Ta ni Ọ̀mọ̀wé Olugbemisola Odusote, Adarí Obìnrin àkọ́kọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga àwọn Amòfin tí Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò?

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu, ti buwọ lu iyansipo Ọmọwe Olugbemisola Titilayo Odusote, gẹgẹ bii Adari apapọ fun ile ẹkọ awọn amofin ni Naijiria (Director-General of the Nigerian Law School).
Atẹjade kan ti Oludamọran fun Aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fi sita lọjọ Iṣẹgun ana, fidi iyansipo naa mulẹ.
Atẹjade naa fi kun un pe ọjọ kẹwaa, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni Ọmọwe Odusote yoo gba akoso iṣẹ naa.
Ọdun mẹrin ni yoo si fi di ipo naa mu.
Odusote, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta (54) ni obinrin akọkọ ti yoo gba ipo Adari ile ẹkọ awọn amofin ni Naijiria lati ọdun 1962 ti wọn ti da ile ẹkọ ọhun silẹ.
Ta a ni Olugbemisola Titilayo Odusote?
Ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn bi nilẹẹ Yoruba ni Ọmọwe Olugbemisola Titilayo Odusote, bo tilẹ jẹ pe akọsilẹ ibẹrẹ aye rẹ ko fi bẹẹ han sode.
Ṣaaju ibuwọlu Aarẹ si ipo Adari ile ẹkọ awọn amofin yii, Odusote lo di ipo Igbakeji Adari agba ẹka ipinlẹ Eko mu nile ẹkọ awọn Amofin.
O n gba ipo Adari agba bayii lọwọ Ọjọgbọn Isa Hayatu Chiroma, ẹni ti saa rẹ yoo wa sopin lọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.
*Amofin Olugbemisola gba oye LLB.B nipa ẹkọ ofin nile ẹkọ Obafemi Awolowo Yunifasiti, Ile Ife.
O di Amofin ilẹ Naijiria ni 1988.
O gba oye LL.M (Master of Laws) ni Obafemi Awolowo University, ẹka ofin to de ileeṣẹ ati karakata.
Oye Ọmọwe ninu ofin (Ph.D. in Law) lo gba ni University of Surrey, United Kingdom.
Bakan naa ni Ọmọwe Odusote ti lọ fi kun imọ rẹ ni Nottingham Trent University (UK), nibi to ti ṣiṣẹ iwadii.
O ti le logun ọdun ti Olugbemisola ti n ba ẹkọ ofin bọ Ọdun 2001 lo darapọ mọ ile ẹkọ ofin Naijiria, gẹgẹ bii olukọ. O di olori ẹka to n ri si eto ati iṣẹ. O figba kan jẹ Adari to n ri si amuṣẹ ofin. Ọmọwe Odusote jẹ adari ẹka ile ẹkọ ofin nipinlẹ Eko, o si bojuto ọkan lara awọn ẹka to tobi julọ ni Naijiria. Ni bayii to di olori pata, lara iṣẹ ti yoo maa mojuto ni Idari ẹkọ, iṣakoso, gbigbe eto idari kalẹ, ati biba awọn ẹka to n ri si ẹkọ ofin ṣe, pẹlu ẹgbẹ awọn amofin ni Naijiria (Nigerian Bar Association).














