Madam Saje: Lónìí ọjọ́ ìbí mi, mo bẹ Ọlọ́run kí ń má jajé ọmọ mi m‘áyé
Ọjọ Kẹtala Osu Keji ọdun ni ọjọ ibi Alhaja Fausat Balogun, ti gbogbo eeyan mọ si Madam Sajẹ ninu ere tiata.
Lọdun 2020 yii si lo pe ọdun mọkanlelọgọta loke eepẹ, to si n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun idasi ẹmi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ san ₦200,000 fún Sowore lórí bí ẹ ṣe ń fi ẹjọ́ falẹ̀ - Iléẹjọ́ pàṣẹ fún ìjọba
- Ìdí tí àwọn ọmọ Nàíjíríà ṣe ń pariwo lé Buhari lórí lójú ayé àti lórí ayélujára
- Ẹ̀yin ọba alayé, ẹ mà ń dákẹ́ pọ̀ lórí ààbò tó mẹ́hẹ ní Nàíjíríà - Sultan figbe ta
- Láì lọ́wọ́ ẹ̀yin aráàlú nínú, yóò nira fún Boko Haram láti ṣọṣẹ́ - Buhari sọ fáwọn èèyàn Borno
- Sunday Igboho gba àwọn èèyàn Soka n‘Ibadan sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ tó wá ṣọṣẹ́
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Madam Sajẹ rọ awọn akẹẹgbẹ rẹ ti wọn jẹ osere ori itage lati mase kanju kọja kadara nitori ibukun Oluwa nii mu ni la, laifi laala kun.
Bakan naa lo bẹ Ọlọrun pe ko si bi oun ti se dagba tabi lokiki to, oun ko fẹ jẹ aye ọmọ oun maye.









