Igboho vs Fulani: Báyìí ni nǹkan ṣé ń lọ nílé Sunday Igboho lónìí

Sunday Igboho

Lati ile Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho tako iroyin to gba ori ayelujara kan wi pe ileeṣẹ ologun ati awọn Fulani ti yii ile ajafẹtọmọniyan naa ka.

Ko si ohunkohun to jọ bẹẹ lasiko ti akọroyin BBC Yoruba ṣe abẹwo si ile Oloye naa to n bẹ ni agbegbe Soka niluu Ibadan lowurọ ọjọ Ẹti.

Sunday Igboho ati alabaṣiṣẹ pọ rẹ n bẹ nile, bẹẹ si ni ohun gbogbo n lọ bi o ti wa tẹlẹ ri.

Bakan naa ni ọkanojọkan ere idaraya n lọ ninu ọgba ile naa.

Iwadii fi idiẹ mulẹ wi pe Igboho ṣi ni ṣe eto lati rin irinajo lọ si Ibarapa lowurọ oni, ṣugbọn akoko ti yoo gbera ni ko ti i han si ẹnikẹni lasiko ti a ṣe akojọpọ iroyin yii.

Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti rọ awọn eeyan ipinlẹ naa pe ki wọn fọkan balẹ wi pe ko si iyọnu.

Ẹwẹ, Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo na ti sọ fawọn eeyan ipinlẹ naa pe ko si ewu lẹgbẹrun ẹkọ lori ọrọ idunkoko mọ awọn Fulani pe ki wọn kuro lori ilẹ ipinlẹ Oyo lagbegbe Ibarapa.

Wọnyii ni awọn aworan bi gbogbo nkan ṣe n lọ nile Igboho laarọ ọjọ Ẹti to ni oun n lọ si Ibarapa.

Awọn to ta ludo nile Igbohu
Sunday Igboho
Sunday Igboho pẹlu awọn eeyan rẹ
Ero biba nile Sunday Igboho
Awọn to n gba bọọlu tẹniisi nile Igboho