Lassa Fever: Àjèjì ààrùn tó ń pani ní Nàìjíríà bàyìí kìí ṣe CoronaVirus, Lassa, tàbí Ebola

Onimọ ayẹwo iṣegun oyinbo

Oríṣun àwòrán, Ncdc

Ajọ to n mojuto igbogun ti aarun ni Naijiria, Nigeria Centre for Disease Control (NCDC) sọ pe ohun ti mu erooja lara omi odo ti aisan ajeji kan ti pa awọn eniyan ti ko din ni mẹẹdogun ni ipinlẹ Benue.

Ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Benue sọ pe awọn ti aarun naa fi ọwọ ba julọ n gbe ni ijọba ibilẹ Oye-Obi nipinlẹ naa.

Iku eniyan mẹẹdogun lo ti wa ni akọsilẹ bayii, ti ọgọrun ati mẹrin eniyan si tun ti kagbako aarun naa to bujade lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2020.

Nkan to ba ni lẹru ni pe ajeji aarun naa tete n ran kiri ju iba Lassa to ti pa eniyan mẹtadinlaadọta lọdun 2020 nikan lọ.

Ni bayii, awọn alaṣẹ ipinlẹ Benue ti di ọna to lọ si odo naa pa.

Bakan naa ni ajọ NCDC ti sọ pe aarun naa kii ṣe Corona virus, iba Lassa tabi Ebola, nitori pe awọn apẹẹrẹ ti awọn to ni i fihan yatọ.

Awọn onimọ ilera sọ pe o maa n to wakati mejidinlaadọta ki esi ayẹwo to jade.

Minisita fun eto ilera ni Naijiria, Dokita Osagie Ehanire sọ pe awọn onimọ ti n wadii iru aarun to jẹ, ti wọn si n duro de e esi ayẹwo.

Minisita fun eto ilera ni Naijiria, Dokita Osagie Ehanire

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@FMOHNIGERIA

Àkọlé àwòrán, Minisita fun eto ilera ni Naijiria, Dokita Osagie Ehanire

Minisita fun eto ilera sọ fun awọn akọroyin l'ọjọ Ẹti to kọja pe awọn koko to ti farahan nipa ajeji aarun naa ni pe:

  • Aarun naa ti pa eniyan ti ko din ni mẹẹdogun, awọn to le ni ọgọrun lo si ni i.
  • Aarun naa maa n mu ki inu ati ẹsẹ ẹni to ba ni ko wu gbẹndu
  • Ijọba n fura pe o ṣeeṣe ko jẹ kẹmika ti wọn fi n pa ẹja lo n fa aarun naa
  • Ajọ NCDC ti ran ikọ adoola si ipinlẹ Benue lati mu eroja fun ayẹwo lara omi odo naa