Coronavirus in Nigeria: Buhari buwọ́lu bílíọ̀nù N6.45b láti dá ibùdó afẹ́fẹ́ gáàsì sílẹ̀ fún ìtójú àwọn alárùn covid-19

Oríṣun àwòrán, Instagram/bashir ahmad
Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu owo to le ni biliọnu mẹfa naira N6.45bn fun ibudo idasilẹ afẹfẹ gaasi fun itọju awọn to larun coronavirus lorilẹede Naijiria.
Ibudo mejidinlogoji kaakiri Naijiria ni awọn ibudo naa yoo wa.
Ṣaaju akoko yii ni ajọ amuṣẹya PTF ti sọ lọjọ karun un oṣu kinni pe ijọba apapọ yoo da ibudo gaasi silẹ kaakiri gbogbo ipinlẹ mẹrindinlọgbọn ni Naijiria.
- Èèyàn 1, 964 tún lùgbàdì covid 19 lánàá, ìpínlẹ̀ Eko kó 824 nínú wọn!
- Àwọn Ọba ló rànṣẹ́ pè mi pé ìyá ìjínigbé àti ìpànìyàn yì tó gẹ́- Sunday Igboho
- Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho
- Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu
- Ẹgbẹ́ Afenifere bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu Aárẹ Buhari lórí gbèńdéke tí Akeredolu fún àwọn darandaran Fulani
- Covid-19 ti ṣekúpa èèyàn 1,478 báyìí ní Nàìjíríà, 92,336 ti jàjàbọ́
Ninu atẹjade kan ti ijọba fi sita l'Ọjọbọ, ijọba ya $671,000 sọtọ fu atunṣe awọn ibudo afẹfẹ gaasi lawọn ile iwosan kan ni Naijiria.
Ijọba ko sọ gbedeke nigba ti awọn ibudo gaasi naa yoo pari.
Minisita eto iṣuna, Zainab Ahmed sọ fun igbimọ NEC to n ri si eto ọrọ-aje pe igbesẹ ijọba naa ṣe pataki fun itọju awọn ọmọ Naijiria ti ọwọja ẹlẹẹkeji covid-19 n ba finra.
Ẹwẹ, eeyan 1964 lo lugbadi coronavirus l'Ọjọbọ ni Naijiria eyi to tii pọ julọ lọjọ kan ṣoṣo.
Ko si ẹni to le sọ pato iye awọn alarun coronavirus to nilo afẹfẹ eemi kaakiri ile iwosan ni Naijiria.
Amọ, ijọba sọ pe ki ọrọ naa pe ninu irora ni ọpọ eeyan to larun coronavirus wa.
- Lere Paimo ṣàlàyé bí fíìmù "Ogbori Elémosho" ṣe sọ ọ̀ di Olóyè MFR pẹ̀lú Dangote àti Adenuga
- "Adájọ́, ẹ má tú wa ká, mo sì nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi bó tilẹ̀ jẹ́ pé alágbèrè pásítọ̀ ni"
- ''Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo kò bẹ̀rù idúnkokò mọ́ni iléeṣẹ́ ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ àwọn Fulani darandaran''
- Ẹ̀yin èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo, mìmì kan kò lè mì yín lónìí- Makinde













