Ìtàn Ayangalu obìnrin onílù ákọ́kọ́, àti bí ó ṣe di ìyàwógbogbo òrìṣà 201 tó wà nílẹ̀ Yorùbá

Àkọlé fídíò, Ìtàn Ayangalu onílù ákọ́kọ́, àti bí ó ṣe di òrìṣà ìlù lágbàáyé
Ìtàn Ayangalu obìnrin onílù ákọ́kọ́, àti bí ó ṣe di ìyàwógbogbo òrìṣà 201 tó wà nílẹ̀ Yorùbá

Ninu itan Yoruba ti awọn baba nla iran naa sọ to si di atẹnudẹnu, gbajumọ onilu ni Arabinrin kan ti wọn n pe ni Ayangalu,

Itan sọ wi pe o wa lara awọn oriṣa to rọ wa sile aye pẹlu Ọrunmila, koda nigba ti ilu kodun mọ laye ọrunmila, Ayangalu yii ni wọn ranṣẹ pe lati sọ bi ilu yoo ṣe dun pada.

Oloye Ayanrẹmilẹkun Ajibọba to jẹ Baalẹ Onilu ni ilu Ile Ifẹ, ṣalaye fun BBC News Yoruba pe, awọn nnkan etutu ti arabinrin Ayangalu la kalẹ lọja naa gẹgẹbi nnkan ẹbọ lati mu ilu dun lo yi pada di ilu ti wọn lu ti ilu fi n dun to fi n larinrin.

Bakan naa ni Oloye Ayanrẹmilẹkun Ajibọba tun ṣalaye pe obinrin aramanda ti wọn n pe ni Ayangalu yii koku rara, o binu di okuta ni, 'nitori to ba jẹ pe o ku ni ilu o ni sọrọ mọ'.

O ṣalaye siwaju sii pe wọn ri Ayangalu gẹgẹbi iyawo gbogbo awọn oriṣa 'mọkanlerugba' to wa ni ilẹ Yoruba; 'gbogbo ọba to ba si ti jẹ lo maa n ṣu u lopo'.