Beer Belly: Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa ikun rẹ tó ń to tobi

Njẹ o jẹ eeyan to maa n mu ọti bia (Beer), abi o mọ ọti bia funra rẹ?
To ba ri bẹẹ, iroyin yii kan ọ.
Aye ijọhun ni wọn maa n ri ọjọ ori gẹgẹ bii ami fun ọrọ ti ẹda ni, ti ọpọ si maa n fi ikun titobi yangan ni awujọ.
Sugbọn bayii, inu fẹ́lẹ́ ti ti ebi kọ ni awọn eeyan n fẹ ninu eyi ti ọpọ ọkunrin si maa n gba ibudo ere idaraya lọ lati mọ bi wọn se ri, ki wọn si din ọra ikun wọn ku.
Awọn ọpọ ọdun ta maa n ri awọn baba ati arakunrin wa ti wọn maa n gbe bia kiri ti waye sẹyin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ki lo de ti awọn ọkunrin se maa n ni 'ọdun bia'?
Bia ta n gbe kiri yii, ni awọn oloyinbo ni pe o ni ohun ti a n pe ni 'Calorie' eyi to n mu ki eeyan sanra, ti ohun mimu naa si wuwo ninu ara.
Nitoripe awọn ọkunrin kan maa n mu ju igo ọti kan lọ nibudo imuti kan, ti wọn ko si ni lero lati se ere idaraya lẹyin mimu ọti yii naa maa n fi kun 'Calorie'ara ni.
Sugbọn laarin awọn obinrin, wahala yii maa n tọ ara wọn ja ni, ti yoo si wọ wọn de ori ẹsẹ wọn.
A si lee pe akoko ti bia lee ba ara mu ni igba ewe si ọdun marundinlogoji, lati akoko yii lọ, isọwọ sisẹ eroja to n mu ki ounjẹ tete da ninu ara, ko ni sisẹ bo se yẹ mọ.
Nigba ti ounjẹ ko ba si da bo se ni kiakia gẹgẹ bo se maa n se tẹlẹ lasiko ti eeyan wa ni ọdọ, itumọ eyi ni pe onitọhun ko sisẹ asekara to yẹ, ti yoo si maa ba ikun rẹ ja.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Se bia nikan lo n jẹ ki ikun yọ sita?
Ọti bia nikan kọ lo n sokunfa bi ikun se n tobi, amọ eroja ọra kan ti wọn pe ni 'Visceral' lo n sokunfa ikun to tobi.
Bakan naa, awọn eeyan to ni aisan atọgbẹ tabi itọ suga, aisan ọkan atawọn oniruuru aisan miran to maa n sediwọ fun eroja insulin lati sisẹ ninu ara, naa maa n fa ki ikun tobi.
- Gbọingbọin lọmọ Nàìjíríà wà lẹ́yìn iléẹjọ́ gíga jùlọ lórí ìdájọ́ ìbò Bayelsa- Atiku
- Àwọn ọmọ onílẹ̀ lọ ṣe àmúṣẹ àṣẹ iléẹjọ́ ní Soka, làwọn ‘Jàǹdùkú’ fi dá wọn lọ̀nà - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ọyọ
- Bàbá àti ìyá mi kò fẹ́ kí n ṣe eré tíátà - Wale Akorede Okunnu
- Ẹ̀yin òṣèrè tíátà, ẹ ní ṣùúrù de àsìkò Ọlọ́run, ẹ máṣe kánjú kọjá kádàrá - Madam Ṣajẹ
Awọn dokita ati onimọ nipa ounjẹ asaraloore ni ọra ikun naa lee maa pọ si to ba se ayipada awọn eroja ounjẹ to n jẹ, paapa apọju awọn ounjẹ to ni eroja suga atawọn ounjẹ afun ara lagbara.
Kini ọna abayọ?
Ọna abayọ to wa fun ọ, to ba ni ikun to tobi ni pe ko se adinku suga ati ounjẹ afara lagbara to n jẹ, taa mọ si Carbonhydrate, jẹ ounjẹ niwọn tun wọnsi, ko si maa sinmi.
- Ó ṣeéṣe kó má sí ẹ̀ṣọ́ aláàbò Amotekun l‘Eko - Ìjọba Eko
- Ẹgbẹ́ alátakò ló sanwó fáwọn èèyàn kan láti pariwo lé ààrẹ Buhari lori - Iléeṣẹ́ ààrẹ
- Arisekola ló fún mi ní ilẹ̀ tí ìjọba Ọyọ gbẹ́sẹ̀ lé, ń kò ní gbà - Ajimobi
- Ta ni wọn yóò búra fún bíi gómínà Bayelsa lónìí, olùdíje PDP ni àbí olórí ilé aṣòfin?
- Ẹ̀ṣọ́ Amotekun ní láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ọlọ́pàá agbègbè- Ọ̀gá ọlọ́pàá Naijiria


















