Lere Paimo: Eda Onile-ola ṣàlàyé bí fíìmù "Ogbori Elemosho" ṣe sọ ọ́ di ìlúmọ̀ọ́ká

Lere Paimo

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nollywood Circle

Awọn agba bọ, wọn ni ori lo mọ iṣẹ aṣela. Ohun lo difa fun agbaọjẹ oṣere tiata Yoruba, Oloye Lere Paimo ti iṣẹ to yan laayo sọ ọ di ilumọọka.

Nigba to b'awọn akọroyin sọrọ laipẹ yii, gbajugbaja oṣere naa ti inagijẹ rẹ n jẹ Eda Onile-ola ṣalaye bi fiimu itan Ogbori Elemosho ṣe ṣọ ọ di olokiki ninu ere tiata.

Ninu esi rẹ si ọrọ t'awọn oṣere kan ṣọ pe awọn kii ṣaaba fẹ ṣe fiimu to da lori itan ilẹ Yoruba nitori kii lowo lori bi awọn fiimu agbelewo to wọpọ lasiko yii, Oloye Paimo ni irọ nla ni.

Eda Onile-ola ṣọ pe fiimu Ogbori Elemosho ti oun ṣe ta, ati pe fiimu yii lo mu ki ijọba apapọ foun loye MFR pẹlu awọn ilumọọka ọlọrọ bíi Aliko Dangote ati Mike Adenuga niluu Abuja.

"Koda ajọ awọn akọṣẹ-mọṣẹ olokowo, Chartered Institute of Commerce ṣẹṣẹ fi oye Ọmọwe da mi lọla ni, nibayii, orukọ mi ti di Oloye Ọmọwe Lere Paimo," Eda Onile-ola ṣalaye.

O ni lati inu fiimu itan ilẹ Yoruba loun ti ri awọn oye yii gba, nibẹ naa loun tun ti ra ọkọ oriṣiiriṣii

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Eda Onile-ola ni nibi iṣẹ tiata yii naa ni oun ti ran awọn ọmọ lọ sile iwe. "Ẹ sọ fun mi kinni eeyan tun n wa laye?"

Agbaọjẹ oṣere yii bu ẹnu atẹ lu bi awọn oṣere asiko yii kii ti fẹ gbe ere jade lori itan ilẹ Yoruba.

O ni ọpọ awọn oṣere yii kii le ronu jinlẹ lati kọ iru itan bẹẹ ni.

Àkọlé fídíò, US Vice President:Ẹ wo ìtàn obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ igbákejì Ààrẹ ilẹ́ Amẹrika?

Eda Onile-ola ni oun atawon akẹgbẹ oun ṣe iwadii lọdọ awọn agbaagba ilẹ Yoruba ki awọn to gbe ere bi Ogbori Elemosho ati Saworo Ide jade.

"Ṣugbọn iwa ainirẹlẹ ko le jẹ k'awọn ọmọ iṣẹyii to n ṣere tiata lọ b'awọn agbaagba fun iwadii lori ere," Oloye Paimo lo sọ bẹẹ.

Eda Onile-ola fikun ọrọ rẹ pe oun at'awọn akẹgbẹ oun ko yaju s'awọn ọga awọn, bẹẹ ni awọn si bọwọ fawọn to ju awọn lọ lọjọ ori.

"Mo fẹ da ileewe ikẹkọọ ere tiata silẹ nibi ti mo ti maa kọ̀ awọn ọdọ nipa ere ṣiṣe, itan kikọ ati ijo jijo ninu ere," Eda Onile-ola lo ṣalaye bẹẹ.

O ni iru awọn ere toun fẹ maa kọ awọn ọdọ gbọdọ kọ awọn eeyan lẹkọọ.

Àkọlé fídíò, America Inauguration Joe: Wo àwọn eré orí ìtàgé tí Donald Trump ṣe kó tó fi ipò aàrẹ sílẹ̀

Lere Paimo ni ohun to fi dabi ẹni pe awọn eeyan ko ṣaaba ri oun ninu ere mọ ni pe awọn olootu ere ni ko ṣaaba pe oun atawon akẹgbẹ oun sí ere mọ.

Eda Onile-ola ṣọ pe iwa ti ko boju mu ni ki wọn maa kun atike soju ọdọ lati ṣe bi arugbo ninu ere nigba t'awọn agba oṣere wa nilẹ.

Gbajugbaja osere yii tun koro oju si bi ọpọ oṣere ti n bo ara, ṣi ara wọn silẹ ti wọn si n lo awọn ede ti ko dun un gbọ leti ninu ere.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí

O ni iru awọn iwa bayii ko ba aṣa Yoruba mu, ati pe oun at'awọn akẹgbẹ oun ko dan iru rẹ wo nigba t'awọn bẹrẹ ere tiata.

Oloye Paimo ni awọn kilọ ni aimọye igba fawọn oṣere to n huwa bayii, amọ ọpọ ninu wọn lo kọ eti ikun.

Ninu awọn ti Eledumare fi ẹbun ijo jijo jinki, ọkan ni Eda Onile-ola jẹ.

Àkọlé fídíò, BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020

Oloye Paimo ni Eduwa fi ijo jijo rọ oun debi pe ko si akẹgbẹ oun kan to le jo bi oun ṣe n jo.

"Ijo ti mo n jo lo mu ki awọn kan gbe mi lọ si orilẹ-ede Amẹrika lọdun 2017 fun ayẹyẹ ọjọ ibi mi," Eda Onile-ola lo wi bẹẹ.

O ni ọpọ lo yanu nigba ti oun f'ẹsẹ rajo ti wọn si sọ pe oun n jo bi gbajugbaja olorin Juju, King Sunny Ade.