Amotekun: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo, Ogun, Ondo ní ìyókù kù sí ọwọ́ asòfin ìpínlẹ̀

Awọn gomina ẹkun Yoruba n sepade pẹlu Igbakeji Aarẹ lori Amotekun

Oríṣun àwòrán, Tolu ogunlesi

Ijọba ipinlẹ Oyo, Ondo ati Ogun ti buwọlu abadofin ọdun 2020 to gbe ikọ amọtẹkun kalẹ ni ipinlẹ naa.

Nibi ipade ajọ amuṣẹya ni awọn ipinlẹ naa ni wọn ti buwọlu abdofin naa, ti yoo wa lo si ile igbimo asofin ibilẹ nibi ti wọn yoo ti jiroro lori rẹ.

Ipade naa to waye ni ilu Ibadan ni wọn ti jiroro lori ohun ti abadofin naa da le lori ati ohun ti wọn gba laaye fun ikọ naa.

Àkọlé fídíò, Kí lo tíì rí nípa Amotekun? Ẹ sùnmọ́bí, ẹ wo gbankọgbì!

Kọmisọnna fun eto idajọ ati agbẹjọro agba ni ipinlẹ naa sọ wi pe gomina ipinlẹ ogun sa ipa rẹ lati mu ki eto naa gberu si.

O ni awọn fi aaye gbawọn lati da duro,bakan naa ni awọn fayegba ibaṣepo to dan mọran laarin ẹka naa ati ẹka eleto aabo to ku ni ipinlẹ mẹfa ni iwọ oorun Naijiria.

Awọn gomina ilẹ Yoruba

Oríṣun àwòrán, Facebook/SEyi Makinde

Kọmisọnna fun eto idajọ ati olootu naa sọ wi pe o da awọn loju pe awọn asofin yoo ri daju pe abadofin naa kẹsẹjari, ki gomina naa le fowosi laipẹ.

Ni ipinlẹ Ogun, awọn igbimọ amuṣẹya naa gbe abadofin naa kalẹ lati le wa ọna abayọ so eto aabo to mẹhẹ,ti awọn igbimọ amuṣẹya naa si pa ohun pọ fẹnu ire pe e.

Buhari atawọn eekan ilẹ oruba meji, Gomina Fayẹmi ati Ọjọgbọn Osinbajo

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Bakan naa ni awọn igbimọ amuṣẹya naa ni ibaṣepọ to danmọran ti wa laarin awọn olootu ijọba mẹfa naa, ti wọn si jọ panupọ lori isoro naa.

Osu Kini, ọdun 2020 ni ipinlẹ mẹfa ni ẹkun iwọ orun Naijiria fowosowọpo lati da eto aabo awarawa silẹ , amọ wọn nilo ofin lati gbe duro daadaa.

Na òṣìṣẹ́ Amotekun, ko san ₦250,000 owó ìjìyà, ko sì tún fi ẹ̀wọ̀n oṣù kan jura

Ìkede ti jáde pe ẹnikẹni to ba na tabi kọju ija si osisẹ ikọ Àmọ̀tẹ́kùn lẹ́nu iṣẹ́, yóò fi ẹ̀wọ̀n osù kan jura àti ko san ẹgbẹ̀rún lọna igba naira ati abọ.

Bakan náà, wọ́n ko le fi òfin de ọmọṣẹ Amotẹkun fún òhun kohun to ba ṣe lásìkò tó ba wà lẹ́nu iṣẹ́.

Ikọ Amọtẹkun
Àkọlé àwòrán, Àṣegbé ni ohunkóhun tí òṣìṣẹ́ aláàbò náà bá ṣe lẹ́nu iṣẹ́

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eyi ni ni ọkàn lára ẹsẹ ofin to wà ninu àbádofin to de isọwọ sisẹ ikọ Amotekun nipinlẹ Ekiti, (Ekiti State Security Agency Bill) ti ọdun 2020, èyi to ti wà niwaju ile igbimọ aṣòfin bayii.

Ọkọ ikọ Amọtẹkun

Oríṣun àwòrán, @DAWNCommission

Gẹ́gẹ́ bi abala kẹrindinlogoji abadofin náà ṣe sọ, "ẹnikẹni to ba gbiyanju lati di Amọtẹkun lọ́wọ́ láti ṣe ojuṣe wọ́n, lù u tàbi pa a lára lọnà àitọ lẹ́nu iṣẹ́, ti ṣẹ lábẹ́ òfin, yóò si fi ẹwọ̀n àti ẹgbẹrun lọ́na igba àti ààbọ̀ naira jura.

Amọtẹkun

Oríṣun àwòrán, facebook/Amotekun

Àkọlé àwòrán, Ọjọ kẹsan an Oṣu Kinni ọdun yii ni awọn gomina ipinlẹ mẹfa lati ilẹ Yoruba ṣe ifilọlẹ ikọ Amọtẹkun nilu Ibadan

Awọn Gomina ìhà Guusu-Iwọ-òòrun to ku náà ti fi abádòfin wọ́n, siwáju ilé ìgbàmọ àsòfin ìpínlẹ̀ koowa wọ́n.

Bakan náà ni òfin tun sọ pé, olori ilé iṣẹ́ Amotẹkun gbọdọ jẹ́ oṣìṣẹ́ fẹ̀yìnti lẹ́nu iṣẹ́ ologun tabi agbofinro.

Àkọlé fídíò, Osogbo Photographer:

O gbọdọ ni ìmọ iṣẹ náà, o kere tan ọdun mẹwàá, ti abadofin náà si kan kọmisona ọlọpàá ipinlẹ náà àti adele ilé iṣẹ́ ọmọogun.

Abadofin náà tun fààye gba ìdásílẹ̀ àjọ Amọtẹkun, ti ko si gbọdun din ni sáà ọdun mẹrin.