Àwọn agbábọ́ọ̀lù adilémú ń bẹ̀rù Osimhen ṣáájú ìdíje Afcon 2025 - Onyeka

Victor Osimhen, n dunnu ninu aṣọ agbabọọlu orilẹede Naijiria lẹyin to gba goolu sawọn ninu ere bọọlu kan

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Ian Williams
    • Role, BBC Sport Africa
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Agbabọọlu aaringbungbun fun ikọ Super Eagles Naijiria, Frank Onyeka, ti sọ pe ẹlẹsẹ ayo, Victor Osimhen, n ṣana lọwọ yii.

Onyeka ni ọpọ awọn agbabọọlu adilemu loun gbagbọ pe wọn n bẹru Osimhen ṣaaju idije Afcon 2025 ti yoo bẹrẹ lọjọ Aiku to n bọ.

Osimhen ati Onyeka wa lara awọn agbabọọlu Naijiria to fidirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Afcon 2023 nibi ti Ivory Coast ti jawe olubori.

Goolu kan ṣoṣo ni Osimhen ri gba sawọn ninu idije Afcon to kọja lọ eyi to waye loriilẹede Ivory Coast.

Onyeka sọ fun BBC pe ''ẹlẹsẹ ayo to dantọ ni Osimhen i ṣe, gbogbo bọọlu lo maa n fẹ lọ fun.

Mo lero pe awọn agbabọọlu adilemu yoo maa bẹru rẹ.''

Ami ayo mẹrin pere ni Super Eagles ri gba ninu mẹẹdogun to yẹ ki wọn gba ninu awọn ere bọọlu ti Osimhen ko le kopa ninu rẹ.

Bakan naa ni iwaju Super Eagles ko ṣana mọ lẹyin ti Osimhen ti jade ni ipari abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife agbaye 2026 FIFA World Cup ti won gba pélu DR Congo.

Onyeka ni ọkan lara awọn agbabọọlu DR Congo gan an sọ pe awọn agbabọọlu adilemu awọn sinmi lẹyin ti Osimhen ko tẹsiwaju pẹlu ifẹsẹwọnsẹ naa mọ.

Onyeka n wo ṣakun idije Afcon 2025

Frank Onyeka agbabọọlu aaringbungbun Super Eagles wọ aṣọ awọn agbabọọlu Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bo tilẹ jẹ pe Onyeka ti n gbabọọlu daadaa fun Naijiria lati bii ọdun meloo sẹyin, nnkan ko lọ daadaa fun un to lẹgbẹ agbabọọlu Brentford.

Onyeka ko tii bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ kankan labẹ akọnimọọgba tuntun fun ikọ agbabọọlu Brentford, Keith Andrews.

Koda, wọn fi Onyeka paarọ lọ si ikọ agbabọọlu Augsburg ni Germany ni saa bọọlu to kọja.

Onyeka ko gba goolu kankan sawọn ninu gbogbo ere bọọlu 34 to kopa ninu rẹ nigba to wa pẹlu Augsburg ni idije Bundesliga.

Amọ, o gba goolu sawọn fun Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Super Eagles gba pẹlu Benin, o si tun gba goolu mii sawọn nigba ti Naijiria koju DR Congo ninu idije ati pegede fun 2026 World Cup.

Chelle akọnimọọgba tawọn eeyan fẹran

Eric Chelle wọ aṣọ awọn akọnimọọgba Naijiria

Oríṣun àwòrán, EPA

Onyeka loun ti ba akọnimọọgba Super Eagles Eric Chelle nipa wi pe oun le maa gba goolu sawọn fun Naijiria.

Onyeka sọ pe akọnimọọgba Eric Chelle mu ayipada ba ikọ Super Eagles pẹlu bi awọn ikọ agbabọọlu ṣe n gbabọọlu.

Agbabọọlu Brentford ti n gba bọọlu daadaa fun Naijiria lati igba ti Chelle ti di akọnimọọgba Super Eagles.

Amọ, ko ni kopa ninu idije Afcon 2025 tori o ti fẹsẹ ṣeeṣe.

Onyeka ni nigba toun dagba toun bẹrẹ sii maa gba bọọlu fun Naijiria loun to mọ pe ko rọrun lati ṣoju Naijiria ninu ere bọọlu.

O ni oriṣiiriṣii ọrọ kobakungbe lawọn eeyan maa n sọ sawọn nigba kugba ti Super Eagles ba ti fidi rẹmi.

Amọ, o ni oun mọ pe ifẹ tawọn ololufẹ Super Eagles ni si ere bọọlu lo jẹ ki wọn maa ṣe bẹẹ.