Àlàyé lórí òfin tuntun tí UK gbé kalẹ̀ lórí àwọn tó ń fi ọkọ̀ ojú omi káwọn àjèjì wọlé

Awọn ẹṣọ atawọn eeyan yika ọkọ oju omi nla

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba UK ti ṣe agbekalẹ ofin kan to fawọn ẹṣọ aṣọbode atawọn ẹṣọ eleto aabo lagbara lati maa gba foonu awọn to wọ ọkọ oju omi wọ orilẹede naa lọna aitọ.

Bi ofin yii yoo ṣe maa ṣisẹ ni pe ijọba fẹ mọ aṣiri awọn to n fi ọkọ oju omi kawọn eeyan wọ UK lori awọn foonu ti wọn ba gba.

Awọn ẹṣọ aṣọbode yoo maa gba foonu awọn to n lo ọkọ oju omi lati japa lọ si UK ni toootọ, amọ, eyi ko tumọ si pe wọn maa fọwọ ofin mawọn eeyan naa.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ilẹ okeere ṣe ṣalaye, awọn oṣiṣẹ aṣọbode laṣẹ bayii lati sọ fawọn to wọ ọkọ oju omi wa si UK lọna aitọ lati bọ aṣọ wọn ki awọn ẹṣọ eleto aabo le wa foonu wọn ati SIM kaadi wọn.

Ajọ NCA to n gbogun ti iwa ọdaran ni UK sọ pe ijọba le lo abọ iwadii yii lati ṣeranwọ fun iwadii lori fifi eeyan ṣe kata-kara.

Minisita to n ri si ọrọ ibode ni UK, Alex Norris, ṣalaye pe ''a n ṣeleri lati maa ṣe idari awọn ibode wa nipa gbigbogun ti awọn to n fi ọkọ oju omi ko awọn ajeji wọ UK.

Idi niyi ti a fi n lo ofin tuntun yii lati ba iṣẹ awọn eeyan to n lo ọkọ oju omi lati kawọn ajeji wọ UK lati ilẹ okeere jẹ.''

''Eeyan ti ko din ni 41,472 ni wọn lo ọkọ oju omi wọle si UK lọdun 2025 lọna aitọ''

Minisita to n ri si bawọn eeyan ṣe n wọle si UK lati ilẹ okeere, Mike Tapp, ni tiẹ ṣalaye pe o ṣee ṣe kawọn ẹṣọ to ba gba foonu lọwọ awọn to wọ ọkọ oju omi wọle si UK si ri foonu wọn gba pada.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọgbẹni Tapp sọ pe iru nnkan ti wọn ba ri lori foonu wọn lo maa sọ bo ya wọn o ri foonu wọn gba pada.

O ni tawọn ẹṣọ aṣọbode ba ri nnkan to le ṣeranwọ fun iwadii, awọn ẹṣọ yoo gba iru foonu bẹẹ.

Ofin tuntun yii fidi rẹ mulẹ pe ẹnikẹni to ba n pese ẹnjini fun ọkọ oju omi ti wọn fi n kawọn eeyan wọle si UK le ṣẹwọn fun ọdun mẹrinla.

Ọgbẹni Martin Hewitt to n lewaju nibi gbigbogun ti awọn to n fi ọkọ oju omi kawọn eeyan wọle si UK lọna aitọ sọ pe lọpọ igba bi ẹgbẹrun mẹrin lawọn ẹṣọ alaabo ti koju eeyan to n lo ọkọ oju omi lati fi kawọn eeyan wọle si UK.

Hewitt ni oriṣiiriṣii nnkan lawọn ti ri gba bii owo lọwọ awọn to n kawọn ajeji wọle.

O ni awọn mii ti foju bale ẹjọ bakan naa lori ọrọ yii.

Ọgbẹni Hewitt ni ofin tuntun ti ijọba ṣe agbekalẹ rẹ yii yoo tubọ ṣeranwọ lati dẹkun awọn to n fi ọkọ oju omi ko ajeji wọle si UK.

Eeyan ti ko din ni 41,472 ni wọn lo ọkọ oju omi lati wọle wa si UK lọdun 2025 lọna aitọ.

Lati ọjọ Aje ọsẹ yii ni ofin tuntun yii ti bẹrẹ ni UK.