'Lassa Fever' kọ́ ni ààrùn tó padà wá, mọ̀ nípa ààrùn yìí tó ti pa èèyàn 15 ní Benue

Mínísítà ètò ìlera ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@FMOHNIGERIA

Mínísítà fún ètò ìlera ní Nàìjíríà, Dokita Osagie Ehanire ti kede pe awọn akọṣẹmọṣẹ[ti koju bọ ọrọ arun ajoji kan to dede ṣẹ yọ ni ipinlẹ Benue.

O ni abọ to jade wa lati ibudo ayẹwo ti wọn mu u lọ fihan pe kii ṣe arun iba Lassa ṣugbọn pe awọn ṣi n duro de esi.

Titi di akoko yii, Naijiria ko tii ko firi aarun to n ja rain-rain ni orilẹede china, Coronavirus, ṣugbọn ki la wa mọ nipa arun tuntun yii?

Àkọlé fídíò, Làáhànmí: Ìwádìí ní èèyàn 219 ni ibà Lassa pa lọ́dún tó lọ́, 29 lọ́dún yìí, tètè dènà rẹ̀

Mínísítà fún ètò ìlera ní Nàìjíríà, Dokita Osagie Ehanire ba awọn oniroyin sọrọ wi pe aarun ọhun ti pa eniyan to to mẹdogun bẹẹ si ni o le ni awọn ọgọrun to ti ko o.

Ṣe ni arun yii maa n mu ki iku ati ẹsẹ eeyan wu

Ẹwẹ, ijọba Naijiria ni awọn n fura pe boya awọn kẹmika ti wọn fi n pa ẹja lo n fa arun yii.

Ibudo to n ri si didojukọ aisan ni Naijiria (NCDC) ti ran ikọ oniṣẹ pajawiri lọ si ipinlẹ Benue kanm kanm lati lọ bu wa lara omi ọhun.

Minisita eto ilera ni kii ṣe iba Lassa ṣugbọn awn ko ri nkan to jọ mọ Coronavirus bayii ayafi igba ti esi ba to jade.

Gẹgẹ bo ṣe wa bayii, iba Lassa ti n ba orilẹede Naijiria finra to si ti pa to eniyan mẹtadinlaadọta lọdun 2020 yii nikan bẹẹ si ni o ti ṣakoba fun awọn eeyan ipinlẹ mẹtalelogun gẹgẹ bi ibudo NCDC ṣe sọ ọ.