Sunday Igboho: Olùkówójọ gbọnmú fún agbẹnusọ Igboho tó ní ₦2.5m kìí ṣe bàbàrà fún owó oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Awuyewuye ti n waye lori owo kan ti iye rẹ to miliọnu meji abọ naira ti awọn eeyan da lati ṣagbatẹru ijijagbara ti Oloye Sunday Igboho n ja fun ilẹ Yoruba.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn eeyan da owo naa si ikawọ arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Maureen Badejọ, to si yẹ ki Maureen fi owo ọhun ṣowọ si Oloye Igboho.
Wahala bẹ silẹ lẹyin ti Maureen sọ pe oun fi owo naa ṣọwọ si Olayomi Koiki, ti ọpọ mọ si Koiki Media, to jẹ agbẹnusọ ajijagbara naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bí Buhari kò bá ṣọ́ra, àwọn ọba alayé ni yóò ṣaájú ìjìjàgbara fún Yorùbá - Sunday Igboho
- Akẹ́kọ̀ọ́ ogún lọ lúwẹ̀ẹ́ léti òkun, 15 kú, mẹ́ta pòórá, méjì yè
- Gómìnà Yorùbá, ẹ lo ààbò lábẹ́lé láti ṣọ́ ìpínlẹ̀ yín, ẹ má gbára lé ọlọ́pàá - Afenifere
- Ẹ dáábò bo ara yín, a kò le ṣọ́ gbogbo ilé ẹ̀kọ́ Nàíjíríà - Ìjọba àpapọ̀ lahùn
- Ohun tó ṣe mi rèé nígbà tí mo gba abẹ́rẹ́ àjẹ́sára AstraZeneca - Kọ̀misáná fétò ìlera l‘Eko
Iroyin naa ni lẹyin ti Koiki gba owo naa tan, ko fidi rẹ mulẹ fun Maureen pe owo naa ti de ikawọ oun fun nnkan bi ọsẹ meji.

Oríṣun àwòrán, @ThePentecostNG
Ko pẹ si asiko yii ti awuyewuye bẹrẹ si n waye lori owo naa, ti wọn pe ni owo ounjẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Idi ree ti Muareen fi ṣe fidio kan, nibi to ti kesi Koiki lati wa sọ boya o ti gba owo naa tabi ko tii gba.
- Níbo ní £46,933 owó ìrànwọ́ tí wọn dá fún Sunday Igboho wa?
- Ẹ mú ẹ̀rí tó dájú wá lórí ọ̀rọ̀ Fulani darandaran Wakili, ọlọ́pàá rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo
- Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ti fà kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Grammy tẹ́lẹ̀ rí
- Iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ láti dóòlà akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì Fásítì Olabisi Onabanjo táwọn agbébọn jígbé- Ọlọ́pàá
- Asari Dokubo tó kéde orílẹ̀èdè Biafra lu òfin ìdìtẹ̀ sí orílẹ̀-èdè - Àgbà Amòfin
- Ọwọ́ mi dẹ púpọ̀ ní Ayete, n kò kéde lórí ayélujára ní – Sunday Igboho
Bo tilẹ jẹ pe ibeere ọhun ati gbagede eto ti Muareen ti beere nipa owo naa ko dun mọ Koiki ninu, o fesi pe lootọ ni oun gba owo ọhun gẹgẹ bii owo ounjẹ.
Gẹgẹ bii ohun ti Maureen sọ, o ni oun n reti ki Koiki kede pe oun ti gba owo naa, ki awọn eeyan to da owo ọhun le mọ bo ṣe n lọ.
Nigba ti Maureen n beere lọwọ rẹ, idi ti ko ṣe fi ohun ransẹ pe oun ti gba owo naa lẹyin ọsẹ meji, ni Koiki ba dahun pe owo ounjẹ lasan ni N2.5 miliọnu, ati pe kii ṣe nnkan babara nitori awọn eeyan ti da owo to ju bẹẹ lọ fun ijagbara ọhun.
Ọrọ ti Koiki sọ yii, pe owo na ko jẹ tuntun ati nnkan babara lobi Muareen ninu, to bẹẹ ti awọn mejeji fi n ta ohun sira wọn.
Lẹyin naa ni Maureen ni ki Koiki fi ori eto oun silẹ.
Gbas gbos to waye laarin Maureen ati Koiki ti wa mu ki obinrin naa ke si ileeṣẹ GoFundMe lati da gbogbo owo to gba lọwọ ara ilu to nifẹ lati ṣagbatẹru ijijagbara ti Sunday Igboho n ṣe, pada fun wọn.
Ti ẹ ko ba gbagbe, oṣu diẹ sẹyin ni Ololye Sunday Igboho kede Koiki Media gẹgẹ bii ojulowo agbẹnusọ oun, lẹyin ti awọn kan bẹrẹ si ni ṣi oriṣiri oju opo lorukọ rẹ.
Níbo ní £46,933 owó ìrànwọ́ tí wọn dá fún Sunday Igboho wa?

