Auno Attack: Àwọn jàndùkú dáná sun arìnrìnàjò 30 lásìkò tí wọ́n sùn sìnú ọkọ̀ wọ́n

Oríṣun àwòrán, Borno state governor/facebook
Awọn afurasi alakatakiti agbebọn ti ṣekupa awọn eniyan ti ko din ni ọgbọn, ti wọn si tun ji awọn obinrin ati ọmọde gbe ni ipinlẹ Borno.
Ọpọlọpọ awọn eniyan naa ni wọn dana sun loju orun lasiko ti ọkọ to n gbe wọn lọ si irinajo duro lati sinmi.
Ikọlu naa waye ni ilu Auno, to jẹ opopona nla kan nipinlẹ Borno.
Agbẹnusọ fun ijọba ipinlẹ Borno, Ahmad Abdurrahman Bundi sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe ọkọ akẹru lo gbe awọn janduku naa wa pẹlu awọn nkan ijagun nlanla, ki wọn o to pa awọn eniyan naa, dana sun wọn, ti wọn si tun ja wọn l'ole.
- Ohun tí a mọ̀ nípa ààrùn tó ń pani ní Nàìjíríà tí kìí ṣe CoronaVirus, Lassa, tàbí Ebola rèé
- Èèyàn mẹ́fá tó n bọ̀ láti ìpàgọ́ àdúrà kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú pópó l'Osun
- Àrà kengé! Ọmọ China to ẹgbá sí ìdí ọmọ'ṣẹ́ rẹ tó pẹ́ ẹ́ dé ibi'ṣẹ́
- BBC tún gbé e dé! Wọ́n tú àṣírí ìfiyàjẹni àwọn Ológun àti SARS káàkiri Nàìjíríà
Bakan naa lo sọ pe awọn oniṣẹẹbi naa tun ba ọkọ mejidinlogun jẹ. O sọ pe lootọ ni wọn ji awọn obinrin ati ọmọde gbe, ṣugbọn ko sọ iye wọn.
Awọn olugbe agbegbe ti isẹlẹ naa ti waye sọ pe awọn eniyan naa n rinrinajo lọ si ilu Maiduguri.

Oríṣun àwòrán, Facebook/govborno
Ṣugbọn wọn ni lati sun si ilu Auno ti ko ju kilomita mẹẹdọgbọn lọ sibẹ, nitori pe awọn ọmọ ogun ti ti oju ọna to lọ si Maiduguri.
Gomina ipinlẹ Borno,Babagana Umara Zulum naa ṣe abẹwo sibi iṣẹlẹ naa lati ba awọn eeyan ibẹ kẹdun.
Ileeṣẹ ologun Naijiria ko ti sọrọ l'ori ikọlu naa.
Ko si ti i fojuhan boya ikọ Boko Haram lo ṣe ikọlu naa tabi ikọ alakatakiti miran.












