba ọmi lorílè-èdè Italy lọjo Ẹtì tó kọjá.