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho Instagram
Awuye wuye ti n waye lori owo iranwọ fun isẹ ijijagbara ti wọn da fun Oloye Sunday Igboho, tii se ajijagbara kan fun iran Yoruba.
Idi ni pe Igboho ti kede fun araye pe oun ko gba owo kankan to to ogoji miliọnu naira tawọn eeyan kan n pariwo pe wọn ko fun oun.
Igboho, ninu fidio kan to ti bawọn araalu atawọn ọmọlẹyin rẹ sọrọ lọjọ Aiku ni ọrọ yii ti jẹyọ.
- Ọwọ́ mi dẹ púpọ̀ ní Ayete, n kò kéde lórí ayélujára ní – Sunday Igboho
- Mò ń lọ ibùdó tí Fulani ti ń wa kùsà ní Idere, màá lé wọn dànù pátápátá - Sunday Igboho
- Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó dá mi lọ́nà lọ́jọ́ Ẹtì fẹ́ pa mí ni -Sunday Igboho
- Ǹkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Olórí Miyetti Allah ilẹ̀ Yorùbá
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Wo ǹkan mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sunday Igboho tí orúkọ rẹ̀ gbẹnu aráyé kán
- Ògo ilẹ̀ Yorùbá ní Sunday Igboho jẹ́, ẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ìràwọ rẹ̀ wọlẹ̀ - OPC
O ni "Owo ti wọn ni wọn da fun mi, pe wọn gbe ogoji miliọnu naira fun mi, n ko gba owo kankan lọwọ ẹnikẹni.
Miliọnu mẹfa ati aabọ naira (N6.5m) pere lo tẹ mi lọwọ. Awọn ti mo sọrọ wọn jade ninu fidio ti mo se nikan lo fun mi lowo naa, mo si kede rẹ nigba naa."
Ajijagbara ọmọ Yoruba naa fikun pe "owo rẹpẹtẹ ti wọn da fun Maureen, a ko ri gba, gbogbo ẹnu ni mo fi sọ.
Awọn eeyan kan fọkan si pe mo gba ogoji miliọnu naira, amọ n ko ri gba. Madam Maureen naa ni oun ko ri owo naa gba.
O ni GoFundme ko gbe owo naa kalẹ, n ko si sọ ohunkohun, tori owo naa kọ la n na."
Sunday Igboho ni ojoojumọ ni awọn n dana pẹlu awọn ọmọlẹyin oun, tawọn n jẹun, da epo sinu ọkọ tawọn n gbe kiri.
Amọ o fikun pe yiyọ ẹkun oun lori ọrọ naa, ti ojo kọ rara.
Ibeere to wa n gba ẹnu ọpọ eeyan ni pe nibo ni owo tuulu yii wa nigba ti ko de ọdọ Sunday Igboho?
Ogundamisi sọrọ lori owo iranwọ ti wọn kojọ fun Igboho
Sugbọn lẹyin ọjọ kan ti Sunday Igboho sọrọ yii lori ayelujara, ni gbajumọ kan nipa ohun to n lọ lawujọ, Kayode Ogundamisi fi ikede kan soju opo Twitter rẹ nipa owo naa ni aarọ ọjọ Aje oni.
Ninu ikede naa ni Ogundamisi ti salaye pe obinrin kan, Maureen Badejo, ti wọn fi ẹsun ikowojẹ kan, ti kọwe si ajọ GoFundMe pe ko da owo to din diẹ ni miliọnu mẹtadinlaadọta pọun (£46,933) pada.

Oríṣun àwòrán, @ogundamisi
Owo iranwọ yii, to ni wọn ko jọ fun Sunday Igboho lo ni ki ajọ naa da pada fun awọn eeyan to da owo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Rògbòdìyàn míì bẹ́ sílẹ̀ láàrin Yorùbá àti Bòròró ní Saki, ẹ̀mí bọ́, dúkìá ṣòfò
- Àlàyé rèé lórí bí wọn ṣe pa bàbá mi àti mọ̀lẹ́bí mi màrùn-ún l‘Osun - Ọmọ olóògbé
- Buhari fẹ́ yá ₦895m owó aráàlú ti wọn ko lo ní báǹkì, Serap fọnmu dele ẹjọ
- Ògo àgbáyé wọ Nàíjíríà, Burna Boy àti WizKid gbàmì ẹyẹ Grammy
- Mò ń lọ ibùdó tí Fulani ti ń wa kùsà ní Idere, màá lé wọn dànù pátápátá - Sunday Igboho
- Oloolu lọ ṣètùtù kí òjò rọ̀ n‘Ibadan, áwọn jàǹdùkú kọ lù ú, ọ̀pọ̀ ṣèṣe, ẹ̀mí sì bọ́
- Àwọn agbébọn láti Òkè Ọya ń wa góòlù ní Ilesa, Owo àti Igangan láì sí ìdíwọ́ - Gani Adams
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá tún wa sílẹ̀, àwọn àjínigbe yìí le ṣe ohunkóhun fún wa
- Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá làwọn ọkùnrin ti ń fipá bá mi lòpọ̀ nígbà márùn-ún - Iyabo Ojo
Nibayii, BBC Yoruba ti n gbe igbesẹ lati ba Maureen Badejo sọrọ lori isẹlẹ yii lati mọ ibi ti ọrọ owo owo iranwọ naa de duro ati bi owo naa se rin.
Bo ba se lọ si, a maa mu iroyin ọhun wa fun yin.






















