Sunday Igboho: OPC fẹ́ k'awọn oríadé Yorùbá parí aáwọ̀ láàrín Igboho àti Seyi Makinde

Seyi Makinde ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi makinde

Yoruba ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ

Eyi lo mu ki ẹgbẹ apapọ ọmọ Oodua, OPC fi n kesi awọn lọbalọba ilẹ Yoruba pe ki wọn wa ọna lati pari aawọ to n waye laarin Gomina Seyi Makinde ati Sunday Igboho.

Arọwa naa ni OPC, ẹka tipinlẹ Oyo fi sita fun awọn akọroyin lẹyin ipade wọn kan to waye nilu Ibadan.

Alaga ẹgbẹ OPC ni ipinlẹ Oyo, Rotimi Olumo ni ''o ṣe pataki lati wa wọrọkọ fi ṣada pẹtu aawọ naa, paapa lasiko yii tilẹ Yoruba n koju ipenija aabo lọwọ awọn darandaran Fulani''

Aworan idanimọ OPC

Oríṣun àwòrán, OPC

Olumo ni ṣiṣe atunto eto aabo ṣe pataki ati pe idunkoko mọ Igboho ko le seso rere nitori eyi kii ṣe ọna abayọ si ọrọ to wa nilẹ naa.

''Abẹwo Igboho si Igangan jẹ igbesẹ to tọ, a ko si gbọdọ fi da wahala silẹ laarin rẹ ati aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba''

O fi kun pe ''Sunday Igboho ti ṣe iṣẹ ribiribi lati mu alaafia ba ilẹ Yoruba, awọn lọbalọba wa ni lati bẹnu atẹ lu iwa aburu ọwọ awọn Fulani, wọn ko si gbọdọ jẹ ki wọn bori wa''

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

Bakan naa ni Olumo bẹnu atẹ lu bawọn kan ti ṣe lọ fina si ile Igboho to wa ni agbegbe Soka.

O wa kesi awọn alaṣẹ lati ri wipe gbogbo awọn to mọ nipa iṣẹlẹ ọhun foju wina ofin.