"Isẹ́ agbálẹ̀-ọjà ni mo fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nijọba ìbílẹ̀, mo jìyà, dá àjọ, gba owóyàá, pa ebi mọ́nú fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí n tó le kọ ilé àmọ́ ijọba Oyo wó o lulẹ̀ torí ọ̀nà Circular"

Àkọlé fídíò, Kí ló dé tí ọ̀nà Circular tó yẹ kó jẹ́ ìdùnnú fáwọn olùgbé Ibadan wáń pa wọ̀n lẹ́kún?
"Isẹ́ agbálẹ̀-ọjà ni mo fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nijọba ìbílẹ̀, mo jìyà, dá àjọ, gba owóyàá, pa ebi mọ́nú fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí n tó le kọ ilé àmọ́ ijọba Oyo wó o lulẹ̀ torí ọ̀nà Circular"

"Isẹ́ agbálẹ̀-ọjà ni mo fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nijọba ìbílẹ̀, owóyàá fún ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi kọ́lé, ọdún kan péré ni mo fi gbé ilé náà, kí ìjọba tó wó ó"

Oluseke Ojelabi lo n fi omije sọ̀rọ̀ yìí lásìkò to ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀, to si jẹ ọkàn lára àwọn aráàlú ti òpópónà Circular jẹ ile wọn ti a ba sọ̀rọ̀.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu omijé lójú, Ojelabi ni iṣẹ́ agbalẹ ọjà ni òun fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ ni ìjọba ìbílẹ̀.

O ni òun sì ń pa ebi mọ inú fún ọ̀pọ̀ ọdún láti fi kọle náà.

Àmọ́ ó ní ọdún kan péré ni òun fi gbé ilé náà, kí ìjọba to wo o.

O fikùn pe ìjọba kò tíì fún òun ní owó gba ma bínú kankan.

"Ibi tí mo dúró sí yìí ni ile ti mo kọ wá, kí ìjọba to wo lulẹ̀ torí ọna Circular.

Mo jìyà, dá àjọ, gba owóyàá ní ẹgbẹ́ alajeseku, pa ebi mọ inú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kí n tó le kọ ilé náà.

Ijọba wo o dànù, èmi ti mo sì ti jẹ ìyá onílé tẹ́lẹ̀, wá lọ padà yà ilé gbé.

Titi di àkókò yìí, ìjọba kò tíì fún mi ní owó gba ma bínú kankan."

Ojú ọ̀nà Circular àti Oluseke Ojelabi, obìnrin tí wọn wo ile rẹ. Ó wọ Ankara aláwọ̀ pọpu, ó sì wẹ gele Ankara náà.

Bawo ni ọrọ òpópónà Circular ṣe jẹ́?

Òpópónà Circular tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ń lá lọ́wọ́ jẹ èyí tó gbà ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà nilu Ibadan kọjá.

Oju ọna yìí jẹ́ olobiripo, tí gómìnà tẹ́lẹ̀ nipinlẹ Oyo, Alhaji Lam Adesina bẹ̀rẹ̀ rẹ, ní ẹni tó gbà ipò lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ to tí di Olubadan báyìí, ọba Rashidi Ladoja bá isẹ lọ lórí rẹ.

Oju ọna náà, tí ìjọba Abiola Ajimobi tẹsiwaju lórí rẹ, tí ìjọba gómìnà Seyi Makinde sì ń bá isẹ lọ lórí rẹ, ni yóò yìí ìlú Ibadan pò láti àríwá de gúúsù, ìlà oòrùn dé ìwọ oòrùn ìlú náà.

Gbogbo èèyàn tó bá sì ń bọ̀ láti àwọn ìlú tó yìí Ibadan ká, tí wọn fẹ́ lọ sáwọn ìlú miran nipinlẹ Oyo tàbí làwọn ipinlẹ miran to yí ìpínlẹ̀ Oyo ká, kò nílò láti wọ inú ìlú Ibadan mọ.

Oluseke Ojelabi, obìnrin tí wọn wo ile rẹ. Ó wọ Ankara aláwọ̀ pọpu, ó sì wẹ gele Ankara náà.

Ìpàdé wáyé laarin awọn olùgbé Ologuneru àti Gómìnà Seyi Makinde

Oju ọna Circular yìí ni wón yóò gbà jáde kúrò ní Ibadan, ló ṣìibi tí wọn ń lọ.

Laipẹ yìí ni Gomina Seyi Makinde báwọn èèyàn agbegbe Ologuneru, tí opopona olobiripo náà jẹ ilé wọn ṣe ìpàdé.

O ṣèlérí láti mú aadọta mita leba ọnanáà.

Àmọ́ kò pę ni ariwo tún sọ, táwọn èèyàn náà sì ni àwọn kò fara mọ́ pé kí ijọba mú aadọta mita ni egbe kinni àti ìkejì òpópónà náà bikoṣe mímú aadọta kìlómítà ní ẹgbẹ́ méjèèjì lapapọ.

Òpópónà Circular to yí ìlú Ibadan po

Onírúurú ìwọ́de ni àwọn aráàlú ti ọrọ naa kan tí ṣe láti pé àkíyèsí ìjọba sì àwọn ohun tó ń dùn wọn lọ́kàn nípa ojú ọ̀nà ọhun

Onírúurú awuyewuye lo ti wáyé nípa òpópónà olobiripo Circular tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ń ṣe lọ́wọ́.

Kódà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilegbe àti ilẹ ni àwọn aráàlú, to wa nijọba ìbílẹ̀ mẹ́fà ni ìpínlẹ̀ Oyo, tí òpópónà náà gba kọjá, ti padanu sọwọ ijọba.

Onírúurú ìwọ́de ni àwọn aráàlú ti ọrọ naa kan tí ṣe láti pé àkíyèsí ìjọba sì àwọn ohun tó ń dùn wọn lọ́kàn nípa ojú ọ̀nà náà.

Àmọ́ kò dabi pé ariwo wọn wọ etí ìjọba torí orin kan náà làwọn èèyàn yìí ń kọ ojoojumo.

Koko ohun tí àwọn èèyàn náà sì ń fi ẹhonu hàn lè lórí ni iye kìlómítà tí ìjọba fe mú ní ẹgbẹ́ kinni àti ìkejì ona náà.

BBC News Yorùbá, nínú ìròyìn yìí, gùnlé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwádìí nípa ojú ọ̀nà Circular road yìí.

A sì fẹ́ mọ àwọn ohun tó ń fa ẹhonu àwọn aráàlú àti ìgbésẹ̀ tí ìjọba ń gbé nípa rẹ.

Bákan náà, a fẹ́ wá ìdáhùn sí ìbéèrè pé kí ló dé tí òpópónà Circular to yẹ kó jẹ́ ìdùnnú àwọn olùgbé Ibadan ṣe wa di ohun tó ń pa wọn lẹ́kùn.

A bá àwọn Aláṣẹ ẹka ijoba ti ọrọ kan sọ̀rọ̀ pẹlu awọn eniyan ti òpópónà jẹ ilé wọn láti tán ìwádìí wa si ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àbọ̀ rèé.