Sunday Igboho: N kò fẹ́ oyè ọ̀gá àgbà páta fún ikọ̀ Amotekun nílẹ̀ Yorùbá
Ṣe lootọ ni pe wọn fẹ fi oloye Sunday Adeyẹmọ, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho jẹ olori gbogbo iko amọtẹkun ilẹ Yoruba?
Ibeere to n ja kaakiri ree bayii lẹyin ipade apapọ awọn gomina ipinlẹ ilẹ Yoruba to waye lọjọ Aje nilu Akurẹ, tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo.
Sunday Igboho lo bọ si agbami ojutaye iroyin lẹyin to gbe gbedeke ọjọ meje kalẹ fawọn Fulani nilu Igangan lagbegbe Ibarapa laipẹ yii.
- Sunday Igboho yarí lórí àwọn ‘ọ̀rọ̀ ìbajẹ́’ tí Babafemi Ojudu kọ nípa rẹ̀
- Wo kókó 15 tí wọn fẹnu kò lé lórí níbi ìpàdé àwọn gómìnà àti darandaran
- Ṣọ́jà àti ikọ̀ aláàbò ESN tí Nnamdi Kanu, ṣíná ìbọn fúnra wọn Gómìnà Uzodinma òfin ìséde kalẹ̀
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
- N kò le ṣàtìlẹyìn fún arúfin láti tán ìṣòro ètò ààbò - Seyi Makinde
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
Igboho ni ki awọn ọdaran Fulani naa ko aasa wọn nitori iwa ifipabanilopọ, ijinigbe, idigunjale ati ipaniyan ti wọn n hu.

Awọn eeyan kan to sunmọ Igboho bi iṣan ọrun, la gbọ pe wọn lu awo ọrọ naa si awọn akọroyin leti.
Amọ nigba to n fesi lori ahesọ ọrọ naa fun awọn akọroyin, ti BBC Yoruba wa lara wọn, Sunday Igboho ni oun ko fẹ ipo oludari patapata fun ikọ Amotekun yika ilẹ Yoruba, ti wọn n yọ ọ naa.
O ni oun to jẹ oun logun bayii ni bi awọn ọdaran Fulani yoo se fi ilẹ Yoruba silẹ, ti alaafia yoo si jọba pada.
"N ko nilo ipo olori Amotekun tabi owo lọdọ ẹnikẹni tabi oloselu kankan.
Alaafia fun awọn Yoruba lo jẹ mi logun lasiko yii, kii se ipo rara."
Sunday Igboho wa rọ awọn gomina to n daba iyansipo naa lati mase fi oun jẹ oye naa.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Lootọ ni awọn kan lara awọn alatilẹyin Sunday Igboho ko fọwọ si igbesẹ naa, amọ sibẹsibẹ ọpọ wọn lo ti gba aba naa wọle gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
- Kìí ṣe àgbẹ̀ nìkan ni ọ̀daràn darandaran n pa, wọ́n n pa àwa Fulani nàá - Ààrẹ Miyetti Allah
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Afurasí Fulani daran-daran fi ìbọn fọ́ ìka obìnrin kan lójú pópó
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí Igangan
Ikọ Amọtẹkun lawọn ijọba ẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria gbe kalẹ lati koju gulegule awọn Fulani darandaran to n da omilẹgbẹ ọran kaakiri ẹkun naa.
Ẹ̀rú kò bà mí lórí ìkéde ọ̀gá ọlọ́pàá láti gbé mi sí àhámọ́ - Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Adeyemo
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Ajafẹtọ ọmọ Yoruba to lewaju lori ọrọ aawọ to da lori gulegule awọn Fulani si ẹya Yoruba, Sunday Igboho ti sọ pe, oun ko bẹru ihalẹ atimọle ti awọn alaṣẹ n daba rẹ.
Ninu fọnran fidio kan to lu ayelujara pa ni o ti sọ ọrọ yii, to si tun dupẹ fawọn agbaagba Yoruba fatilẹyin wọn.
Igboho sọ pe ''awọn darandaran ko le le wa kuro lori ilẹ wa, oju wa ti ṣi bayi, ayafi ti wọn ba fẹ pa wa lo ku''
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Kìí ṣe àgbẹ̀ nìkan ni ọ̀daràn darandaran n pa, wọ́n n pa àwa Fulani nàá - Ààrẹ Miyetti Allah
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Afurasí Fulani daran-daran fi ìbọn fọ́ ìka obìnrin kan lójú pópó
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí Igangan
O wa kesi awọn alatilẹyin rẹ lati mase kọ ẹnu eebu sawọn ọba alade ilẹ Yoruba.
Bakan naa ni Igboho n fọwọ gbaya pe ẹru ko ba oun rara lori asẹ ọga agba ọlọpaa to ni ki wọn mu oun wa.

