Somali child rapists: Wọ́n yìnbọn pa àwọn afipabánilòpọ̀ ní gbangba ní Somalia

Aisah llyas

Oríṣun àwòrán, Radio banaadir

Àkọlé àwòrán, Iku Aisha fa awuye-wuye ati ifẹhonu han kaakiri orilẹ-ede Somalia l'ọdun 2019.

Ọkunrin meji ti di eero ọrun lẹyin ti wọn yinbọn pa wọn fun pe wọn fi ipa ba ọmọ ọdun mejila kan lopọ, wọn si tun pa a.

Aisha llyas Aden ti wọn ji gbe, ni wọn fi ipa balopọ, ti wọn si tun pa a nitosi ile awọn obi rẹ nilu Galkayo, ni ẹkun Puntland, l'orilẹ-ede Somalia, l'oṣu Keji, ọdun 2020.

Iṣẹlẹ naa fa awuye-wuye ati ifẹhonu han kaakiri orilẹ-ede naa.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti ti kéde oṣù mẹ́fà fún àwọn obìnrin tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba láti maa fi sinmi lẹ́yìn ìbímọ.

Awọn afurasi mẹwa ni ọwọ kọkọ tẹ, ṣugbọn ile ẹjọ agbegbe naa ri i pe awọn mẹta pere lo jẹbi l'oṣu Karun un.

Fun igba akọkọ, awọn amofin to gbọ ẹsun wọn ṣe amulo sei ayẹwo DNA lati we dajọ wọn.

Abdifatah Abdirahman Warsame ati Abdishakur Mohamed Dige bẹ baba ọmọ naa fun idariji.

Oríṣun àwòrán, Sbc

Àkọlé àwòrán, Abdifatah Abdirahman Warsame ati Abdishakur Mohamed Dige bẹ baba ọmọ naa fun idariji.

Meji lara awọn ti wọn sọ pe o jẹbi Abdifatah Abdirahman Warsame ati Abdishakur Mohamed Dige, ni wọn yinbọn pa ni ita gbangba nilu Bossasso ni owurọ ọjọ Iṣẹgun.

Botilẹjẹ pe ile ẹjọ dajọ iku fun ọkunrin kẹta, Abdisalam Abdirahman Warsame, to jẹ arakunrin Abdifatah, wọn yọnda oun.

Baba Aisha, llyas Aden sọ fun awọn akọroyin pe oun sọ fun ile ẹjọ pe ki wọn o ṣun ọjọ ti wọn yoo pa siwaju fun ọjọ mẹwaa titi wọn yoo fi tun ẹjọ rẹ yẹwo.

Bakan naa lo sọ fun akọroyin BBC kan lori ẹrọ ibaraẹni sọrọ pe oun ba awọn ọdaran naa sọrọ ki wọn o to pa wọn, ti wọn si sọ pe lootọ ni ṣẹ ẹṣẹ naa, wọn si tun tọrọ aforiji.

llyas sọ pe oun yẹ wọn wo lẹyin ti wọn yinbọn fun wọn ki oun le mọ boya wọn ti ku.

Oríṣun àwòrán, Sbc

Àkọlé àwòrán, llyas sọ pe oun yẹ wọn wo lẹyin ti wọn yinbọn fun wọn ki oun le mọ boya wọn ti ku.

Oun paapa lo darukọ awọn to fẹ ko yinbọn pa wọn.

Ọgbẹni Aden sọ pe "pipa ti wọn pa wọn yoo jẹ ẹkọ nla, ati pe aabo yoo wa fun awọn ọmọdebinrin Somali".