Tí mo bá rí obìnrin tó kò níṣẹ́ lápá, mó máa ń ní kí wọ́n wò mí ṣe àríkọ́gbọ́n

Àkọlé fídíò, Ẹ wo obìnrin "Bricklayer" tó sì ń bọ́ ẹnu èèyàn mẹ́ẹ̀dógún

Jane Ifeoma ni orukọ rẹ n jẹ, obinrin bi ọkunrin tabi ka tilẹ ni obinrin to ju ọkunrin lọ ni.

Iṣẹ ọwọ rẹ to yan laayo ko doju ti i rara. Ko da o ni ohun ti oun n lo lati fi fun eeyan mẹẹdogun lounjẹ ninu ile oun niyii.

Iṣẹ birikila lo wayan laayo to si maa n yaa lor lati wa iṣẹ lọ ibikibi ti wọn ba ti n kọle.

"Ti wọ́n ba sọ fun mi pe kii ṣe iṣẹ obinrin, mo maa n sọ fun wọn pe ko ni ohunkohun ṣe pẹlu pe mo jẹ obinrin".

Ọp ajalu lo ṣẹlẹ si i. "Ọmọ méje ni mo bí ṣùgbọ́n gbogbo wọ́n ti ṣaláìsí".

O mọkan o si gba ọkọ rẹ nimọran fun itẹsiwaju idile wọn.

Ninu owo to n ri lo ti bẹrẹ ile ara rẹ diẹ diẹ titi ti oun fi di onile ara rẹ.