Oríṣun àwòrán, @SundayIgboho2
''Ẹ maṣe tẹnbẹlu awọn ọba Yoruba wa tabi ki ẹ bẹnu atẹ lu wọn. Mo fi ogun bura, inu awọn naa ko dun si ohun to n sẹlẹ yii. Wọn ti n sọrọ soke bayii''
O ni "idi ree ti gbogbo wọn ati awọn olori ilẹ Yoruba fi dide pe ki wọn ma ṣe mu Sunday Igboho."
- Ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Oduduwa ló mú kí Yorùbá wá kọlu Fulani ní Igangan - Ọmọ Seriki Fulani
- Báyìí ni àwa àti Sunday Igboho ṣe rìnrìn àjò láti Ibadan lọ sí Igangan"
- Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn lọ́balọ́ba, ọlọ́pàá àti Seyi Makinde fẹ́ gbé lórí áàwọ Ibarapa
- Wo ǹkan mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sunday Igboho tí orúkọ rẹ̀ gbẹnu aráyé kán
- Ó tó gẹ́! Ọ̀gá Ọlọ́pàá pàṣẹ pé kí Kọmísọ́nnà Oyo mú Igboho wà sí Abuja
''Ohun to bani ninujẹ ni bi wọn ṣe n ṣe wa baṣubaṣu, ti wọn n pa awọn ọmọ obinrin wa, ti awọn afurasi apaayan darandaran yii tun n fipa bawọn lo pọ.A ko le lọ si oko mọ, a ko le lọ sodo.O to gẹ!''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bi a ko ba gbagbe laipẹ yi ni ọga patapata ọlọpaa Naijiria paṣẹ ki Kọmisana ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo mu Sunday Igboho wa si Abuja lati wa jẹjọ.
Eyi waye lẹyin to lọ si Ibarapa lati lọ sọ fun olori awọn Fulani nibẹ pe ki wọn kuro nilẹ awọn laarin ọjọ meje.

Oríṣun àwòrán, https://www.instagram.com/sunday_igboho1/
Sunday Igboho sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí Igangan
Eekan ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ti sọrọ fun igba akọkọ lyin to sabẹwo silu Igangan lọjọ Ẹti.
Sunday Igboho ṣalaye pe asiko to fawọn alakoso iṣejọba ni ilẹ Yoruba lati mọ pe, bi wọn ba kuna lati mojuto abo araalu to dibo fun wọn, ko si igba ti araalu o ni gbe ara wọn nija.
Oloye Sunday Igboho ṣalaye eyi ninu awọn atẹjade kan to fi sita loju opo Twitter rẹ, @SundayIgboho2
- Ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Oduduwa ló mú kí Yorùbá wá kọlu Fulani ní Igangan - Ọmọ Seriki Fulani
- Báyìí ni àwa àti Sunday Igboho ṣe rìnrìn àjò láti Ibadan lọ sí Igangan"
- Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn lọ́balọ́ba, ọlọ́pàá àti Seyi Makinde fẹ́ gbé lórí áàwọ Ibarapa
- Ọkọ̀ akẹ́rù Dangote ya wọ ibùdó ìtajà ní Akungba Akoko, èèyàn mẹ́jọ dèrò ọ̀run
- Ọ̀nà àbáyọ mẹ́wàá rè é fún aláboyún tí kò bá rí oorun ṣùn
- Àwọn ọmọ ìṣọta àti Toyin Abraham jọ wàákò lásìkò tó ń ya sinimá
Igboho ni o ṣeni laanu pe awọn iwa ti aye rẹ o si fawọn ọmọ Yoruba to tẹdo si agbegbe miran lorilẹede Naijiria, ni wọn n fi n lọ Yoruba lori ilẹ won.

Oríṣun àwòrán, @SundayIgboho2
Oloye Igboho ni omilẹgbẹ awọn eekan ọmọ Yoruba lo ti jade laye nipasẹ awọn agbebọn darandaran Fulani, ninu eyi to ti darukọ gbajugba oniṣegun ibilẹ ni, ti ọpọ mọ si ọkọ Oloyun ati Ọmọwe Aborode.
"O ko lee ri ọmọ Yoruba ko lọ maa paniyan ni ipakupa nilu Kano.
Bi ọmọ Yoruba ba gba Hausa/Fulani loju, wọn lee tori rẹ bẹ ẹ lor,i ka to wa sọ pe ko ba nnkan oko jẹ"
O ni ko si nnkan ti ijọba tii ṣe lori gbogbo awọn ti awọn afurasi Fulani darandaran pa nilẹ Yoruba, sibẹ ojojumọ l'ẹmi n ṣofo si.

Oríṣun àwòrán, @SundayIgboho2
Igboho ni gbogbo awọn to n sọ ahesọ ọrọ kiri pe nitori owo, ipo abi gbajumọ loun se gbe igbesẹ naa, ko mọ iru eeyan ti oun jẹ ni.
O fikun pe gẹgẹ bi ọmọ agbegbe Oke Ogun ni ipinlẹ Ọyọ, asiko kan wa sẹyin to jẹ pe ifọkanbalẹ l'awọn eeyan fi n gbe aye wọn lagbegbe naa eleyii ti kori bẹẹ mọ bayii.
"L'awọn igba naa a maa n pada lati oko nibii agogo kan oru laisi ibẹru tabi ikayasoke pe ẹnikan le e kọlu wa."

Oríṣun àwòrán, @SundayIgboho2
O ni nnkan o fara rọ mọ lagbegbe naa nitori gulegule awọn kọlọransi darandaran Fulani kan.
Sunday Igboho wa fi ọwọ gbaya pe idunkooko ileesẹ ọlọpaa ko le da jinni-jinni bo awọn eeyan ipinlẹ Oyo nitori o gba oun ni akoko ati igbaradi ki oun to gbe igbesẹ to lagbara yii, eyi to jẹ ipinnu to bọ sasiko.

Oríṣun àwòrán, @SundayIgboho2
O fikun pe igbesẹ́ naa waye nitori ara wa ati ọjọ ọla iran to n bọ.




















