Insecurity: Ọọ̀ni ni báwọn ọba alayé ṣe lọ́wọ́ nínú àgbékalẹ̀ Amotekun, ni yóò ṣe tọ́jọ́

Ọọni Adeyeye Ogunwusi ati Sultan ti Sokoto

Oríṣun àwòrán, From The Palace of Ooni of Ife

Yoruba ni agba kii wa lọja kori ọmọ tuntun wọ, bẹẹ si ni agba ti ko ba kẹhun sọrọ, afaimọ ko ma kẹtan sare.

Boya eyi lo mu ki Sultan ilu Sokoto, Alhaji Sa'ad Abubakar Kẹta fi n lọgun too fun awọn ọba alaye pe wọn ti n dakẹ pupọ ju lai sọrọ lori eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria, tori bi ara ile ẹni ba n jẹ kokoro buruku, ti a ko ba wi fun, hẹrẹhuru rẹ ko ni jẹ ka sun loru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sultan parọwa yii nilu Osogbo lọjọbọ lasiko to n sọrọnibi ipade apero lori eto aabo ati aifararọ ni Naijiria eyi ti ibudo kan to wa fun agbelarugẹ asa ilẹ adulawọ seto.

Ọọni Adeyeye Ogunwusi ati Sultan ti Sokoto

Oríṣun àwòrán, From The Palace of Ooni of Ife

Sultan, ẹni to n fi ika gun awọn ọlaju lawujọ nimu pe se ni wọn n lo awọn mẹkunnu ti ko ni nkankan lati gba ohun ti wọn n fẹ, tun rawọ ẹbẹ sawọn ọba alaye pe ki wọn maa pariwo sita nipa isoro to n koju orilẹede yii, wọn sa ni igi gogogro ma gun mi loju, ati okeere laa tii lọọ.

Bakan naa, ni ọba alaye ọhun ẹni to tun gbarata lori ebu ẹyin to n ba ipese awọn ohun eelo amayedẹrun lorilẹede yii, wa ran awọn ọba alaye leti pe lati ọdun gbọọrọ wa ni wsn ti n se akoso awujọ wọn, ki ijọba to gba wọn sẹyin lọdun 1914, ti isopọ waye ni Naijiria.

Ọọni Adeyeye Ogunwusi ati Sultan ti Sokoto

Oríṣun àwòrán, From The Palace of Ooni of Ife

"A ko lee ni alaafia ati eto aabo to peye nigba ti a ko ni isejọba rere ati idajọ ododo. Ohun ti awọn baba nla wa se ree, a si gbọdọ dide si ipenija yii, nitori nkan ko sẹnu re rara ni, Tẹ ba si dakẹ, ti ẹ ko dide lati seranwọ fun awọn oloselu lori isẹlẹ yii, a jẹ pe awa gangan jẹ ara isoro naa."

Sultan tun gba awọn ọba alaye nimọran lati maa sọ otitọ lai bẹru pe gomina abi awọn alaga ijọba ibilẹ yoo dunkoko mọ wọn. O ni to ba da yin loju, ẹ sọ ọrọ sita, kẹ si duro lori rẹ.

Àkọlé fídíò, World Radio Day: Àwọn òṣìṣẹ́ rédíò ní àwọn ń pa ìsòro àwọn mọ́ra ni láti mú inú aráàlú dùn

Nigba to n sọrọ, Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Ẹnitan Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja Keji ni nitori pe awọn ọba alaye lọwọ si eto aabo Amotekun, ni yoo se fidi mulẹ, to si rọ ijọba lati maa jẹ kawọn ọba alaye lọwọ ninu agbekalẹ eto aabo lagbegbe wọn.